Janet Akinrinade
Janet Akinrinade (1930 - 1994) fìgbà kan jẹ́ olóṣèlú orílẹ̀-èdè Naijiria, òun sì ni Mínísítà ìlú lásìkò ìjọba Shehu Shagari.[1] Ní àsìkò ìdìbò ti ọdún 1977, òun nìkan ni obìnrin tí wọ́n dìbò wọlé fún.[2]
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀
àtúnṣeÌlú Iseyin ni wọ́n bí Janet sì, wọ́n bí i sínú ìdílé ọlọ́mọ mẹ́rin, òun ni àbígbẹ̀yìn, òun sì nìkan sì ni obìnrin tí àwọn òbí rẹ bí. Ó pàdánù àwọn òbí rẹ̀ nígbà tí ó ṣì kéré. Ẹ̀gbọ́n àgbà kan ló gbà á tọ́, ó sì ṣètò ẹ̀kọ́ rẹ̀, ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ nìkan ló gbà. Kò lọ ilé-ìwé gírámà, àmọ́ ó yege nínú ìdánwò ilé-ìwé gírámà nípa kíkọ́ ara ẹni. Ní ọdún 1950, ó fẹ́ T.A Akinrinade tó jẹ́ alámòójútó ilé-iṣẹ́ tábà kan, níṣu lọ́kà. Ní ọdún 1957, ó kẹ́kọ̀ọ́ Secretarial Studies, Cookery and Dress Making ní ìlú London. Ní ọdún 1964, ilé-iṣẹ́ ọkọ rẹ̀ ní ọ̀rọ̀ gbọ́nmisi-omi-ò-to pẹ̀lú àwọn àgbè tábà kéékèèké, Akinrinade kó ipa ribiribi láti ri pé àlàáfíà jọba. Nítorí ipá ribiribi tó kó nínú ọ̀rọ̀ ọ̀hún, Ṣọ̀ún Ogbomosho ìgbà náà fi òun àti ọkọ rẹ̀ joyè ní ìlú náà.
Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi olóṣèlú
àtúnṣeÓ kò sínú iṣẹ́ olóṣèlú ní ọdún 1970, nígbà náà ni wọ́n dìbò fún tó wọlé ipò Kanselo Iseyin, ó wà nípò náà fún ọdún méje. Ní ọdún 1977, Akinrinade wọlé ìdìbò láti darapọ̀ mọ́ Constituent Assembly. Lẹ́yìn ọdún kan, ó darapọ̀ mọ́ Nigerian People's Party, òun sì ni amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ gómìnà ẹgbẹ́ náà ní ọdún 1979. Ìbáṣepọ̀ láàrin ẹgbẹ́ Akinrinade àti ẹgbẹ́ gómìnà Ìpínlẹ̀ náà lásìkò yẹn ló mu kí wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bíi Mínísítà nígbà ìjọba náà.
Ní ọdún 1982, ó fi ipò Mínísítà síl, ó sì di Kọmíṣọ́nà Ìpínlẹ̀ Plateau, lábẹ́ ìjọba Solomon Lar.