Edo State Taskforce Against Human Trafficking (ETAHT)

Edo State Task Force Against Human Trafficking (ETAHT) jẹ́ àjọ-agbófinró orílẹ̀ èdè Nigeria tí ìjọba Ìpínlẹ̀ Edó gbé kalẹ̀ láti dènà kíkó ọmọ ènìyàn lọ sókè òkun lọ́nà àìtọ́ pẹ̀lú àwọn orúkọ burúkú tí ó pèlé e ní ìpínlè náà. Ní báyìí, àwọn Ìpínlẹ̀ mìíràn bí i; Oǹdó, Ọ̀yọ́, Èkó, Enugu, Ekiti àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ tí wo àwòkọ́ṣe Ìpínlẹ̀ Edo láti dá àjọ agbófinró lórí ìwà ìbàjẹ́ kíkó ọmọ ènìyàn ròkè òkun lọ́nà àìtọ́ sílẹ̀.[1]. Ọ̀jọ̀gbọ́n Yinka Omirogbe, ọ̀gá-àgbà àwọn adájọ́ àti Kọmíṣọ́nnà fún ètò ìdájọ́ ní Ìpínlẹ̀ Edo ni Alága àjọ-agbófinró náà.[2] Lọ́dún 2017, Gómìnà Godwin Obaseki ṣe ìfilọ́lẹ̀ àjọ-agbófinró tó ń tako kiko ọmọ ènìyàn ròkè òkun lọ́nà àìtọ́ ní ìpínlè náà.[3] Wọ́n ṣe ìfilọ́lẹ̀ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àjọ náà nílé ìṣèjọba Ìpínlẹ̀ Ẹdó ní Ìlú Benin, tí ó jẹ́ olú-ìlú Ìpínlẹ̀ náà.[4] Àjọ Edo Task Force Against Human Trafficking ni a gbọ́ pé ó ti gba àwọn arìnrìn-àjò lọ́nà àìtọ́ tó tó 5,619 padà láti orílẹ̀ èdè Libya, tí wọ́n ń gbìyànjú láti ròkè òkun sí ilẹ̀ Europe láti ọdún 2017 títí asiko yìí .[5]

Edo State Task Force Against Human Trafficking (ETAHT)
Agency overview
Formed 2017
Jurisdiction Edo State
Website
etaht.org/

Wọ́n dá àjọ-agbofinro yìí sílẹ̀ pẹ̀lú aṣojú láti àjọ agbófinró lorisirisi, àwọn àjọ tí kìí ṣe tí ìjọba NGOs, àjọ NAPTIP MDAS, àjọ àwọn ẹ̀sìn gbogbo.[6]

Àwọn Àfojúsùn

àtúnṣe

Láti fòpin sí òwò-ẹrú ìgbàlódé tí wọ́n ń pè ní Kíkó àwọn ọmọ ènìyàn ròkè òkun lọ́nà àìtọ́, àti rí i pé wọ́n ran àwọn ènìyàn tí wọ́n gbà padà láti gbé ìgbé ayé tó dára láwùjọ.[7]

Àwọn èròǹgbà

àtúnṣe
  • Láti ṣe àdínkù sí ìṣòro àti ọ̀ràn kíkó ọmọ ènìyàn ròkè òkun lọ́nà àìtọ́ ní Ìpínlẹ̀ Ẹdo.
  • Láti ran àwọn tí wọ́n lùgbàdì ìwà burúkú yìí láti di ènìyàn tó dára padà láwùjọ ní Ìpínlẹ̀ Edo
  • Láti ṣe ìwádìí àti ìgbé lárugẹ àwọn ọgbọ́n-inú láti gbégi dínà ìwà ọ̀daràn yìí ní Ìpínlè Edo
  • Láti ni ìbáṣepọ̀ tó dára pẹ̀lú àwọn àjọ mìíràn pẹ̀lú èròǹgbà láti gbégi dínà ìwà ọ̀daràn yìí ní Ìpínlẹ̀ Edo

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́

àtúnṣe
  • Professor (Mrs) Yinka Omorogbe - Alága àjọ-agbofinro
  • Barr. Mrs Abieyuwa Oyemwense - Akọ̀wé

Àwọn Alábáṣepọ̀ àti Alájọṣe

àtúnṣe

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "EU SUPPORTS NAPTIP TO ESTABLISH KANO STATE HUMAN TRAFFICKING TASK FORCE". A-TIPSOM. 31 August 2021. Retrieved 30 March 2022. 
  2. "Obaseki sets up task force to tackle human trafficking". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2017-08-15. Retrieved 2022-03-30. 
  3. "Obaseki Inaugurates Task Force On Anti-Human Trafficking". ChannelsTV. 16 August 2017. Retrieved 30 March 2022. 
  4. "U.S. Applauds Edo State’s Integrated Anti-Human Trafficking Framework". U.S. Embassy & Consulate in Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-03-27. Archived from the original on 2021-11-24. Retrieved 2022-03-30. 
  5. "Edo receives 5,619 Libya returnees in four years -- Official" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-03-18. Retrieved 2022-03-30. 
  6. "Nigeria heeds global call, sets up State Task Force against human trafficking". www.unodc.org. Archived from the original on 2022-03-30. Retrieved 2022-03-30. 
  7. "Edo govt, IOM strengthen ties in fight against human trafficking". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-02-20. Retrieved 2022-03-30.