Boko Haram
Bòkó Àráámùù, tí wọ́n pe ara wọn ní Wilāyat Gharb Ifrīqīyyah (èdè lárúbáwá: الولاية الإسلامية غرب أفريقيا, (Islamic State West Africa Province, ISWAP), àti: Jamā'at Ahl as-Sunnah lid-Da'wah wa'l-Jihād (èdè lárúbáwá: جماعة أهل السنة للدعوة والجهاد, "Ẹgbẹ́ àwọn ènìyàn Sunnah fún ìwàásù àti Jihad"), jẹ́ ẹgbẹ́ ìmàle tí ó wà ní àríwá-ìlà oòrùn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, tí ó tún ṣiṣẹ́ ní orílẹ̀ èdè Chad, Niger àti àríwá Cameroon. Olórí ẹgbẹ́ yìí ní Abubakar Shekau. Ẹgbẹ́ yìí ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú al-Qaeda, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kẹtà ọdún 2015, wọ́n ṣe ìkéde ìfọwọ́sowọ́pọ̀ wọn pẹ̀lú Islamic State of Iraq and the Levant (ISIL). Lati ìgbà tí ìdojú ìjà kọ ìjọba yìí tí bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 2009, ẹgbẹ̀rú lọ́na ogún ènìyàn ni wọ́n ti pa, tí wọ́n sí sọ ènìyàn mílíọ́nù méjì àti ọgọ́rún mẹ́ta di aláìnílé tí wọ́n sì ṣe ipò kínín nínú àwọn ẹgbẹ́ jàndùkú tí ó wà ní gbogbo àgbàyé, àwọn Global Terrorism Index ni wọ́n ṣe àkójọ yìí ní ọdún 2015.
Bòkó Àráámùù | |
---|---|
Participant in the Boko Haram insurgency and the War on Terror | |
Top: The black standard of ISIL, which was adopted by Boko Haram in 2015 Bottom: Logo of Boko Haram until 2015 | |
Active | 2002–present |
Ideology | Wahhabism Salafism Islamic fundamentalism |
Leaders | Abubakar Shekau (current leader) Mohammed YusufÀdàkọ:KIA (founder) |
Headquarters | * Sambisa Forest, Borno, Nigeria (March 2015–present)[1][2] |
Area of operations |
Northeast Nigeria, Northern Cameroon, Niger, Chad |
Part of | Àdàkọ:Country data Islamic State of Iraq and the Levant (2015–present) |
Became | Wilayat Gharb Afriqiya (ISWAP) |
Opponents |
Lẹ́yìn ìdásílẹ̀ rẹ̀ ní ọdún 2002, ìpánle Boko Haram peléke tí ó sì ṣe okùnfà ikú olórí wọn ní oṣù keje ọdún 2009. Wọ́n tún yọjú àìmọ̀tẹ́lẹ̀, lẹ́yín ìfipá já ọgbà ẹ̀wọn ní Oṣù kẹsán ọdún 2010, bẹ́ẹ̀ni ìdojúìjà àwọn ènìyàn ń peléke síi, lakọ́kọ, wọ́n ń dojú ìjà kọ àwọn tí kò lágbáraa, bẹ́ẹ̀ ni wàhálà yìí pọ̀ síi ní ọdún 2011 tí ó fi di àwọn ìfàdó olóropànìyàn paraẹni tí ó ṣelẹ̀ ní ọgbà olọ́pa àti United Nation ní Abuja. Ìgbéṣẹ̀ ìjọba àpapọ̀ lati ṣàyipada sí àwọn ijọba ìpínlẹ̀ tí ó wà ní àríwá ìlà-oòrùn Nàìjíríà ní ọdún 2012, tí ó tún ṭ̀síwájú síi ní ọdún tó tẹ̀le fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlòkúlò àwọn ológun ti ààbò àti ìdojú ìjà kọ àwọn ènìyan lọ́wọ àwọn tí ó ń dojú ìjà kọ ìjọba.
Nínú àwọn ènìyàn mílíọ́nù méjì àti ọgọ́rún mẹ́ta tí wọ́n ti sọ di aláìnílé lasti Oṣù karún ọdún 2013, ókéré jù, bíi ènìyàn 250,000 ti fi Nàìjíríà sílẹ̀ lọ sí Cameroon, Chad tàbí Niger. Boko Haram pa àwọn ènìyàn tí ó ju 6,600 lọ ní Ọdún 2014. Ẹgbẹ́ yìí fipá kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lọ àti ìfipá kó akẹ́kọ́ igba lé mẹ́rìndínlọ́gọrin kúrò ní Chibok ní Oṣù kẹrin Ọdún 2014. Ìwàìbàjẹ́ nínú àwọn òṣìṣẹ́ ààbò àti àwọn ajàfẹ́tọ àwọn ènìyàn jẹ́ kí ìgbìyànjú àti bẹ́gilé àìní ìsinmi yí ṣòro.
