Oge Okoye

òṣèré orí ìtàgè ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjírírà

Oge Okoye (tí a bí ní 16 Oṣù Kọkànlá, Ọdún 1980) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó wá láti Nnewi ní Ìpínlẹ̀ Anámbra.[1] Ìlú Lọ́ndọ̀nù ni a bí Oge Okoye sí[2] kí ó tó di pé ó gbèrò láti wá gbé ní Ìlú Èkó pẹ̀lú àwọn ẹbí rẹ̀. Ó parí ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ní Ìlú Lọ́ndọ̀nù ṣááju kí ó tó wá sí Nàìjíríà. Nígbàtí ó padà sí Nàìjíríà, ó tún lọ sí Ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ University Primary School ní ìlú Enúgu, kí ó tó tún wá lọ sí Holy Rosary College fún ètò-ẹ̀kọ́ girama rẹ̀[3] .

Oge Okoye
Ọjọ́ìbí(1980-11-16)16 Oṣù Kọkànlá 1980
London, United Kingdom
Orílẹ̀-èdèBiritiṣi ati Naijiria
Iléẹ̀kọ́ gígaYunifásítì Nnamdi Azikiwe
Iṣẹ́Osere

Ó parí ilé-ẹ̀kọ́ gígai Yunifásítì Nnamdi Azikiwe, ti ìlú Awka pẹ̀lú oyè ní eré Tíátà . Ó darapọ̀ mọ́ ilé-iṣẹ́ fíìmù ti Nàìjíríà tí a mọ̀ ní Nollywood ní ọdún 2001. Ó di gbajúmọ̀ òṣèré lẹ́hìn tí ó kópa nínu fíìmù 'Spanner' ní ọdún 2002 pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Chinedu Ikedieze tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí 'Ákí' nídi iṣẹ́ fíìmù ti Nàìjíríà. Ó ṣe ìgbéyàwó ní ọdún 2005 pẹ̀lú ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ Stangley Duruo tí wọ́n ti jọ́ n bá ara wọn bọ̀ fún ìgbà pípẹ́, ṣùgbọ́n àwọn méjéèjì ti padà ṣe ìpinyà ní ọdún 2012 lẹ́hìn ọmọ méjì tí wọ́n ní fún arawọn.[4] Ní ọdún 2006, ó rí yíyàn fún àmì-ẹ̀ye African Movie Academy ní ẹ̀ka ti “amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ òṣèré tí ó dára jùlọ” fún ipa rẹ̀ nínu fíìmù "Eagle's Bride"[5][6][7]

Ó tún jẹ́ olùgbéréjáde àti afẹwàṣiṣẹ́. Ó ti hàn nínu ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àtẹ̀jáde fún oge ṣíṣe àti àwọn ìkéde ìpolówó ọjà lóri tẹlifíṣọ̀nù. Ó ti fi ìgbàkan jẹ́ aṣojú ìpolówó ọjà fún àwọn ilé-iṣẹ́ bi Globacom àti MTN Nàìjíríà, àwọn méjéèjì jẹ́ ilé-iṣẹ́ ti Nàìjíríà tó n rí sí ìbáraẹnisọ̀rọ̀ lóri ẹ̀rọ.[8] .

Àkójọ àwọn sinimá àgbéléwò rẹ̀

àtúnṣe

Eré tẹlifíṣọ̀nù

àtúnṣe
Ọdún Àkọ́lé Ipa Ìtọ́kasí
2015 Hotel Majestic Patricia, ọmọ ọdọ laafin [9]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe