Bella Awa Gassama
Bella Awa Gassama jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Gámbíà.
Bella Awa Gassama | |
---|---|
Orílẹ̀-èdè | Gambian |
Orúkọ míràn | Awa Gassama |
Iṣẹ́ | Actress |
Ìgbà iṣẹ́ | 2004-present |
Ìsẹ̀mí rẹ̀
àtúnṣeGassama ní ìbátan pẹ̀lú oníìdájọ́ bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá tí n ṣe Bakary "Papa" Gassama.[1] Ó parí ẹ̀kọ́ girama rẹ̀ ní ilé-ìwé Marina International School ní ọdún 2004. Ó kó àkọ́kọ́ ipa rẹ̀ nínu fíìmù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Arrou ní ọdún 2004 yìí kan náà. Wọ́n wo fíìmù náà níbi ayẹyẹ Pan-African Film Festival kan tí ó wáyé ní ìlú Los Angeles, Gassama náà sì tún rí yíyàn fún àmì-ẹ̀yẹ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ òṣèré tí ó dára jùlọ níbi ayẹyẹ 2nd Africa Movie Academy Awards.[2] Wọ́n tún yàán fún òṣèré ilẹ̀ Gámbíà tí ó dára jùlọ níbi ayẹyẹ Vinasha Film Festival.[3] Ní ọdún 2008 bákan náà, Gassama tún kó àkọ́kọ́ ipa rẹ̀ nínu fíìmù ilẹ̀ Nàìjíríà tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ My Gambian Holiday pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Desmond Elliot àti Oge Okoye.[4] Ó tún kó ipa amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ nínu fíìmù Mirror Boy ti ọdún 2011, ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Fatima Jabbe àti Genevieve Nnaji.[5] Ní ọdún 2012, Gassama parí ìkẹ́kọ̀ọ́ láti ilé-ẹ̀kọ́ gígaTask Crown College.[6]
Gassama kópa nínu eré Sidy Diallo kan ti ọdún 2014 tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ The Soul.[7] Wọ́n yàán fún àmì-ẹ̀yẹ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ òṣèré tí ó dára jùlọ níbi ayẹyẹ Zulu African Film Academy Awards.[8] Ó kópa nínu eré tẹlifíṣọ̀nù ti ọdún 2019 kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Nakala.[9] Ní Oṣù kọkànlá Ọdún 2019, Gassama ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú Pa Lie Low.[10]
Àwọn àṣàyàn eré rẹ̀
àtúnṣe- 2004: Arrou (Idena)
- 2008: Isinmi Gambian mi
- 2011: Ọmọkunrin Digi
- 2013: Idanimọ ti ko tọ
- 2014: Ọkàn
- 2019: Nakala (jara TV)
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Gassama, Awa (9 January 2014). "Gambia: Papa Gassama - It Takes Hard Work, Dedication to Get to the Top". https://allafrica.com/stories/201401091185.html. Retrieved 16 October 2020.
- ↑ "Introducing (Bella Awa Gassama)". The Standard. 5 May 2014. https://standard.gm/introducing-bella-awa-gassama/. Retrieved 16 October 2020.
- ↑ Khan, Alieu (28 November 2006). "Who is your Gambian actor and actress of the year?". Africa.gm. Archived from the original on 18 November 2021. Retrieved 16 October 2020.
- ↑ "Introducing (Bella Awa Gassama)". The Standard. 5 May 2014. https://standard.gm/introducing-bella-awa-gassama/. Retrieved 16 October 2020.
- ↑ Wally, Omar (6 June 2011). "Gambia: 'The Mirror Boy' Launched in Gambia". https://allafrica.com/stories/201106062042.html. Retrieved 16 October 2020.
- ↑ "Introducing (Bella Awa Gassama)". 5 May 2014. https://standard.gm/introducing-bella-awa-gassama/. Retrieved 16 October 2020.
- ↑ Obi, Ikenna. "THE SOUL premiers: 26th of April 2014 at the LightHouse in Camberwell.". FabAfriq. Retrieved 16 October 2020.
- ↑ "ZAFFA Unveils 2014 Nominees". Pulse. 25 August 2014. Retrieved 16 October 2020.
- ↑ "Come and get it! Bella Gassama shows some leg in promo photo". What's On Gambia. 30 November 2019. Archived from the original on 17 October 2020. Retrieved 16 October 2020.
- ↑ "Congratulations! Nollywood Actress Bella Gassama gets married to US-based Pa Lie Low". What's On Gambia. 30 November 2019. Archived from the original on 20 October 2020. Retrieved 16 October 2020.