Demas Akpore (ọjọ́ kẹrin oṣù kẹjọ, ọdún 1928 sí ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù Kejìlá, ọdún 1993. ) jẹ́ gọ́mìnà àkọ́kọ́ tí a dibò fún ti Bendel State (ọdún 1979 sí ọdún 1983), ó jẹ́ Ọ̀gá Ilé Ìwé ti Government College, Ughelli, olùdásílẹ̀ àti Ọ̀gá Ilé Ìwé Gírámà ti Orogun.[1][2]

Olóyè Demas Onoliobakpovba Akpore ni a bí ní ọjọ́ kẹrin oṣù kẹjọ, ní ọdún 1928 Warri, Nàìjíríà , sí ìdílé Krìstẹ́nì kan. Àwọn òbí rẹ̀ ni Ọ̀gbẹ́ni Itedjere Akpore láti Unukpo, Orogun ní Ughelli North Local Government Area, Ìpínlẹ̀ Delta, àti Arábìnrin Etawhota Akpore (tí ń jẹ́ Agbomiyeri tẹ́lẹ̀) láti Kokori ni Ethiope East Local Government Area ti Ìpínlẹ̀ Delta. Ó jé ọmọ kan ṣoṣo tí ìyá rẹ̀ bí, ó jẹ́ ọmọ tó dàgbà jù nínú ọmọ mẹ́jọ, ó sì jẹ́ àkọ́bí ní ìdílé rẹ̀.

Ìgbà Èwe àti Ẹ̀kọ́ Rẹ̀

àtúnṣe

Nígbà tó ṣi kéré, Demas pàdánù ìyá rẹ̀ lọ́nà tó bá ni lọ́kàn jẹ́, lẹ́yìn èyí ni Mrs. Inaba fi tìfẹ́tìfẹ́ gba sọ́dọ̀, ìyá yìí sì tọ́jú rẹ̀ bí ẹni pé òun ló bi.

Ó bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ilé ìwé àwọn ìránṣẹ́ orí pápá ti St Andrew, ní ìlú Warri, Ìpínlẹ̀ Delta, Nàìjíríà láti ọdún 1937 sí ọdún 1944. Ó sì tẹ̀síwájú lọ sí Ilé Ìwé Gíga fún àwọn olùkọ́ ti Ìjọba, nibi tó tí jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ tí ń tayọ.[3]

Láì tí ó parí ẹ̀kọ́ gírámà rẹ̀ ní ọdún 1951,ó tẹ̀síwájú lọ sí University College, Ibadan, Nàìjíríà láti ọdún 1951 sí ọdún 1956. Ó gba ìwé ẹ̀rí ní ẹ̀kọ́ kílásíkì. Nítorí òye tó ń wá, ó lọ sí University of British Columbia ní Vancouver, Canada, láti ọdún 1956 sí ọdún 1958 níbi tó ti gba Master of Arts degree nínú ẹ̀kọ́ Kílásíkì.

Fún Postgraduate Diploma rẹ̀ nínú ìmọ̀ Ẹ̀kọ́ (PGDE), ó padà lọ sí Yunifásítì ti Ahmadu Bello, Ìpínlẹ̀ Zaria, Nàìjíríà láti ọdún 1974 sí ọdún 1975.

Iṣẹ́ Rẹ̀

àtúnṣe

Nígbà tó ṣi jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ni Ilé Ẹ̀kọ́ Gíga ti Yunifásítì Ìbàdàn, ó lo ìgbà ìsinmi rẹ̀ láti máa kọ́ àwọn ènìyàn ní èdè Látìnì ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gíga ti Urhobo, Effurun, Ìpínlẹ̀ Delta, Nàìjíríà

Lẹ́yìn tó padà láti Ìlú Canada, ó gba isẹ́ olùkọ́ pẹ̀lú Ilé Ẹ̀kọ́ Gíga fún Ètò Ajé (United College of Commerce), Ìlú Warri. Láàárín ọdún 1959 sí ọdún 1962, ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí igbá-kejì Ọ̀gá ilé ìwé, ó sì gba ìgbéga lọ sí ipò Ọ̀gá Ilé ìwé ní ọdún 1962,ipò tí ó dìmú títí dé ọdún 1966,ó ń bójú tó àwọn ọ̀rọ̀ ti Ilé Ìwé náà, ó sì ń tọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ la àkókò ìdàgbàsókè àti ìgbéga.

