Gogo Chu Nzeribe

Olóṣèlú

Gogo Chu Nzeribe jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kan tó jẹ́ òṣìṣẹ́ òwò àti aṣáájú ẹgbẹ́ Kọ́múníìsì ní orílẹ̀-èdè náà nígbà ìgbòkègbodò òmìnira ní àwọn ọdún 1950. [1] Òun ni akọ̀wé àgbà fún Ẹgbẹ oníṣòwò Nàìjíríà, èyí tí Aare Michael Imoudu jẹ́ olórí nígbà náà. Nzeribe tí a pa ní ọdún 1967 nípasẹ̀ àwọn ọmọ ogun olótìítọ́ si igun ti ìjọba àpapò lákòókò rògbòdìyàn ti ọdún 1960. Ṣáájú ikú rẹ̀, ìjọba Yakubu Gowon ni wọ́n ti mú, tí wọ́n sì ti fi ṣémọ́lé ní Dodan Barrack.

Ó ní ọmọbìnrin kan pẹ̀lú Òǹkọ̀wé orílè-èdè Nàìjíríà, ìyẹn Flora Nwapa.[2]

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀

àtúnṣe

A bí Nzeribe sí ìdílé tó dára ó sì lọ sí ilé ìwé King's College,ní ìlú Èkó. Ó yipada di ọ̀kan lára ẹgbẹ iṣowo nítorí ìfẹ́ rẹ sí ìjàjàǹgbara Nàìjíríà fún òmìnira. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣètò àwọn ọmọ ilé-ìwé àti àwọn àpéjọ òṣìṣẹ́ lòdì sí ìjọba amúnisìn.[3]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. American Assembly. United States and Africa, American Assembly, Ayer Publishing, 1970. p 91. ISBN 0-8369-1781-2
  2. Chikwenye Okonjo Ogunyemi. African Wo/Man Palava: The Nigerian Novel by Women, University of Chicago Press, 1996. p 134. ISBN 0-226-62085-9
  3. Steven L. Jacobs, Samuel Totten. Pioneers of Genocide Studies (Clt), Transaction Publishers, 2002. p 142. ISBN 0-7658-0151-5