Christiane Chabi-Kao (tí a bí ní 30 Oṣù kẹẹ̀fà, Ọdún 1963) jẹ́ olùdarí eré àti ònkọ̀tàn ọmọ orílẹ̀-èdè Benin.

Christiane Chabi-Kao
Ọjọ́ìbí30 Oṣù Kẹfà 1963 (1963-06-30) (ọmọ ọdún 61)
Marseille
Orílẹ̀-èdèBeninese
Iṣẹ́Film director, screenwriter

Ìsẹ̀mí ayẹ́ rẹ̀

àtúnṣe

A bí Chabi-Kao ní ìlú Marseille, orílẹ̀-èdè Fránsì ní ọdún 1963.[1] Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ gíga <i>University of Reims Champagne-Ardenne</i> láti ọdún 1984 si 1986. Ní ọdún 1990, Chabi-Kao padà sí ilẹ̀ Áfíríkà.[2] Ó ṣe àkọ́kọ́ fíìmù rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Les enfants esclaves ní ọdún 2005, eré tí n ṣe àpèjúwe àwọn ẹrú òde-òní.[3]

Ní ọdún 2007, ó ṣe adarí fíìmù Les inseparables. Eré náà dá lóri ìtàn àwọn tẹ̀gbọ́ntàbúrò kan, Yawa àti Abi, tí bàbá wọn gbé tà fún àwọn agbọ́mọfiṣiṣẹ́. Ààjọ UNICEF àti Beninese National Radio and Television (ORTB) ni wọ́n ṣe onígbọ̀wọ́ fún ṣíṣe fíìmù náà. Chabi-Kao kọ fíìmù náà léte láti la àwọn èyàn lọ́yẹ̀ nípa gbígbé ọmọdé fi ṣiṣẹ́ ati láti dẹ́kùn irú ìwà bẹ́ẹ̀.[4] Fíìmù náà gba àmì-ẹ̀yẹ níbi àjọ̀dún Vues d'Afrique, èyí tí ó wáyé ní ìlú Montreal ní ọdún 2008, ó sì tún gba ẹ̀bùn tí Human Rights gbé kalẹ̀ níbi ayẹyẹ <i>Panafrican Film and Television Festival of Ouagadougou</i> ti ọdún 2009.[5]

Ní ọdún 2009, ó rọ́pò Monique Mbeke Phoba gẹ́gẹ́ bi adarí fún ti ayẹyẹ àjọ̀dún Lagunimages ti ìlú Kútọnu.[6] Ó ṣiṣẹ́ dídarí àjọ̀dún náà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ṣááju kí wọ́n tó gbàá tọwótẹsẹ̀ gẹ́gé bi olùdarí, ó sì rí ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Deutsche Welle Academy fún kíkọ́ bí ó ṣe lè máa ṣètò àjọ̀dún náà.[7]

Chabi-Kao lẹni tí ó kọ ìtàn eré tẹlifíṣọ̀nù Les Chenapans ti ọdún 2013, tó sì tún darí rẹ̀. Eré náà ṣe àpèjúwe ìsẹ̀mí àti ìtiraka àwọn ọ̀dọ́ márùn-ún kan. [8]

Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀

àtúnṣe
  • 2005: Les enfants esclaves
  • 2007: Les inseparables
  • 2013: Les Chenapans
  • 2014: Crocodile dans la Mangrove

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "CINE24 - BÉNIN : CHRISTIANE CHABI KAO EST UNE RÉALISATRICE ET SCÉNARISTE". Africa24TV (in French). Archived from the original on 25 October 2020. Retrieved 3 October 2020. 
  2. "Christiane CHABI KAO". Linternaute.com (in French). Retrieved 3 October 2020. 
  3. "Les Chenapans". Sortir.bf (in French). Archived from the original on 26 August 2021. Retrieved 3 October 2020. 
  4. David-Gnahoui, Reine (10 July 2017). "‘Les inséparables’ films help combat child trafficking in Benin and worldwide". UNICEF. Archived from the original on 23 October 2012. Retrieved 3 October 2020. 
  5. "CINE24 - BÉNIN : CHRISTIANE CHABI KAO EST UNE RÉALISATRICE ET SCÉNARISTE". Africa24TV (in French). Archived from the original on 25 October 2020. Retrieved 3 October 2020. 
  6. "Christiane Chabi Kao - biographie". Africultures (in French). Retrieved 3 October 2020. 
  7. Bationo, Fotrune (April 11, 2019). "Christiane Chabi Kao, directrice de Lagunimages au Bénin (du 23 au 26 avril)". Africine. Retrieved 3 October 2020. 
  8. Bousquet, Delphine (25 November 2017). "Bénin: la série TV "Chenapans" cherche distributeur" (in French). RFI. https://www.rfi.fr/fr/emission/20171126-benin-serie-televisee-chenapans-cherche-distributeur. Retrieved 3 October 2020. 

Àwọn ìtakùn Ìjásóde

àtúnṣe