Ní ọdún kan náà, ó kúrò, ó sì lọ dá ilé ìwé gírámà Orogun, ní Orogun, ìlú rẹ̀. Ó di adárí àti Ọ̀gá ilé ìwé náà títí di ọdún 1973.[3][2]

Nígbà tí ìjọba Ìpínlẹ̀ Bendel gbà ṣàkóso àwọn ilé ìwé àdáni, wọ́n fi Oloye Demas Akpore sípò gẹ́gẹ́ bí Ọ̀gá Ilé Ìwé Government College, Ughelli, nibi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ jáde. Ó ṣiṣẹ́ ni ipò yìí láti ọdún 1973 sí ọdún 1978, ó sì ń fi ìfaraẹnijì àti ìtayọ darí ilé ìwé náà.

Ó kọ̀ láti gba owó gbà-má-bínú láti ọwọ́ ìjọba fún ilé ìwé rẹ̀ láti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òun dá ilé ìwé náà sílẹ̀ fún àwọn ará ìlú òun, òun kò sí ní jèrè láti ibẹ̀f.[4][5]

Ní ọdún 1988, nígbà tí ìjọba ṣí gbèdeké tí wọ́n fi sórí ilé ìwé àdáni, ó tún dá Ilé Ẹ̀kọ́ Idise sílẹ̀ ni Ìlú Warri.

Olóyè Demas Akpore je ọ̀kan lára ọmọ ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ tí Ilé Ẹ̀kọ́ Gíga fún àwọn olùkọ́, Abraka láti ọdún 1973 sí ọdún 1978.[4]

Iṣẹ́ Òṣèlú Rẹ̀

àtúnṣe

Nígbà tí ó wà ní ilé ìwé gíga ni ìlú Ìbàdàn, Olóyè Demas Akpore bẹ̀rẹ̀ sí ní nífẹ̀ẹ́ sí òṣèlú, ó sì dara pọ̀ mọ́ wọ́n, ó di adárí àwọn akẹ́kọ̀ọ́. Ó padà darapọ̀ mọ́ National Council of Nigeria àti the Cameroons (NCNC) ó sì gòkè kíákíá láti di adárí àwọn ọ̀dọ́ ni ẹgbẹ́ tí ó wà, ó sì ń ṣe àfihàn ìfẹ́ tó ní sí dídi adárí ni òṣèlú àti kíkó àwọn ènìyàn jọ.

Ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Zikist National Party Vanguard àti Midwest Democratic Front ní ọdún 1963, ó si kó pá takuntakun nínú iṣẹ́ òṣèlú ti ìgbà náà.

Ó bá Olóyè Dennis Osadebay rìn tímọ́tímọ́, ọ̀kan lára àwọn àgbà òṣèlú tó sí jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n, láti ṣe agbátẹ̀rù fún ìdásílẹ̀ Àgbègbè tí Àárín Ìhà Ìwọ̀ Oòrùn (Midwest Region). Iṣẹ́ wọ́n so èso jáde ní ọdún 1963. Ó tún darí ìtara rẹ̀ nípa ṣíṣe agbátẹ̀rù fún ìdásílẹ̀ Ìpínlẹ̀ Delta. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó wà ní ilé ìwòsàn ni United States nígbà náà, inú rẹ̀ dùn nígbà tó gbọ́ wípé àlá rẹ̀, ìyẹn ìdásílẹ̀ Ìpínlẹ̀ Delta, ti wá sí mù ṣẹ.[6]

