Gbàngàn Tafawa Balewa Square

Gbàngàn pápá ìṣeré Tafawa Balewa, (TBS) jẹ́ ilẹ̀-ayẹyẹ tí ó tó sààre ilẹ̀ bí ìwọ̀n 35.8 acres (14.5 ha) èyí tí a àkọ́kọ́ pè ní (Ilé Eré-ìje”) èyí tí ó wà ní Erékùṣù, EÌpínlẹ̀ Èkó . [1] [2]

Ìtàn nípa gbàgàn yí

àtúnṣe

Ilé Eré-ìje Ìpínlẹ̀ Èkó tí ó ti di TBS báyìí ni ó jẹ́ pápá tí ìfẹṣin sáré ìdárayá tẹ́lẹ́ ní ìlú Èkó tí wọ́n sì ya apá ibì kan sọ́tọ̀ fún eré bọ́ọ́lù aláfẹsẹ̀gbá àti àyè kan fún eré bọ́ọ̀lù ẹlẹ́yin orí ilẹ̀. Wọ́n yan ilẹ̀ náà fún àwọn ìjọba amúnisìn tí ó ń ṣàkóso lórí ilẹ̀ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ nípa àṣẹ Ọba Dosunmu ní ọ̀dún 1859, tí ó sì padà mú ìdàgbàsókè bá agbègbè náà. Pápá náà ni ó ọ̀ Ọ̀gágun Yakubu Gowon wo palẹ̀ tí ó sì yi padà sí gbàgàn Tafawa Balewa Square.Nígbà pápá yí wà l loju iṣẹ́, àwọn ìlà eré-ìje fún àwọn esin tí Ó ń sáré níbẹ̀ tó méje sí mẹ́jọ, tí wọ́n sì gùn tó ibùsọ kan (1 mile).[3]

Ní ọdún 1960, wọ́n tún pápá yí ṣe láti fi sàmì ayẹyẹ òmìnira orílẹ̀-èdè Nàìjíríà , tí wọ́n sì fa àsíá orílẹ̀-èdè Gẹ̀ẹ́sì amúnisìn wálẹ̀.

Ibi tí gbàgàn yí wà

àtúnṣe

Gbàngàn TBS tí wọ́n kọ́ ní ọdún 1972 fìdí ti òpópónà Awólọ́wọ̀ Cable Street, ọ̀nà Fọ́ọ̀sì, ọ̀nà Catholic Mistree àti 26-storey independence building.

Gbàgàn yí bí ohun mánigbàgbé

àtúnṣe

Ẹnu àbáwọlé gbàgàn yí ni àwọn ère ẹṣin mẹ́rin tí a ṣe ànọ̀ rẹ̀ lọ́jọ̀ pẹ̀lú àwọ̀ funfun báláu, àti àwọ́n éyẹ àṣá méje tí a ṣe ọ̀nà wọn pẹ̀lú àwọ̀ pupa tí wọ́n ń ra bàbà lójú ọ̀run, tí àwọn ìṣeẹ́ ọ̀nà yí sì ń tọ́ka sí àmì Agbára àti Iyì gẹ́gẹ́ bí àkọmọ̀nà orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Àwọn ohun ará ọ̀tọ̀ tí ó jẹ́ mánigbàgbé nì 1(àmì ìrántí Ogun Àgbáyé Àkọ́kọ́ (I). Ogun Àgbáyé Ẹlẹ́kejì II àti àwọn tó fara káṣá nínú Ogun Abẹ̀lé Ilẹ̀ Nàìjíríà , tí ó sì tún dúró fún (the26-storey Independence House), tí wọ́n kọ́ ní ọdún 1963, tí ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ilé tí ó ga jùlọ fún ìgbà pípẹ́ jùlọ ní orẹ̀-èdè Nàìjíríà.[4]

Àwọn ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀

àtúnṣe

Gbàngàn yí gba àwọn ènìyàn tí ó tó ẹgbẹ́ẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Àwọn aye bí ibi ìtajà oríṣiríṣi, ilé ońjẹ, àyè Igbóọ́kọ̀ sí, àti ibi tí wọ́n ti ń Ṣé tó ìwé ìrìnà lè sókè òkun.[5]

Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì tí ó ti wáyé níbẹ̀ rí

àtúnṣe

Lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ti wáyé tí ó kẹ́ mánigbàgbé ni ayẹ̀yẹ ìgbòmìnira tí ó wáyé ní Ọjọ́ Kíní oṣù Kẹwàá, ọdún 1960 (1-10-1960), tí Olórí Mínísítà nígbà náà Tafawa Balewa, sì bá àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà sọ̀rọ̀. Lára rẹ̀ náà ni ayẹyẹ ọjọ́ Òṣèlú Àwa-Ara wa (Democracy Day), àti àwọn mìíràn bí ìpàgọ́ orin àti ìpàgọ́ àti ìpéjọ pọ̀ àwọn ẹlẹ́sìn gbogbo.[6]

Àwọn ìtọ́ka sí

àtúnṣe
  1. Lagos: A Cultural and Literary History (Landscapes of the Imagination). https://books.google.com/books?id=fcS_BAAAQBAJ&pg=PT192&dq=. 
  2. "BUILDING THE LAGOS CENTRAL BUSINESS DISTRICT". Archived from the original on 18 May 2015. https://web.archive.org/web/20150518085721/http://www.thisdaylive.com/articles/building-the-lagos-central-business-district/198358/. 
  3. Ajani, Jide (October 1, 2000). "The Lagos Race Course: Crossroads of a Political Heritage". Vanguard. https://allafrica.com/stories/200010010011.html. 
  4. Kaye Whiteman (2013). Lagos: A Cultural and Literary History (Landscapes of the Imagination). 5. Andrews UK Limited. ISBN 978-1-908-4938-97. https://books.google.com/books?id=fcS_BAAAQBAJ&pg=PT192&dq=. 
  5. "Is Tafawa Balewa Square The Forgotten Race Course Of Independence?" (in en-US). Nigeria Real Estate Hub. 2015-09-30. Archived from the original on 2018-10-28. https://web.archive.org/web/20181028231102/https://nigeriarealestatehub.com/tafawa-balewa-square-the-forgotten-race-course-of-independence.html/. 
  6. "‘Tafawa Balewa Square leased, not sold’ - The Nation Nigeria". http://thenationonlineng.net/tafawa-balewa-square-leased-not-sold/.