Ọlábísí Ọnàbánjọ

Olóṣèlú

Olóyè Victor Ọlábísí Ọnàbánjọ ni wón bí ní ọjọ́ kejìlá oṣù kejì ọduń 1927, tí ó sì papò dà ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kẹ́rin ọdún 1990. Ó ti fìgbà kan jẹ́ gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní Ìpínlẹ̀ Ògùn ní àárín ọdún 1979 sí ọdún 1983, nígbà ayé òṣèlú ẹlẹ́kejì ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. [1] Bákan náà ni ó jẹ́ ọmọ ilu Ìpẹru Rẹ́mọ.[2]

Ọlábísí Ọnàbánjọ
Governor of Ogun State
In office
Oct 1979 – Dec 1983
AsíwájúHarris Eghagha
Arọ́pòỌládípọ̀ Díyà
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí(1927-02-12)Oṣù Kejì 12, 1927
Lagos, Nigeria
AláìsíApril 14, 1990(1990-04-14) (ọmọ ọdún 63)

Ìgbé ayé rẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n bí olóyè Victor Ọlábísí Ọnàbánjọ ní ọdún 1927 ní Ìpínlẹ̀ Èkó. Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ ti Onítẹ̀bọmi ti Baptist Academy, nígbà tí ó sì lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ Regent Street Polytechnic ní orílẹ̀-èdè Brítènì, níbi tí ó ti kọ́ ìmọ̀ nípa ìròyìn àti ìgbóhùn-sáfẹ́fẹ́ láàrín ọdún 1950 sí ọdún 1951. Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí oníròyìn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ṣáájú kí ó tó padà di olóṣèlú pọ́nbélé. Ọnàbánjọ ma ń sọ àwọn òrọ̀ tí ó jẹ́ òtítọ́ nínú àlàfo Ìwé Ìròyìn olójoojúmọ́ ti Daily Service àti Daily Express níbi tí ó ti ma ń pe àkọ́lé ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní "Ayékòótọ́ láàrín ọdún 1954 sí ọdún 1962.[3]

Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Olóṣèlú

àtúnṣe

Wọ́n yan Ọlábísí gẹ́gẹ́ sí ipò alága Ìjọba Ìbílẹ̀ Ìjẹ̀bú-Òde, ní ọdún 1977 lábẹ́ ọ̀gá rẹ̀ olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀. Lẹ́yìn tí ó kúrò ní ipò alága ìjọba ìbílẹ̀ yí tán ni wọ́n tú́n yàn án sípò Gómìnà ti Ìpínlẹ̀ Ògùn ní inú oṣù kẹwàá ọdún 1979 lábẹ́ ẹgbẹ́ ìṣèlú Unity Party of Nigeria.[3]

Ọlábísí ṣe ìfilọ́ọ́lẹ̀ Ilé-iṣẹ́ amóhùnmáwòrán ti Ìpínlẹ̀ Ògùn ní ọjọ́ Kẹtàlá oṣù Karùn ún ọdún 1982. [4] Ilé-ẹ̀kọ́ Yunifásitì ti Ìpínlẹ̀ Ògùn tí wọ́n dá sílè ní ọjọ́ keje oṣù keje ọdún 1982 ni wọ́n yí orúkọ rẹ̀ padà sí Yunifásitì Ọlábísí Ọnàbánjọ ní ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù karùn ún ọdún 2001 láti fi bu ọlá fún Olóyè Ọlábísí Ọnàbánjọ tí ó ti di olóògbé`.[5] Olóyè Ọlábísí Ọnàbánjọ ni ó ṣe àgbékalẹ̀ ilé-ẹ̀kọ́ Abraham Adésànyà Polytechnic, àmọ́ Ọ̀gágun Ọládípọ̀ Díyà tí ó jẹ́ gónìmà lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Ológun fagilé ilé-ẹ̀kọ́ náà, wọ́n sì ṣí ilé-ẹ̀kọ́ náà padà nígbà tí ìṣèjọba pààrọ̀ ọwọ́ kúrò ni tológun sí ti àwa ara wa ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ọdún 1999.[6] Lẹ́yìn ìfipá gbàjọba tí ó gbé ọ̀gágun Muhammadu Buhari dé orí ipò Ààrẹ apàṣẹ wàá, Buhari sọ Ọlábísí Ọnàbánjọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún méjìlélógún, tí wọ́n sì da sílẹ̀ ní ọdún 1985 lábẹ́ ìṣèjọba ọ̀gágun Ibrahim Babangida tí ó bojú àánú wòó. Ọ̀gágun Ibrahim Babangida ni ó sì tún ṣètò bí ó ṣe padà lọ sí ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì láti lọ ṣètọ́jú ara rẹ̀. [7] Lẹ́yìn tí wọ́n da sílẹ̀ kúrò ní ọgbà ẹ̀wọ̀n, Ó padà sí ẹnu iṣẹ́ ìròyìn rẹ̀ tí ó sì ń ṣàgbéjáde àwọn ìròyìn òdodo tí ó ti ń ṣe tẹ́lẹ̀ tí ó pe àkọ́lé rẹ̀ ní Ayékòótọ́ nínú àlàfo ìwé-ìròyìn Nigerian Tribune láàrín ọdún 1987 sí 1989. Olóyè Ọnàbánjọ dágbére fáyé ní ọjọ́ kẹrinlá oṣù kẹrin ọdún 1990.[8]

Ìwé Ìtọ́kàsí

àtúnṣe
  • Victor Olabisi Onabanjo (Edited by Felix A. Adenaike) (1991). Aiyekooto. Syndicated Communications Ltd, Ibadan. ISBN 978-31115-0-7. 

Àwọn Ìtọ́kàsí

àtúnṣe
  1. "West Africa". West Africa : Africa's Weekly Magazine (Afrimedia International) (nos. 3233-3258). 1979. ISSN 0043-2962. https://books.google.com/books?id=ezMOAQAAMAAJ. Retrieved 2015-08-24. 
  2. "Ogun 2011: Those Who Want OGD's Job". Saturday Tribune. 21 November 2009. Archived from the original on November 25, 2009. Retrieved 2009-12-17.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. 3.0 3.1 "Aiyekooto". AfBIS. Archived from the original on 2009-04-18. Retrieved 2009-12-17. 
  4. Tayo Agunbiade. "Gateway Television: Name- Change And Politics Of Envy". Gamji. Retrieved 2009-12-17. 
  5. Admin. "OOU History". OOU. Retrieved 27 January 2019. 
  6. LUKMAN OLABIYI (June 15, 2009). "When fresh breeze blew on Adesanya Poly". Daily Sun. http://www.sunnewsonline.com/webpages/features/featurettes/2009/june/15/Featurettes-06-15-2009-001.htm. Retrieved 2009-12-17. 
  7. Olakunle Abimbola (15 September 2009). "Exit Gani (1938-2009)". The Nation. Retrieved 2009-12-17. 
  8. "How Babangida helped my family back to England". P.M. News. 2015-11-05. Retrieved 2024-07-14.