Nígbà tí a mú gbèndeké orí iṣẹ́ òṣèlú kúrò ní ọdún 1978, ó dara pọ mọ́ Ẹgbẹ́ Unity ti Nàìjíríà (UPN) ó sì di ọ̀kan lára àwọn aláṣẹ ẹgbẹ́ náà fún ti Ìpínlẹ̀ rẹ̀. Òun ni àwọn ẹgbẹ́ yàn láti ṣe igbá kejì aṣojú Ambrose Folorunsho Alli fún ipò gómìnà ti ẹgbẹ́ rẹ̀ ní ọdún 1979. Wọ́n gbégbá-òróké nínú ìbò náà, a sì yán wọ́n gẹ́gẹ́ bí Gọ́mìnà àti Ìgbá kejì Gómìnà àkọ́kọ́ ti Ìpínlẹ̀ Bendel ti tẹ́lẹ̀, a fi wọ́n sí iṣẹ́ ní ọjọ́ Kínní oṣù kẹwàá, ọdún 1979. Ṣùgbọ́n, ó fiṣẹ́ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí igbá kejì Gómìnà ní ọjọ́ kẹta oṣù kọkànlá, ọdún 1982 fún àwọn ìyàtọ̀ kan tí kò lè gbà mọ́ra.[7][8]. Lẹ́yìn oṣù kan, àwọn agbani pa kòlú, wọ́n si fi sílẹ̀ láti kú.

Ibi tí a ti gba Ìròyìn

àtúnṣe
  • Ahon, Festus Nigeria: "Immortalize Akpore, Activist Urges Delta Government" (Vanguard (Nigeria) 30 December 2008)
  • Akpore, Demas O. "The Question of the Falling Standard of Education: A Policy in Transition, The Nigerian Experience from An Educator's Viewpoint". (A lecture delivered on the occasion of the 1981 University of Ibadan Alumni Association Annual Lectures held at the University of Ibadan, Ibadan, 20 March 1981.
  • Akpoyibo, Marvel- Lagos State Police Commissioner "I never had a girlfriend in school because I was married to my books" (The Punch-Nigeria-By FRIDAY OLOKOR, Published: 20 December 2009)
  • Awhefeada, Sunny. "Remembering Demas Akpore" (National Daily, Nigeria- 27 December 2008)
  • Darra, G.G. "Urhobo and the Mowoe Legacy"(The Guardian, Nigeria-10 August 2005) Professor of English, Delta State University, Abraka/Special Adviser on Public Communications to the Governor of Delta State
  • Eromosele, Victor "Government College Ughelli at 60"(The Guardian, Nigeria 9 November 2005)
  • Olodu, Monn "Much Ado About Delta State Capital"
  • Omu, Stella "Demas Akpore" Administrator, Nigeria federal Ministry of Education.

Àwọn Ìtọ́kási

àtúnṣe
  1. "Memorial lecture: Demas Akpore the man who gave everything to humanity". The News Guru. Retrieved 5 September 2024. 
  2. 2.0 2.1 "Orogun Grammar School: Old Students Set to Honour Akpore". This Day Live. 20 September 2019. 
  3. 3.0 3.1 "Stakeholders recount Demas Akpore's contributions to Nigeria's developmemt". Truth Reporters. 15 December 2021. 
  4. 4.0 4.1 "14 Eminent Orogun Personalities who won African Gold Merit Award Recently". afrikanwatchngr.com. 4 December 2019. 
  5. "OGSO:Old boys to the rescue". This Day Live. 8 November 2019. 
  6. "Ogbemudia Wants Delta Varsity Named After Osadebay". All African stories. 12 April 2004. 
  7. "Urhobo and the Mowoe legacy". Urhobo Digital Library. Retrieved 5 September 2024. 
  8. ""Excessive individualism", bane of Nigeria's underdevelopment". Truth Reporters. 18 December 2021.