Baptist Academy, jẹ́ ilé-ẹ̀kọ́ girama kan tí ó wà ní agbègbè Ọbaníkòró ní Ìpínlẹ̀ Èkó. Àwọ́n ajíyìnrere ará ilẹ̀ Amẹ́tíkà kan ni wọ́n wá dá ilé-ẹ̀kọ́ náà sílẹ̀ sí ìlú Èkó ní ọdún 1855.[1][2] Ilé-ẹ̀kọ́ yí jẹ́ ẹ̀ka ilé-ẹ̀kọ́ Reagan Memorial Baptist Girls' Secondary School, tí ó wà ní agbègbè YábáÌpínlẹ̀ Èkó.

Ìtàn Ìṣẹ̀dálẹ̀ rẹ̀ àtúnṣe

Wọ́n da ilé-ẹ̀kọ́ yí sílẹ̀ lẹ́yìn tí àwọ́n ajíyìn-rere tí wọ́n jẹ́ ọmọ otílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí wọ́n ti ṣe àtìpó ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà da ilé-ìjọsìn Onítẹ́bọmi sílẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Èkó . Ọba Dòsùmú tí ó jẹ́ Ọba Èkó nígbà náà ni ó fún wọn ní ilẹ̀ tí wọ́n fi kọ́lé ìjọsìn wọn sí. Láìpẹ́, ètò-ẹ̀kọ́ beeẹ̀ ní pẹrẹu, bí iṣẹ́ ìyìn-rere ṣe ń tẹ̀ siwájú náà ni ilé-ẹ̀kọ́ náà ń dàgbà si. Nígbà tí yóò fi di nkan bí ọdún 1888, ilé-ẹ̀kọ́ náà ti ní àwọn ọmọ akẹ́kọ̀ọ́ ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ọmọ ọkùnrin tí ó ti tó ọgbàọ́rùn un kan àti ẹyọ mọ́kàndínlógún, nígbà tí àwọ akèkọ̀ọ́ ọmọ obinrin jẹ́ márùndínlọ́sàánọ́gọ́rùn un, nígbà tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ò wà ní ilé-ẹ̀kọ́ girama jẹ́ mẹ́rìndínlógún lọ́kùnrin àti akẹ́kọ̀ọ́bìnrin mẹ́ta péré. Ṣáájú ọdún 1926, ajíyìn-rere ọmọ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà kan ni ó ṣe ọ̀gá àgbà fún ilé-ẹ̀kọ́ náà, amọ́ ní inú oṣù Kíní ọdún 1926, ọ̀gbẹ́ni ajíyìn-rere Eyo Ita dara pọ̀ mọ́ ilé-ẹ̀kọ́ náà gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ tí ó sì di ọ̀gá àgbà ilé-ẹ̀kọ́ náà. [3] Ibi tí wọ́n kọ́ ilé-ẹ̀kọ́ náà sí tẹ́lẹ̀ ni àdúgbò Broad Street, ṣáájú kí wọ́n tó gbe lọ sí ọ̀nà Ìkòròdú. Ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ nìkan ni wọn kò gbé kúrò ní Broad Street, síbẹ̀ wọ́n yí orúkọ rẹ̀ padà sí W.J David Memorial Baptist Primary School nírántí olóògbé (William Joshua David) tí ó jẹ́ ajíyìn-rere ọmọ ilẹ̀ [[Amẹ́ríkà tí ó kọ́kọ́ gbé ìjọ Onítẹ̀bọmi wá sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ilé-ẹ̀kọ́ Àlàkalẹ̀ọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ yí wà ní Broad street títí di ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1980 kí wọ́n tó wo ilé-ẹ̀kọ́ náà lulẹ̀ nígbà tí wọ́n fẹ́ fa ilé-ìjọsìn onítẹ̀bọmi tí ó wà ní ìdàkejì ilé-ẹ̀kọ́ náà siwájú si. Gbogbo àwọn ọmọ akẹ́kọ̀ọ́ ilé-ẹ̀kọ́ alàkákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ibẹ̀ ni wọ́n fi sọ̀kò sí àwọn ilé-ẹ̀kọ́ Àlàkalẹ̀ọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ onítẹ̀bọmi tí ó wà ní agbègbè ibẹ̀.


Ọ̀rọ̀ akin ilé-ẹ̀kọ́ náà àtúnṣe

Deo duce which means God is my leader.

Àkọmànà ilé-ẹ̀kọ́ náà àtúnṣe

Up Baptacads

Orin Ìṣelákin wọn àtúnṣe

We are Baptist Academy boys and We're proud of our dear Alma Mater Where sweet fellowship we all enjoy Where the spirit of Christ is taught Where our captain, God, lead us along We"ll be true to our Alma Mater always.

Up school Up Baptacads

Àtòjọ àwọn Olùkọ́ àgbà àtúnṣe

Some of the principals of the school include

  • Prof. S.M Harden. 1855
  • Miss Lucile Reagan. 1924 - 1937
  • Dr. A. Scott Patterson. 1937 - 1940
  • Rev. B.T Griffin 1941 - 1945
  • Rev. John Mills 1946 - 1951
  • Rev. G.Lane 1951 - 1953
  • Rev. Dr. J.A. Adegbite(first Nigerian principal of the school) 1954 - 1975
  • Mr. Abayomi Ladipo 1976 - 1977(Old boy)
  • Mr. Micheal O. Alake 1977 - 1979
  • Rev. V.S Adenugba. 1979 - 1981
  • Rev. S.O.B. Oyawoye 1981 - 1982
  • Mr. Olakunle 1982 - 1983
  • Mr. Aiyelokun 1983 - 1991
  • Mr. C.O. Oduleye 1992 - 1994
  • Mr. A.C. Adesanya. 1994 - 1999
  • Mrs. F.O. Ojo. 1999 - 2003
  • Mr. H.O. Alamu 2003 - 2009
  • Rev. Mrs. B.A Ladoba 2009 - 2018
  • Dcn. Gbenga Abodunrin 2018 till date

Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́jáde tó ti lààmì-laaka àtúnṣe

Ẹ tún lè wo àtúnṣe

Àdàkọ:Portal box

Àwọn Itọ́kasí àtúnṣe

Àwọn Ìtàkùn ìjásóde àtúnṣe

Àdàkọ:Coord missing