Bayyinat

Jọ́nà oṣooṣù ti Lárúbáwá, èyí tí Jamia Uloom-ul-Islamia máa ń tẹ̀jáde

Bayyināt (Urdu: بینات)jẹ́ ìwé àtìgbàdégbà oṣooṣù titi Jamia Uloom-ul-Islamia. Àtẹ̀jáde rẹ̀ náà wà ní èdè Lárúbáwá tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Al-Bayyinat. Wọ́n tẹ jáde ní ní oṣù kọkànlá ọdún 1962. Ó jẹ́ iṣẹ́ àkànṣe iṣẹ́ fún Aláṣẹ ẹ̀sìn Deobandi Ulama ní ilẹ̀ Pakistan. Yàtọ̀ sí pé kí a gbé ògo fún Ulama fún ilé kéwú àwọn òbí, ó ti tẹ àwọn àròkọ jáde èyí tí ó tako Shias àti Qadyanis lápá kan, tí tako àwọn ìṣe kan tí ó wọ́pọ̀, ètò ẹ̀kọ́ wọn àti ètò òṣèlú ilẹ̀ Pakistan bákan náà [1][2][3][4]

Bayyinat  
Abbreviated title(s) Bayyināt
Discipline {{{discipline}}}
Language Urdu
Publication details
Publisher Jamia Uloom-ul-Islamia (Pakistan)
Links

Àríyànjiyàn àkọ́kọ́ lórí Bayyinat yí kárí lábẹ́ àjọ olóòtú Abdur Rashid Numani. Numani jẹ́ olóòtú ìwé àtìgbàdégbà títí di oṣù Kejìlá ọdún 1963 lẹ́yìn náà ni Muhammad Yusuf Banuri jẹ títí, kí ó tó papòdà ní ọdún 1977.Ẹ̀ka-ẹ̀kọ́ ọ̀tọ̀ wọ́n dá Shuba-i Tasnif ní Jamia Uloomul Islamia tí wọ́n sì yan aṣojú ojúṣe rẹ̀ fún àtẹ̀jáde Bayyināt. Ní ọdún 1962, owó sísan ọdọọdún náà kò ju rúpíìsì mẹ́fà lọ, àádọ́ta paisa fún oṣoòṣù, ní ọdún 1977,owó ọdọọdún fòsókè sí rúpíìsì márùndínlógún, tí oṣoòṣù sì jẹ́ rúpíìsì kan àti àádọ́ta paisa fún ìwé Bayyinat kọ̀ọ̀kan. Bí ó ti jẹ́ pé owó yìí di ìlọ́po méjì láàárín ọdún 1962 sí ọdún 1977, kò ì ti sọ pé kí wọ́n na ní owó kékeré. Wọ́n máa ń tẹ ìwé àtìgbàdégbà náà jáde ní ọjọ́ keje oṣù lórí kálẹ́ńdà Gregorian. Àròpín ìwé Bayyinat máa ń sáábà jẹ́ àádọ́ta sí ọgọ́rin ojú ewé, ṣùgbọ́n àtẹ̀jáde pàtàkì tí wọ́n ṣe ní ìrántí Yusuf Banuri lé ní Ojú ewé ẹgbẹrìn, tí àwọn àwòrán Jamia Uloomul Islamia tí a kùn ní dúdú àti funfun náà sì wà níbẹ̀. Àwọn àríyànjiyàn àkọ́kọ́ ló bí ìgbéjáde ìwé tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́"Parwez Kafir He" (Parwez jẹ́ ìwé alágbèrè ẹ̀sìn) pẹ̀lú àwọn kókó ọ̀rọ̀ inú ìwé náà àti ìjúwe rẹ̀.[4][3]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
àtúnṣe