Eucharia Oluchi Nwaichi
Eucharia Oluchi Nwaichi jẹ́ ọ̀mọ̀wé ìmọ̀ ẹ̀yà Biochemistry, tí ó ní se pẹ̀lú àyíká. Ó tún jẹ́ onímọ̀n Toxicology. Ó gba àmì ẹ̀yẹ tí àwon olóyìnbó n pè ní L'Oreal-UNESCO Awards fún àwon obìnrin ní odún 2013 fún iṣẹ́ rẹ̀ lórí " ìjìnlẹ̀ ṣàyẹnsí ojutú sí àyík á èérí. Ó sì jẹ́ ikeji ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lati ẹ̀yà íbò lóbìnrin tí ó gba àmì ẹ̀yẹ L'Oreal-UNESCO Awards fún àwon obìnrin nínú ìmọ̀ Síáyẹ́nsì.[1][2]
Ìgbésí ayé
àtúnṣeA bí ọ̀mọ̀wé Nwaichi si Ìpínlẹ̀ Ábíá sí idílé Ọ̀gbẹ́ Donatus Nwaichi ti ìlú Ábíá. Ó ní báṣẹ́lọ̀ (B.SC) ati másíta Síáyẹ́nsì (B.Sc) pẹ̀lú dókítọ́réti nínú ìmọ̀ Biochemistry lati Yunifásítì ìlú Port hacourt níbi tí ó tí padà di olùkọ́ ìmọ̀ Biokẹ́mísìrì . kí ó tó darapọ̀ mọ́ Yunifásítì ìlú Port hacourt, Ó ṣiṣẹ́ ilẹ́ "Shell Oil" fún odún kan péré. Iṣẹ́ rẹ̀ tó dáyatọ̀ nínú ìmọ̀ Síáyẹ́nsì ni ó jẹ́ kì ó gba àmì ẹ̀yẹ ti L'Oreal-UNESCO ni odún 2013.[3][4]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ "Nigerian Shines UNESCO Science Laureate wins-$100,000-NAN". Sahara Reporters. Retrieved November 13, 2015.
- ↑ "Eucharia Oluchi Nwaichi Port harcourt studies how to remove arsenic and copper from polluted soil". Star Africa. Retrieved November 13, 2015.
- ↑ "Two Nigerian Scientists bag UNESCO LOreal 2013 award". Vanguard News. Retrieved November 13, 2015.
- ↑ "Nigerian Women whocracked science". The Sun Newspaper. Retrieved November 13, 2015.