Bayo Lawal
Adebayo Adeleke Lawal jẹ́ olóṣèlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó ti fìgbà kan jẹ́ igbá-kejì gómínà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láti oṣù keje, ọdún 2022. Wọ́n yàn án sípò lẹ́yìn tí wọ́n yọ Rauf Olaniyan nítorí àwọn àṣemáṣe tí wọ́n kà sí i lẹ́sẹ̀.[1][2]
Bayo Lawal | |
---|---|
Deputy Governor of Oyo State | |
Lọ́wọ́lọ́wọ́ | |
Ó gun orí àga 19 July 2022 | |
Gómìnà | Seyi Makinde |
Asíwájú | Rauf Olaniyan |
Oyo State Commissioner of Justice | |
In office 1999–2003 | |
Gómìnà | Lam Adesina |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | Adebayo Adeleke Lawal |
Ọmọorílẹ̀-èdè | Nigerian |
Ó jẹ́ alága Housing Corporation.[3] Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní Yunifásítì ìlú Ìbàdàn, nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ Ẹkọ́nọ́míìkì. Lam Adesina yàn án gẹ́gẹ́ bíi Kọmíṣọ́nà tó ń rí sí ẹ̀ka ìdájọ́, wọ́n sì fi jẹ amòfin àgbà tó ga jù lọ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní ọdún 1999. Ó sì ṣiṣẹ́ títí di ọdún 2003.[4]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Adebayo, Musliudeen (18 July 2022). "Oyo Assembly approves nomination of Bayo Lawal as new Deputy Governor". Daily Post Nigeria. https://dailypost.ng/2022/07/18/oyo-assembly-approves-nomination-of-bayo-lawal-as-new-deputy-governor/.
- ↑ "Oyo gets new deputy gov after Olaniyan's removal". Punch Newspapers. 18 July 2022. https://punchng.com/just-in-oyo-gets-new-deputy-gov-after-olaniyans-removal/.
- ↑ "Barrister Lawal Fecilitates With Muslim Devotees, Calls For Prayers, Assistance For Gov. Makinde". Ọ̀YỌ́ M'ÈSÌ Ọ̀RỌ̀. 10 July 2022. https://oyomesioro.com/barrister-lawal-fecilitates-with-muslim-devotees-calls-for-prayers-assistance-for-gov-makinde/.
- ↑ "All Africa". https://allafrica.com/stories/200209010213.html.