Ekei Essien Oku
Ekei Essien Oku ( ti a bini ojo keji-le-logun Oṣu Kini, odun 1924 – ojo kẹrindilogun Oṣu Kẹwa Ọdun 2004) jẹ olumojuto ile-ikawe ọmọ orilẹede Naijiria, ako itan, ati Akọwe . Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ilé-ìkàwé àkọ́kọ́ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti obìnrin àkọ́kọ́ tí ó jẹ́ Olóye Ilé-ìkàwé ní Nàìjíríà. Ó ti tẹ ìwádìí rẹ̀ jáde nínú ìtàn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó dá lórí àkọsílẹ̀ àwọn mílosiọ́nnárì tí wọ́n ṣàkọsílẹ̀ àkókò tí wọ́n fi dá àwọn ìlú sílẹ̀ ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún.
Ekei Essien Oku | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Calabar | 22 Oṣù Kínní 1924
Aláìsí | 16 October 2004 | (ọmọ ọdún 80)
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Ẹ̀kọ́ | Queen's College, Lagos and North Western Polytechnic |
Iṣẹ́ | Chartered Librarian |
Gbajúmọ̀ fún | writing Nigerian history |
Olólùfẹ́ | Chief Essien Oku 1956 |
Àwọn ọmọ | one son, two daughters |
Igbesi aye
àtúnṣeIlu Calabar ni won bi Oku si, ni osu kini odun 1924. O ti lo ile ẹkọ ni Nijiria, Queen's College, Lagos . Ó kọ́kọ́ ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ kí ó tó lọ ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí akọ̀wé, wọ́n sì rán lọ Lọndọnu láti lọ kẹ́kọ̀ọ́ ní North Western Polytechnic (ti o je Yunifásítì ti North London ni isin). Ó padà sí Nàìjíríà níbi tí ó ti di obìnrin àkọ́kọ́ láti Nàìjíríà tí ó di òṣìṣẹ́ ilé-ìkàwé ní ọdún 1953. Eyi jẹ ọdun meji pere lẹhin ọkunrin akọkọ, Kalu Chima Okorie, ni ọdun 1951. O jẹ obinrin akọkọ olori ile-ikawe ni Nigeria ni ọdun 1964 . [1] ó sì di ipò náà mú ní Calabar àti ní Èkó .
Oku ṣe iwadi osi kọwe ti a pe akole re ni "The Kings and Chiefs of Old Calabar (1785-1925)". Iwe naa jade ni ọdun 1989. [2] Ó kẹ́kọ̀ọ́ akosile ise ti àwọn míṣọ́nnárì ṣe, títí kan ìgbà ẹrú, ó sì gbà pé àwọn ẹrú náà ṣè atìlẹ́yìn fún ọ̀gá wọn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹrú náà fẹ́ òmìnira lẹ́yìn tí awọn ọ̀gá wọn ba ku, wọ́n láti reti ìdájọ́ òdodo tàbí ẹ̀san fún àwọn tí ó pa ọ̀gá wọn. [1]
Oku jẹ eyan mimo ni ọdun 2000 nipasẹ The British Broadcasting Corporation (BBC) ni ikẹkọ idaji kan igbesi aye ati iṣẹ rẹ “Irisi Afirika”. O ku ni ọjọ kẹrindilogun Oṣu Kẹwa Ọdun 2004, ni gba to pe ogorin . [3]
Awọn itọkasi
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 African Voices on Slavery and the Slave Trade: Volume 1, The Sources. https://books.google.com/books?id=XKIaBQAAQBAJ&q=Ekei+Essien+Oku&pg=PA446.
- ↑ The Kings & Chiefs of Old Calabar (1785-1925). https://books.google.com/books?id=UKwsAAAAIAAJ&q=The+Kings+and+Chiefs+of+Old+Calabar.
- ↑ Antera Duke, The Diary Of Antera Duke, An Eighteenth-century African Slave Trader