Abidemi Ayodeji Ogunmolu, tí a tún mọ̀ sí Bidemi Olaoba, jẹ́ olórin ìhìnrere àti akọrin. Wọ́n mọ̀ ọ́n gẹ́gẹ́ bí òǹkọrin ìhìnrere ní ìlànà fújì.[1]

Bidemi Olona
Background information
Orúkọ àbísọAbidemi Ayodeji Ogunmolu
Ìbẹ̀rẹ̀Ikale, Okitipupa, Ondo State, Nigeria
Occupation(s)
  • Singer-songwriter
  • worship leader
Years active2012- present
Labels
  • Olaoba Entertainment
Associated acts

Ìgbésí ayé ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n bí Olaoba ní ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù kẹwàá, ọdún 1991[2] sínú ìdílé kírítẹ́nì; mẹ́fà ni wọ́n jẹ nínú ìdílé náà ní ìlú Èkó, orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ó wá láti ìlú Ìkálẹ̀ Okitipupa ni ìlú Ondo.[3] Bidemi kọ́ nípa Civil Engineering ní ilé ìwé gíga tí Yaba College of Technology ní ìlú Èkó àti ẹ̀kọ́ Economics[4] ní ilé ìwé gíga Yunifásítì tí Èkó (UNILAG), orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Ìgbésí ayé àti iṣẹ́ tó yàn láàyò

àtúnṣe

Olaoba bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ orin kíkọ gẹ́gẹ́ bíi adarí orin ìyìn nínú ìjọ àpósítélì ti Kristi[5], ó sì dárapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ akọrin ìjọ CAC àti ti ìjọ àwọn ìràpadà kírítẹ́nì. Lẹ́yìn tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ yìí, Olaoba gbé orin àkọ́kọ́ rẹ̀ jáde tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní "Final Say" ní ọdún 2016.[6] Ó lókìkí nípa ọ̀rọ̀ tó máa ń sọ pé "The Bible Says".[7][8][9]

Wọ́n pe Olaoba sí ibi ìyìn àṣẹ è dánu dúró (marathon praise)[10][11] èyí tí ìjọ àwọn ìràpadà kírítẹ́nì (RCCG) ṣágbékalẹ̀ rẹ̀ tí wọ́n sì lókìkí lọ́pọ̀lọpọ̀. Ó ní orin àdàkọ mẹ́fà, ti orí pápá méjì àti orin àjọkọ pẹ̀lú àwọn olórin ìhìn rere lóríṣiríṣi. Olaoba lọ sí àwọn ìlú bíi Íróòbù, Amẹ́ríkà àti àwọn ìlú Áfíríkà, Ó gbé ìyìn kalẹ̀ níbẹ̀, òun sì ni agbátẹrù ìyìn orí afẹ́fẹ́ tí ó pè ní "Unrestricted Praise"[12][13] tí ó bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 2020 Ó sì dàpọ̀ mọ́ àwọn olórin ìhìnrere bíi Buchi, Tope Alabi, Mike Abdul, Adeleke Adeboye, Eben, àti Samie Okposo láti kọ orin.

Olaoba ṣeré ní ibi ìpéjọpọ̀ àwọn kírítẹ́nì tó tóbi jù ní Nàìjíríà àti ìyìn Mèsáyà àṣe è dánu dúró tì wọ́n pè ní Festival of Life tí ìjọ àwọn kírítẹ́nì ìràpadà gbé kalẹ̀ (Dubai, Dublin, Italy àti United Kingdom), MASS, HI-impact Praise, àti COZA.[14] concert by the Redeemed Christian Church Of God, Festival Of Life[15]

Àwọn orin rẹ̀

àtúnṣe

Studio albums

àtúnṣe
  • Final Say (2016)
  • Bonjour (2017)
  • My Life (2018)
  • Baba (2019)
  • Holy Gyration (2020)

Àwọn àwo àṣepọ̀ orí pápá rẹ̀

àtúnṣe
  • Winning Praise (2019)
  • Mass (2020)

Àwọn orin fíìmù rẹ̀

àtúnṣe
sn Video Year Released
1 Bonjour 2018[16]
2 Baba 2019[17]
3 Akanchawa 2020[18]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Messages of hope needed now more than ever –Bidemi Olaoba". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-01-06. 
  2. "Bidemi Olaoba Biography: Age, Wife, Children & Net Worth - Famous Today" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2023-10-16. Retrieved 2023-10-28. 
  3. Oma, Zowonu. "Unrestricted Praise". Archived from the original on 2021-01-07.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  4. "Unrestricted Praises". Archived from the original on 2021-01-07.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  5. Oma, Zowonu (2017-02-09). "'I'm a Lover of Music'". THISDAYLIVE (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-01-03. 
  6. Oma. "Bidemi Releases New Single". Archived from the original on 2017-11-27.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  7. "Bidemi Olaoba Bonjour Release". 
  8. "The Bible Says". Archived from the original on 2021-01-09.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  9. "Bidemi Olaoba". Encounter 5.0 (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2021-01-09. Retrieved 2021-01-03.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  10. "Marathon Praise". THISDAYLIVE (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-02-21. Archived from the original on 2017-02-18. Retrieved 2021-01-04.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  11. Oma, Zowonu. "Marathon Praise Official website". Archived from the original on 2014-03-02.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  12. Oma. "Bidemi Olaoba, others for 'unrestricted praises". Archived from the original on 2020-10-23.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  13. "Olaoba, Tope Alabi, Sammie Okposo, Eben, Young Bishop others rock Unrestricted Praise Concert". Archived from the original on 2021-01-07.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  14. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named :02
  15. "Chapel Of Transfiguration Website". Archived from the original on 2021-01-09.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  16. "Bidemi Olaoba - Bonjour Official Video". Notjustok. Jan 19, 2018. Retrieved January 18, 2018. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  17. Olaboye, Moses (2019-09-29). "(Music + Video): Bidemi Olaoba – Baba". Gospelloop.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-01-06. 
  18. "Bidemi Olaoba preaches hope in Akanchawa". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-05-09. Retrieved 2021-05-12.