Ní bi àárín ọdún 2014, gba ìletò tí ó yí ilé wọn ká ní ìpínlẹ̀ Borno, tí a ṣírò sí bí 50,000 square kilometres (20,000 sq mi) ní Oṣù kínín Ọdún 2015, ṣùgbọ́n wọn kò rí ìpínlẹ̀ Maiduguri kó, ní ibi tí ẹgbẹ́ yìí ti kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀. Ní oṣù kẹsán ọdún, 2015, olùdarí ìròyìn fún olúilé iṣẹ́ ológun tí Nàìjíríà sọọ́ di mímọ̀ pé wọ́n ti ba gbogbo abà Boko Haram jẹ́.
Orúkọ
àtúnṣeOrúkọ ẹgbẹ́ yìí gangan ni Wilayat Gharb Afriqiya, fún ẹ̀ka to designate it as a branch or "ìgbèríko" ti mùsùlùmí tí Iraq àti ti Levant (ISIL). Kí Abubakar Shekau tó jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún ISIL, orúkọ ẹgbẹ́ yìí ni Jamā'atu Ahli is-Sunnah lid-Da'wati wal-Jihād جماعة أهل السنة للدعوة والجهاد, tí ó túmọ̀ sí "Àwọn ènìyàn tí kọ́ ẹ̀kọ́ Prophet àti Jihad".
Orúkọ "Boko Haram" yìí túmọ̀ sí "Èèwọ̀ ni ẹ̀kọ́ ọ̀làjú". Haram jẹyọ lati èdè lárúbáwá حَرَام ḥarām, "èèwọ̀"; tí ọ̀rọ̀ Hausa yìí boko [tí àìránmúpè àkọ́kọ́ gùn long, tí èkejì máa ń pe oùn ìsàlẹ̀], tí ó túmọ̀ sí "ẹbu", tí wọ́n fi ń pe ẹ̀kọ́ ọ̀làjú. Boko Haram tún túmọ̀ sí "Ẹ̀ṣè ni ọ̀làjú" and "Ọlàjú kìí ṣe oun tó mọ́". Kí olùdásílẹ̀ rẹ̀ Mohammed Yusuf, tó kú, wọ́n mọ ẹgbẹ́ yìí sí Yusifiyya. Àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí àríwá kò fìgbàkan gba ti ọ̀làjú tí wọ́n sì ń pèé ni ilimin boko ("ẹbu ẹ̀kọ́") tí wọ́n sí máa ń pe ilé ìwé ní makaranta boko.
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 Morgan Winsor (17 April 2015). "Boko Haram In Nigeria: President Goodluck Jonathan Rejects Help From UN Forces To Fight Insurgency". International Business Times. Retrieved 18 April 2015.
- ↑ 2.0 2.1 "With Help From ISIS, a More Deadly Boko Haram Makes a Comeback". The Daily Beast. Retrieved 11 September 2015.
- ↑ "We have restricted Boko Haram to Sambisa Forest – Buhari". Retrieved 21 May 2016.
- ↑ 4.0 4.1 4.2 Bureau of Counterterrorism. "Country Reports on Terrorism 2013". U.S. Department of State. Retrieved 7 August 2014.
- ↑ 5.0 5.1 5.2 "Ẹda pamosi". Archived from the original on 2015-01-18. Retrieved 2016-07-10.
- ↑ 6.0 6.1 6.2 "Jonathan tasks Defence, Foreign Ministers of Nigeria, Chad, Cameroon, Niger, Benin on Boko Haram's defeat". sunnewsonline.com. http://sunnewsonline.com/new/?p=85939.
- ↑ 7.0 7.1 7.2 Martin Williams. "African leaders pledge 'total war' on Boko Haram after Nigeria kidnap". The Guardian. http://www.theguardian.com/world/2014/may/17/west-african-countries-must-unite-fight-boko-haram-nigeria.
- ↑ "Chadian Forces Deploy Against Boko Haram". VOA. 16 January 2015. http://www.voanews.com/content/chad-sending-troops-to-help-cameroon-fight-boko-haram/2600762.html. Retrieved 16 January 2015.