Maimunat Adaji
Hajiya Maimuna Usman Adaji tí àwon ènìyàn mò si Maimunat Adaji (1957 – 2019) jẹ́ olóṣèlú Nàìjíríà nigba ayé rè. A kọkọ diboyan fun Ile igbimo Aṣoju ni ọdun 2003, a tun dibo yan lẹẹkansi ni ọdun 2011 lábé egbé oselu All Nigeria people's party.
Maimunat Adaji | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Hajiya Maimuna Usman Adaji c. 1957[1] Nigeria |
Aláìsí | 2019 (ọmọ ọdún 61–62)[1] Abuja, Nigeria (2019) |
Orúkọ míràn | Usman |
Iṣẹ́ | Politician |
Political party | All Nigeria Peoples Party |
Igbé ayé rè
àtúnṣeAdaji jẹ́ olûkó, ó sì ní ilé ẹ̀kọ́ kan, ó sì tún jẹ́ olóṣèlú ní Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Kẹrin. Adaji gbe ni Kaduna fun opolopo ìgbà ayé rè, ósì se asoju ẹkun Baruten/Kaiama laarin ọdun 2003 si 2011.[2] A kọkọ dibo yan si ile igbimọ aṣojú ni ọdun 2003. Bí otile jewipe o jẹ ọmọ ẹgbẹ oselu ti All Nigeria Peoples Party (ANPP), tí agbegbe náà sì jé ìbí tí egbe oselu People's Democratic party(PDP) tí gbajumo, Adaji jawe olibori nínú ìbò náà.
Ni ọdun 2011, a tún diboyan gégé bi asojú. Awọn obinrin miran tí a diboyan ni ọdun yẹn ni Suleiman Oba Nimota, Folake Olunloyo, Martha Bodunrin, Betty Okogua-Apiafi, Rose Oko ati Nkoyo Toyo.
Adaji se alaisi ni ọdun 2019 ni ẹni ọdun 62, o bí omo méjì nigba ayé rè. [3]
Àwon Ìtókasí
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 "Maimuna Usman Adaji, Former Kwara House Of Reps Member, Dies At 62 – Orient Mags" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2020-01-02. Retrieved 2021-01-19.
- ↑ "Public offices held by Hajia Maimunat Adaji in Nigeria". Citizen Science Nigeria. 2007-05-29. Retrieved 2022-05-22.
- ↑ "Maimunat Adaji Wiki, Biography, Age, Husband, Net Worth, Family, Instagram, Twitter & More Facts". Wiki and Biography world. 2021-03-18. Archived from the original on 2021-11-21. Retrieved 2022-05-22.