Joel Olaniyi Oyatoye

(Àtúnjúwe láti Joel Olaniyi Ọyátóyè)

Ọmọ Ọba Joel Ọláníyì Ọyátóyè tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Bàbá Àṣà, jẹ́ ọmọ bíbí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti Kánádà, ó jẹ́ akọ ewì, olùgbóhùnsafẹ́fẹ́, oníṣẹ́ ara-ẹni, ajíyìnrere, olùpolongo àti olùgbélárúgẹ àṣà àti ìṣe Yorùbá. [1]

Ibẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n bí Ọláníyì ní Ìpínlẹ̀ Kwara ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni 27 January, 1984 níbi tí ó ti lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama ṣáájú kí ó tó lọ sí orílẹ̀-èdè Canada láti lọ tẹ̀ siwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀.

Ọyátóyè tí ó jẹ́ ọmọọba nífẹ́ sí gbígbé àṣà Yorùbá lárugẹ jákè-jádò agbáyé, pàá pàá jùlọ bí ó ṣe ma ń wọ aṣọ ìbílẹ̀ tí ó sì ń lo gbogbo ohun èlò ìbílẹ̀ Yorùbá láti fi pàtàkì àṣà Yorùbá hàn fáyé rí. Ọyátóyè jẹtọ́ àṣà òun ìgbéga Yorùbá láti kékeré láti ara bàbá rẹ̀ Olóyè Titus Ọyátóyè Títíloyè tí ó ti dolóògbé. Iya re Cicilia Oyatoye

Iṣẹ́ rẹ̀

àtúnṣe

Ọyátóyè ṣàkíyèsí wípé iná àṣà àti ìṣe Yorùbá ti ń jó àjórẹ̀yìn, èyí kò sì bójúmu, àìbìkítà sí ìgbéga àṣà òun ìṣe Yorùbá lè ṣakóbá fún láti ròkun ìgbagbé. Èyí ni ó múmú láyà rẹ̀ tí ó fi ń gbé àdá Yorùbá lárugẹ. [2] Ifẹ́ rẹ̀ sí èdè Yorùbá ni ó mu kọ́ṣẹ́ nípa ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ láti lè ma polongo ohun ina àjogúnbá Yorùbá lórí afẹ́fẹ́. Ó ti ṣe àwọn ìṣeẹ́ àkànṣe nípa èdè, àṣà Yorùbá gẹ́gẹ́ olùgbóhùnsafẹ́fẹ́ pàá pàá jùlọ lórí àwọn ilé-iṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ bíi: Paramount FM tí ó wà ní ìlú Abẹ́òkúta, Radio Lagos tí ó wà ní ìlú Ìkẹjà, Choice FM . Ó gbajúmọ̀ fún [[ewì][ kíké, Rárá sísun, ìjálá, ẹkún ìyàwó sísun àti oríkì kíké.[3] Láti lè mú èrò àti àlá rẹ̀ ṣẹ, ó gbéra lọ sí orílẹ̀-èdè Canada láti lọ kẹ́kọ̀ọ́ tí ó sì ń ṣiṣẹ́ mọ. Ó lọ ilé ẹ̀kọ́ Red River College, àti Academic College tí àwọn méjèjì wà ní agbègbè Winnipeg ní ìlú Canada, O ko eko nipa Eto isiwa (Immigration Consultant) ni Ashton College British Columbia Canada. Ó ti ṣisẹ́ pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ ààbò Impact Security láàrín ọdún 2013 sí 2015, bákan náà ni ó ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú St Amant láàrín ọdún 2013 sí 2020 ní orílẹ̀-èdè Canada. Lati 2020 o ti n sise Ara re. O je Aare ati Oludasile Egbe ti a n pe ni Asa Day Worldwide Inc. Canada, ti n se igbe laruge Asa Yoruba kakiri agbaye, Oun si tun ni Oludasile ati alamojuto Asa Day Museum ni Canada.

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Daniels, Ajiri (2021-12-26). "Olaniyi Oyatoye: Young Yoruba art, culture enthusiast". The Sun Nigeria. Retrieved 2023-07-25. 
  2. "‘Why I am celebrating Yoruba culture in Canada’". Tribune Online. 2019-08-08. Retrieved 2023-07-25. 
  3. "Olaniyi Oyatoye: How I Ply my Cultural Promotion Trade". THISDAYLIVE. 2021-09-03. Retrieved 2023-07-25.