Òróró jẹ́ ohun èlò kan tí ó gbajúmọ̀ tí wọ́n jẹ́ kẹ́míkà tí wọ́n ṣe láti ara hydrocarbons tí ó sì tún jẹ́ ́̀hydrophobic tí wọn kò fi omi sínú rẹ̀ rárá. Òróró sábà ma ń jẹ́ ohun tí ó lè gbaná látàrí surface active tí ó wà nínú rẹ̀.

Ìgò òróró olive tí wón ń fi dáná.

Oríṣi òróró tí ó wà àtúnṣe

Òróró ohun abẹmí àtúnṣe

Òróró ohun abẹmí ni àwọn òróró tí a mú jáde láti ara àwọn ohun abẹ̀mí bíi: ẹranko, ẹja omi àti ewébẹ̀ bíi: Kárọ́ọ̀tì, Avocado àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ tí wọn lè ṣara lóore.[1]

Òróró ohun àlùmọ́nì àtúnṣe

Àwọn ohun àlùmọ́nì bíi epo bẹntiróò tí wọ́n ti ṣàtúnṣe rẹ̀, tí wọ́n sì ti yọ àwọn òróró kọ̀ọ̀kan nínú rẹ̀ tí wọ́n ń rọ sínú ọkọ̀.[2]

Ìlò òróró àtúnṣe

Óróró lè jẹ́ èyí tí a rí fàyọ láti ara ẹranko, ewébẹ̀ tàbí èyí tí wọ́n fi àwon kẹ́míkà ṣe àgbékalẹ̀ wọn. A lè lo òróró bíi olive oil fún óúnjẹ sísè. A lè lo irúfẹ́ òróró míràn fún àwọn ohun èlò ẹ̀rọ ilé wa bíi ọkọ̀, alùpùpù àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. A lè lo àwọn òróró bì mineral oil fùn ìtọ́jú àwọn aláàrẹ̀ nílé ìwòsàn, bẹ́ẹ̀ ni àwọn òróró kan wà tí àwọn ẹlẹ́sìn ma ń lò ̀lọ́nà ọ̀tọ̀ láti fi ṣe àdúrà tàbí ìyàsímímọ́ nínú ẹ̀sìn wọn.

Fún ìpèsè óúnjẹ àtúnṣe

Àdàkọ:Main article Oríṣiríṣi àwọn òróró ni ó wà fún jíjẹ, yálà èyí tí wọ́n yo láti ara ewé ni tàbí ẹranko, tí wọ́n sì ń lòó fún ìpèsè oríṣiríṣi óúnjẹ jíjẹ ní àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé gbogbo. Lọ́pọ̀ ìgbà ni wọ́n ma ń fi òróró dín àwọn óúnjẹ kan nítorí ó dára ju kí wọ́n fi omi lásán sè wọ́n lọ. Wọ́n tún ń lo òróró ̀láti fi yí bí wọ́n ṣe rí padà nípa lílo òróró bọ́tà tí wọ́n yọ láti ara eranko gẹ́gẹ́ bí ọ̀rá tábí èyí tí wọ́n yọ láti ara àwon ewébẹ̀ bíi: olive, àgbàdo, sunflower àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. [3]

Fún ìpara àtúnṣe

A ma ń lo òróró gẹ́gẹ́ bí ìpara tàbí ìparun láti lè jẹ́ kí a dùn-ún wò tàbí dùn ún rí láwùjọ ènìyàn. Àwọn èyí tí a ń lò láti fi pa irun ni ó ma ń jẹ́ kí irun wa ó dúdú kí ó sì ma dán yọ̀ọ́ yọ̀ọ́ tí kò fi ní ta kókó.

Fún ìjọsin àtúnṣe

Oríṣiríṣi ọ̀nà ni ọmọnìyàn ti lo òróró gẹ́gẹ́ bí ohun ìyàsí mímọ́ fún ìjọsìn nínú ìtàn lórílẹ̀ àgbáyé. Púpọ̀ àwọn ènìyàn ni wọ́n kàá kùn ọ̀nà kan pàtàkì tí wọ́n fi lè mú ìdàgbàsókè bá ẹ̀mí nínú ìjọsìn wọn. Àpẹẹrẹ ni ẹ̀sìn Judaism] àti [4] ẹ̀sìn Christianity.[5]


Fún amohuntutù àtúnṣe

Àwon òróró kan wà tí wọ́n jẹ́ amóhuntutù, bíi àpẹẹrẹ ẹ̀rọ tí ń múná wá transformers. Àwọn òróró tí wọ́n ń lò fún mímú ǹkan tutù yí ni wọ́n ma ń dẹ́kun ìgbóná-gbooru tí ó ma ń ṣẹlẹ̀ látàrí iṣẹ́ tí àwọn ẹ̀rọ náà ń ṣe.Àdàkọ:Cn

Ẹ tún lè wo àtúnṣe

Àwọn ìtọ́ka sí àtúnṣe

  1. Alberts, Bruce; Johnson, Alexander; Lewis, Julian; Raff, Martin; Roberts, Keith; Walter, Peter. Molecular Biology of the Cell. New York: Garland Science, 2002, pp. 62, 118-119.
  2. Kvenvolden, Keith A. (2006). "Organic geochemistry – A retrospective of its first 70 years". Organic Geochemistry 37: 1. doi:10.1016/j.orggeochem.2005.09.001. https://zenodo.org/record/1000677. 
  3. Brown, Jessica. "Which cooking oil is the healthiest?". www.bbc.com. BBC. Retrieved 18 May 2021. 
  4. Chesnutt, Randall D. (January 2005). "Perceptions of Oil in Early Judaism and the Meal Formula in Joseph and Aseneth" (in en). Journal for the Study of the Pseudepigrapha 14 (2): 113–132. doi:10.1177/0951820705051955. ISSN 0951-8207. http://journals.sagepub.com/doi/10.1177/0951820705051955. 
  5. Sahagun, Louis (2008-10-11). "Armenian priests journey for jars of holy oil". Los Angeles Times. http://articles.latimes.com/2008/oct/11/local/me-beliefs11. 

Ìtàkùn ìjásóde àtúnṣe

Àdàkọ:Wiktionary

 
Wikiquote logo
Nínú Wikiquote a ó rí ọ̀rọ̀ tójẹmọ́:

Àdàkọ:Authority control