Janet Edeme jẹ́ onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó ní ṣe pẹ̀lú ohun ọ̀gbìn ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú ohun ọ̀gbìn, tí ó ṣiṣẹ́ bí Olùdarí ẹ̀ka (Rural Economy and Agriculture at the African Union Commission - AUC/DREA), tí ó wà ní Addis Ababa, Ilẹ̀ Ethiopia. AUC/DREA jẹ́ ẹ̀ka kan láàrín Ìṣọ̀kan Áfíríkà, tí ó ní ìdúró fún ìgbéga, ìdàgbàsókè ìgbèríko alágbèrò nípasẹ̀ iṣẹ́-ọ̀gbìn àti ìlọsíwájú ti ààbò oúnjẹ ní gbogbo ilẹ̀ Áfíríkà. [1][2]

Janet Edeme
Ọjọ́ìbíNigeria
Orílẹ̀-èdèNigerian
Ọmọ orílẹ̀-èdèNigeria
Ẹ̀kọ́University of Ibadan
(Bachelor of Science)
(Master of Science)
Texas A&M University
(Doctor of Philosophy)
Iṣẹ́Agricultural Scientist and Plant Biologist
Ìgbà iṣẹ́1980 to present

Ayé Àti Ẹ̀kọ́ Rẹ̀

àtúnṣe

Edeme jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí wọ́n bí, tó dàgbà, tó sì kẹ́kọ̀ọ́ ní orílẹ̀-èdè rẹ̀. Arábìnrin náà gba oyè Master of Science nínú Agricultural Biology, pẹ̀lú ìmọ̀ nípa ohun ògbìn tí ó dá lé lórí, Yunifásítì ìlú Ìbàdàn fún un ní àmì-ẹ̀yẹ. Dókítà rẹ̀ nínú ìwé-ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ọgbọ́n orí ni wọ́n fún ní ilé ẹ̀kọ́ gíga ní Fásítì Ìbàdàn, Fásítì ti Texas A&M, ní College Station, Texas, United States àti International Institute for Tropical Agriculture (IITA), ní Ìbàdàn. [3]

Ìrírí Rẹ̀ Lórí Iṣẹ́

àtúnṣe

Iṣẹ́ àti ìwádìí Edeme dá lórí ààyè ti ìmọ̀-ògbìn. Ó ṣe ìwádìí ti (post doctoral) ní International Livestock Research Institute (ILRI), ní ìlú Nairobi, ní ilẹ̀ Kenya. Ó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ tí ó lọ, Fásítì Ìbàdàn. Ó tún ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùgbaninímọ̀ràn sí àwọn àjọ tí ó mọ̀ọ́mọ̀, pẹ̀lú Eto Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Lórí HIV/AIDS (Joint United Nations Programme on HIV/AIDS - UNAIDS) àti àjọ tó ń bójú tó Oúnjẹ àti Àgbẹ̀ ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè - Food and Agricultural Organisation of the United Nations (FAO). [3]

Ohun Mìíràn Tí A Mọ̀ ọ́ Fún

àtúnṣe

Edeme jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ti Ìgbìmọ̀ Alákoso ti àwọn irúgbìn Áfíríkà, àjọ láàrín ìjọba, láàrín Ìṣọ̀kan Áfíríkà (African Union), tí ó ní ìdúró fún ìmuṣe Ètò African Seed and Biotechnology Programme. [3]

Àwọn Ìtọ́ka Sí

àtúnṣe
  1. Africa Lead (24 September 2015). "African Union, Africa Lead Agree to Collaborate on Support for Malabo Declaration and New Alliance". Bethesda, Maryland: Africaleadftf.org (Africa Lead). Archived from the original on 15 August 2021. Retrieved 21 November 2017. 
  2. FAO (22 June 2016). "AUC and FAO determined to promote agricultural mechanization". Food and Agriculture Organization of the United Nations (FAO). Archived from the original on 15 August 2021. Retrieved 21 November 2017. 
  3. 3.0 3.1 3.2 AfricaSeeds (21 November 2017). "AfricaSeeds: Governing Board". Abidjan: Africa-seeds.org (AfricaSeeds). Retrieved 21 November 2017.