Atiku Abubakar
Atiku Abubakar GCON (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n oṣù kọkànlá ọdún 1946) jẹ́ gbajúgbajà olóṣèlú ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Adamawa lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Òun ni Igbákejì Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà nígbà ìṣèjọba Ààrẹ Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ láti ọdun 1999 sí ọdun 2007. [1][2] Lọ́dún 2019, ó díje dupó Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lábẹ́ àsíyá ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party tako Ààrẹ Muhammadu Buhari tí ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, ṣùgbọ́n ìbò àti orí kò ṣe é lóore, ó fìdí remi.[3]
Atiku Abubakar | |
---|---|
11th Vice President of Nigeria | |
In office Oṣù Kàrún 29, 1999 – Oṣù Kàrún 29, 2007 | |
Ààrẹ | Olusegun Obasanjo |
Asíwájú | Mike Akhigbe |
Arọ́pò | Goodluck Jonathan |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | 25 Oṣù Kọkànlá 1946 Adamawa State, Nigeria |
Ẹgbẹ́ olóṣèlú | Peoples Democratic Party |
Ni osu kaarun odún 2022,ni won yan Atiku Abubakar gege bi oludije fun aare orílẹ̀ èdè Naijiria ti odun 2023 lábẹ́ àsíyá ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party .[4][5][6]
Láti ìgbà tí o ti wo òsèlù ní 1989, Atiku Abubakar ti díje fún ipò ààre orílè-èdè Nàìjíríà ní emarun(odun 1993, 2007, 2011, 2015 àti 2019) tí o sì fìdíremi. Ni odun 1993, o fidiremi ní idibo primari fun Moshood Abiola àti Baba Gana Kanibe.[7]
Ìdílé rẹ̀
àtúnṣeA bí Abubakar ní 25 November 1946 sí ìlú Jẹ́daà, Ìpínlẹ̀ Adamawa.[8] Orúkọ bàbá rẹ̀ ni Garba Abubakar, ẹni tí o jẹ́ oǹtajà àti àgbẹ́ Fulani, orúkọ Ìyá Atiku sì ni Aisha Kande. A sọ Atiku Abubakar lórúkọ Bàbá-àgbà rẹ̀, ẹni tí ó ń jẹ́ Atiku Abdulqadir, o sì jẹ́ ọmọbíbí ìlú Wurno, ìpinlè Sokoto, kó tó dipé o lọ sí ìlú Jẹ́dà.
Èkó rè
àtúnṣeBaba Atiku Abubakar lòdì sí èkó, o si gbiyanju láti mó jé kí Atiku kàwé sugbon ní ìgbà ijoba gbó nipa oro yìí, wón ti baba Atiku mon ewon fún ojo díè kí o to dipe ìyá-ìyàwó rè san owo lati gba léè. Atiku Abubakar bèrè ìwé nígbanígbà tí o jé omo odún méjo.
Abubakar lo ilé iwe Jada Primary School ni ìpínlè Adamawa. Léyìn ìgbà tí o parí èkó rè ní odún 1960, o wolé si ilé èkó Sekondiri ti Adamawa ní odun kana, pèlú omo ilé-ìwé okandinlogota(59) bi ti rè. Ni odun 1965, o keko jade ni ilé-ìwé naa, o si ni "grade three ni idanwo abajade WAEC rè.[9] Leyin ìwé sekondiri, Abubakar tèsíwájú ìwé ní Nigeria Police College ni Kaduna, sugbon o kuro léyìn ìgbà díè nitori ko fi èrí esi idanwo Mathematics rè han. Léyìn náà, o sisé agbowo ode koto dipé o wolé sí ilé-ìwé School of Hygiene ní Ìpínlè Kano ni 1966, o kó èkó jáde pèlù àmì-èye Diploma ni odun 1967.[10] Atiku tún tesiwaju ìwé léyìn èyí.
Ìdílé rè
àtúnṣeAtiku ní ìyàwó merin àti omo mejidinlogbon.[11] Atiku so wipe: "Mo fé ní idile tí o tóbi, mo wa ni eminikan lopolopo nígbà ti mo wà lomode, mi o ní egbon tàbí àbúrò okunrin tàbí obinrin. Mi o fé kí àwon omo mi wa ní àwon nikan bi o ti jé nígbà ti mo wa lomode, óún ni mo se fé ju ìyàwó kan lo, an ìyàwó mi jé aburobinrin mi, òré mi ati olubadamoran mi, won si ún ran arawon lówó.
Ni odun 1971, Atiku fé Titilayo Albert ní ikoko, ni ìlú èkó, o fe ni ikoko nitoripe idile rè kókó tako ìfé won.[12]
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Atiku Abubakar - Profile". Africa Confidential. 2019-12-19. Retrieved 2019-12-19.
- ↑ "The Nigerian operator who knows how to make money". BBC News. 2019-02-06. Retrieved 2019-12-19.
- ↑ Lawal, Nurudeen (May 30, 2022). "APC rigged 2019 presidential poll results, stole my votes in 5 states - Atiku". Legit.ng - Nigeria news. Retrieved June 9, 2022.
- ↑ "A Vice President for Atiku". THISDAYLIVE. June 10, 2022. Retrieved June 11, 2022.
- ↑ "Running mate: Crisis looms as Atiku intensifies consultations". Vanguard News. June 10, 2022. Retrieved June 11, 2022.
- ↑ Daramola, Kunle (June 10, 2022). "2023: Tinubu will defeat Atiku in Adamawa, says Babachir Lawal". TheCable. Retrieved June 11, 2022.
- ↑ "Atiku’s Many Shots at Presidency – THISDAYLIVE". THISDAYLIVE – Truth and Reason. 2018-10-08. Retrieved 2022-07-29.
- ↑ Ogundipe, Samuel (2019-04-22). "How I was born, raised in Nigeria - Atiku". Premium Times Nigeria. Retrieved 2022-07-29.
- ↑ "The Warrior from Jada – THISDAYLIVE". THISDAYLIVE – Truth and Reason. 2019-02-23. Retrieved 2022-08-05.
- ↑ Ezeadichie, Christopher (2022-07-18). "BIOGRAPHY AND LIFE OF NIGERIAN BUSINESSMAN AND POLITICIAN, ATIKU ABUBAKAR.". Financial Quest. Retrieved 2022-08-05.
- ↑ Orjinmo, Nduka (2022-07-10). "Atiku Abubakar woos Nigerians with a reminder of the good times". BBC News. Retrieved 2022-08-11.
- ↑ "ABUBAKAR, Atiku (GCON)". Biographical Legacy and Research Foundation. 2022-08-08. Retrieved 2022-08-11.