Bolanle Olukanni
Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Isírẹ́lì, Amẹ́ríkà àti Kẹ́ńyà ni wọ́n ti tọ́ Bọ́láńlé. [1] Bọ́láńlé Olukanni lọ si St. Saviour's Primary School ní ìlú Eko fún ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀. Ó tẹ̀ síwájú lọ sí Queens College fún ilé-ẹ̀kọ́ Gírámà. Olukanni tún lọ sí Kenya níbití ó ti lọ síRosslyn Academy ni Nairobi, Kenya fún apákan ti ilé-ẹ̀kọ́ gíga rẹ̀. Ṣáájú ọdún ìkẹyìn rẹ̀ ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga, ó lọ sí Amẹrika àti fún ọdún àgbà rẹ̀, ó lọ sí Ilé-ẹ̀kọ̀ gíga Wichita Southeast ní Wichita, Kansas, níbití ó ti kópa nínú Ìdíje ọ̀rọ̀ Orílẹ̀-èdè àti Ìdíje àríyànjiyàn fún èto "Dramatic Interpretation".
Bolanle Olukanni | |
---|---|
on Ndani TV's The Juice in March 2019 | |
Ọjọ́ìbí | 19 August 19?? |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Ẹ̀kọ́ | Loyola University, Chicago |
Iṣẹ́ | Presenter |
Ní ọdún 2007, Olukanni gba oyè ìwé-ẹ̀rí Básẹ́lọ̀ láti iilé-ẹ̀kọ́ gíga Loyola ní Chicago, pẹ̀lú aléfà méjì - Bachelors of Arts nínú Communications àti International Studies. [2] Ó ti jẹ́ olùgbàlejò lórí ètò "Àwọn Àkókò pẹ̀lú Mo" lórí DStv ati Project Fame West Africa .
Ó ní iṣẹ́ móhùn-máworan èyiun TV àkọ́kọ́ rẹ̀ bíi agbàlejò kejì lórí ilé-iṣẹ́ mohùn-máwòrán kan fún ètò tí a pè ní "Àwọn àkókò pẹ̀lú Mo”. Wọ́n yàn-án láti ṣe atọ́kùn ètò yìí pẹ̀lú olùdarí EbonyLife TV, Mo Abudu tí ó ń gbóhùn sáfẹ́fẹ́ lórí EbonyLife TV.
Àwọn ìtọ́kasí.
àtúnṣe- ↑ Izuzu, Chidumga. "Bolanle Olukanni: 5 things you probably don"t know about the charming TV host" (in en-US). Archived from the original on 2018-05-16. https://web.archive.org/web/20180516053820/http://www.pulse.ng/entertainment/movies/bolanle-olukanni-5-things-you-probably-dont-know-about-the-charming-tv-host-id4086129.html.
- ↑ Introducing the New Girl! Meet “Moments with Mo” Co-Host Bolanle Olukanni