Dambou
Dambu tàbí dambou jẹ́ oúnjẹ àwọn ènìyàn Zarma àti Songhai ní apá Gúúsù mọ́ Ìwọ̀-Oòrùn ilẹ̀ Niger, èyí tí wọ́n fi cereal àti Moringa ṣe. Ìgbàkúgbà ni wọ́n máa ń jẹ ẹ́ pàápàá jù lọ lásìkọ̀ ayẹyẹ ọdún ìbílẹ̀ kan bí ìgbéyàwó tàbí ayẹyẹ òmíràn. Oúnjẹ yìí tún gbajúmọ̀ láàárín àwọn ènìyàn Dendi ní apá Àríwà ilẹ̀ Benin àti ní àwọn ìlú mìíràn tí ó wà ní apá Ìwọ̀-oòrùn ilẹ̀ Africa. Bákan náà ni ó gbajúmọ̀ nií agbègbè Zongo níbi tí àwọn ènìyàn Songhai àti Zarma máa ń rin ìrìn-àjò lọ.[1]
Dambou | |
Alternative names | Dambu |
---|---|
Place of origin | Niger |
Created by | Zarma people, Songhai people |
Main ingredients | Usually Rice Flour or millet, wheat or corn couscous or corn couscous, moringa leaves, peanut, meat or fish |
Àdàkọ:Wikibooks-inline
|
Àwọn èròjà fún sísè
àtúnṣeSísè
àtúnṣeBí ó bá ṣe wun ẹni tó ń se Dambou ni ó ṣe le sè é. Àmọ́ láti se oúnjẹ yìí, àwọn alásè máa ń lo: ìyẹ̀fun ìrẹsì tàbí wheat semolina (couscous semolina) tàbí ọkà bàbà, tàbí couscous ti àgbàdo. Wọ́n máa sè é fún ogún tàbí ọgbọ̀n ìṣẹ́jú kí wọ́n ṣè tó wá fi ewé mọ̀ríngà tí wọ́n ti sè sínú rẹ̀. Lẹ́yìn náà, àwọn èròjà mìíràn bí: àlùbọ́sà, ata, iyọ̀, omi ẹran, ẹ̀pà, òróró, ẹran tàbí ẹja á wá wọ inú rẹ̀.[3][4][5][6]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Dambou", couscous aux épinards, 2017, retrieved 2021-05-09
- ↑ Dambou:Couscous with moringa leaves, Afrik Cuisine, archived from the original on 2021-05-09, retrieved 2021-05-09
- ↑ Un Jour, une Recette : Le Dambou, ESMA – Paris 1, 29 April 2020, retrieved 2021-05-09
- ↑ Couscous aux épinards - Dambou (Niger), retrieved 2021-05-09
- ↑ Dambou, couscou avec épinards, 2020, retrieved 2021-05-09
- ↑ Dambou, retrieved 2021-05-09