Olubukola Abubakar Saraki (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù Kejìlá ọdún 1962) jẹ́ òṣèlú àti Ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti ìpínlẹ̀ Kwara. Ó ti fìgbà kan jẹ gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara fún ọdún mẹ́jọ gbáko, bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 2003 di 2011 lábẹ́ àsíyá ẹgbẹ́ òṣèlú People's Democratic Party, PDP. Ní kété tí ó fipò gómìnà sílẹ̀ lọ́dún 2011, wọ́n dibò yàn án sì ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà láti ṣojú ẹkùn ìdìbò àárín-gbùngbùn Ìpínlẹ̀ Kwara, bákan náà lọ́dún 2015,ó tún wọlé lẹ́ẹ̀kejì ṣùgbọ́n lábẹ́ àsíyá ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC. Ó pàdánù ìdìbò láti padà sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà ni ẹ̀kẹta lọ́dún 2019, nígbàtí ó digbá-dagbọ̀n rẹ̀ kúrò ní APC, tí ó sì padà sí PDP, ègbé òṣèlú rẹ̀ àná.[1] Lásìkò yìí náà, ó díje dípò Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, ṣùgbọ́n, ìdìbò abẹ́lé kò gbè ẹ. Igbá-kejì Ààrẹ-àná, Atiku Abubakar ni ẹgbẹ́ PDP fà kalẹ̀.[2] [3] [4] [5]

Bukola Saraki, osu kẹwàá ọdún 2017

Ìgbé-ayé rẹ̀ nígbà èwe àti aáyán ẹ̀kọ́ kíkà rẹ̀ àtúnṣe

Wọ́n bí Bùkọ́lá Sàràkí lọ́dún 1962 ní orílè èdè Bìrìtìkó (United Kingdom). Àgbà òṣèlú àti Sínétọ̀ ni bàbá tó bí i lọ́mọ, Olúṣọlá Sàràkí lọ́dún 1979 sí 1983. Florence Morẹ́nikẹ̀ Sàràkí lórúkọ Ìyá rẹ̀. Ìdílé atàpátadìde pọ́ńbélé ló ti wá. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ kíkà rẹ̀, ó lọ sí Corona School, ní Victoria Island, Ìlú Èkó, ní ìlú Èkó kí ó tó tẹ̀síwájú ní ilé-ìwé gíga ti King's College, ní ìlú Èkó bákan náà lọ́dún 1973 sí 1978. Lẹ́yìn èyí, ó tún tẹ̀síwájú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ilé-ìwé Cheltenham College ní orílè-èdè United Kingdom lọ́dún 1979 to 1981, ibẹ̀ ló ti gba ìwé-ẹ̀rí ẹ̀kọ́ gíga rẹ̀. Ó tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ síi ní London Hospital Medical College of the University of London lọ́dún 1982 sí 1987, níbi tí ó ti gba ìwé ẹ̀rí dókítà àṣẹ wòsàn M.B.B.S (London).[6] [7]

Ìgbé ayé rẹ̀ àtúnṣe

Toyin Sàràkí ni orúkọ ìyàwó Bukola Saraki. Ọmọ mẹ́rin ni wọ́n bí fún ara wọn. Ní sáà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara, wọ́n fi í joyè Tùràkí tí gbogbo àwọn Fúlàní. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Ọba ìlú Ìlọrin tún fi í joyè Waziri tí gbogbo Ìlọrin, oyè Waziri dàbí òye Ààrẹ-ìlú, (Prime Minister). Bàbá rẹ̀, Olúṣọlá Sàràkí ló joyè náà kí Bùkọ̀lá Sàràkí tó jẹ ẹ́. Bákan náà, Olúbàdàn tí ìlú Ìbàdàn, Oba Sálíù Adétúnjí tún fi í joyè Ajagùnnà tí ìlú Ìbàdàn lọ́dún 2017. [8]

Àwọn Ìtọ́kasí àtúnṣe

  1. "2019 Election: Saraki loses Senate seat to APC’s Oloriegbe". Punch Newspapers. 2015-12-15. Retrieved 2019-11-18. 
  2. Published (2015-12-15). "UPDATED: Saraki declares his intention to run for presidency". Punch Newspapers. Retrieved 2019-11-18. 
  3. vanguard; vanguard (2018-10-16). "Saraki named Atiku’s Presidential Campaign Council DG". Vanguard News. Retrieved 2019-11-18. 
  4. "Governor Bukola Saraki - Home". bukisaraki.org. 2010-04-08. Archived from the original on 2010-04-08. Retrieved 2019-11-18. 
  5. "COLUMBIA, SC". Who's On The Move. 2018-10-04. Retrieved 2019-11-18. 
  6. Odunayo, Adams (2015-09-21). "Passport Linked To Saraki Forged – UK Authority". Legit.ng - Nigeria news. Retrieved 2019-11-18. 
  7. "Bukola Saraki: Profile Of An Ambitious Political Gatekeeper". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. 2015-05-03. Retrieved 2019-11-18. 
  8. "Saraki, 15 Others Get Chieftaincy Titles". Information Nigeria. 2017-03-04. Retrieved 2019-11-18.