Betty Apiafi
Betty Jocelyne Okagua - Apiafi(ti a bi ní 19 January 1962) jẹ onimọ-ọrọ-aje, olukorede àti òtòkùlú olósèlú ní Nàìjirià. Apiafi wà lara àwon Senato Nàìjirià, óún se asoju Rivers West Senatorial District. [1] O tun se aṣoju fun Abua/Odual-Ahoada East Federal Constituency ní ilé igbimo asofin kekere(house of Representatives) ti Ipinle Rivers ni 2007. O jẹ ọmọ ẹgbẹ oselu People’s Party Democratic (PDP).
Betty Apiafi | |
---|---|
Senator ikọ̀ Rivers West | |
Lọ́wọ́lọ́wọ́ | |
Ó gun orí àga 2019 | |
Asíwájú | Osinakachukwu Ideozu |
Member of the House of Representatives for Abua/Odual—Ahoada East | |
Arọ́pò | Solomon Bob |
In office 2007–2019 | |
Asíwájú | Osinakachukwu Ideozu |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | 19 Oṣù Kejì 1962 Rivers State, Nigeria |
Ẹgbẹ́ olóṣèlú | PDP |
(Àwọn) olólùfẹ́ | Kalada Apiafi |
Alma mater | University of Port Harcourt Rivers State University |
Awards | Distinguished Service Star of Rivers State (DSSRS) |
Àárò ayé àti èkó rè
àtúnṣeWón bí Betty Jocelyne Apiafi ni ojo 19 February 1962. O kékó gboyè ninu èkó oro ajé lati ile-ẹkọ Yunifásitì Port Harcourt, ósì tún tèsíwájú láti gba oyè Masters ní Rivers State University of Science and Technology [2]
Ilé igbimo asoju
àtúnṣeNigba sáà rè ní ilé igbimo asoju(house of Representatives) ní odun 2007 si 2019, o jé ara àwon tí oun ja takuntakun fún ètó àti èkó àwon omo obinrin. Awọn obinrin miiran ti a yan sí ipò igbimo asojú pèlú rè ni Folake Olunloyo, Maimunat Adaji, Martha Bodunrin, Suleiman Oba Nimota, Mulikat Adeola Akande, Uche Lilian Ekunife, Beni Lar, Lynda Chuba-Ikpeazu, Mercy Almona-Isei, Doris Uboh, hette E. [3]
Ilé igbimo asofin àgbà
àtúnṣeA diboyan Betty Apiafi si ile igbimọ aṣofin Naijiria kesan ni ọdun 2019 labẹ ẹgbẹ People's Democratic Party, óún ṣe aṣoju Agbegbe Rivers West Senatorial lowolowo. Òun ni obinrin akoko láti ipinle Rivers tí a diboyan sí ipò ilé igbimo asoju tàbí/àti sí ilé igbimo asofin. [4]
Àwon Ìtókasí
àtúnṣe- ↑ "Senate moves to mainstream gender parity in Constitution". The Nation Newspaper. 2021-03-10. Retrieved 2022-05-21.
- ↑ "OKAGUA-APIAFI,HON Jocelyn Betty". Biographical Legacy and Research Foundation. 2017-10-25. Retrieved 2022-05-21.
- ↑ "Women who will shape Seventh National Assembly". Vanguard News. 2011-06-06. Retrieved 2022-05-21.
- ↑ "Betty Apiafi". Wikiwand. 2010-01-01. Retrieved 2022-05-21.