Fúnmi Martins
Fúnmi Martins tí wọ́n bí ní ìlú Iléṣà ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ní inú oṣù Kẹsàn án ọdún 1963 jẹ́ òṣèré orí-ìtàgé àti sinimá àgbéléwò ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. [1]
Olúwafúnmi Martins | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Olúwafúnmi 1963 Iléṣà, Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, |
Aláìsí | Ìpínlẹ̀ Èkó |
Orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Iṣẹ́ | Òṣèré orí-ìtàgé |
Àwọn ọmọ | Midé Fúnmi Martins, Ayọ̀ Martins. Àkanbí Ayọ̀mípọ̀ |
Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀
àtúnṣeWọ́n bí Fúnmi ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ní inú oṣù Kẹsàn án ọdún 1963, ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Òkè-Ọnà àti ilé-ẹ̀kọ́ girama ní Ìlú Abẹ́òkúta ní Ìpínlẹ̀ Ògùn. Lẹ́yìn ẹ̀kọ́ girama, ó tẹ̀ siwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Beepo Secretarial Institute ní ìlú Ìbàdàn níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ gba ìwé-ẹ̀rí dípúlọ́mà nínú ìmọ̀ Secretariate.
Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣèré
àtúnṣeFúnmi kọ́kọ́ se modeling fúngbà díẹ̀ ṣáájú kí ó tó bẹrẹ ẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ eré orí-ìtàgé. Ó di ìlú-mòọ́ká látara eré kan tí ọ̀gbẹ́ni Fidelis Duker gbé jáde ní ọdún 1993. Ó kópa nínú àwọn eré ọlọ́kan-ò-jọkan ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní àsìkò ọdún 1990s. Lásìkò yí, àwọn òṣèré orí-ìtàgé bí Fúnmi Martins, Adébáyọ̀ Sàlámì àti àwọn díẹ̀ kan ni wọ́n lè sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì láti fi kópa nínú eré tí a fi èdè Yorùbá àti èdè Gẹ̀ẹ́sì gbé jáde.[2][3]
Àwọn àsàyàn eré rẹ̀
àtúnṣeÓ ti kópa lààmì-laaka nínú àwọn onírúurú eré bíi:
- Ìjà ọmọdé
- Ẹrù ẹlẹ́rù
- Ẹ̀tọ́ mi
- Pẹ̀lú mi ati bẹ̀ẹ́ bẹ̀ẹ́ lọ.
Ìgbé ayé rẹ̀
àtúnṣeFúnmi bí ọmọ méjì fún ọkọ àárọ̀ ọjọ́ rẹ̀, ìyẹn Mide Martins àti Ayọ̀ Martins. Lẹ́yìn tí ìgbéyàwó òun ati ọkọ rẹ̀ akọ́kọ́ forí ṣọ́pọ́n ni ó tún fẹ́ gbajú-gbajà olórin Afro jùjú tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Sir Shina Peters tí ó sì bímọ ọkùnrin tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Àkànbí Ayọ̀mípọ̀ Peters ní ọdún 2002.
Ikú rẹ̀
àtúnṣeFúnmi papò dà ní ọmọ ọdún méjìdínlógójì nkan bí oṣù méjì lẹ́yìn tí ó bímọ rẹ̀ tán látàrí àìsàn ọkan. Ó kú sí ilé ìwòsàn kan ní agbègbè Agége ní ọjọ́ Karùn-ún oṣù Karùn-ún ọdún 2002. [4]
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Orodare, Michael (2020-03-11). "Remembering Funmi Martins: Nollywood actor who left early but left an heir". Nigerian Entertainment Today. Retrieved 2020-10-23.
- ↑ "Sam Loco, Funmi Martins, other Nollywood stars we miss". Latest Nigeria News, Nigerian Newspapers, Politics. 2020-02-11. Retrieved 2020-10-23.
- ↑ "The Story Of The Life And Death Of Legendary Yoruba Actress, Funmi Martins". GQBuzz.com. 2018-01-04. Archived from the original on 2020-10-27. Retrieved 2020-10-23.
- ↑ Falae, Vivian (2018-01-04). "The truth about Funmi Martins death revealed". Legit.ng - Nigeria news. Retrieved 2020-10-23.