Hassan Kehinde Daniel tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Kent Edunjobi jẹ́ akọrin àti olùpilẹ̀ṣẹ̀ orin ní Nàìjíríà.[1][2]

Ìgbésí ayé àti iṣẹ́ rẹ̀

àtúnṣe

Kehinde kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀-ẹ̀rọ kọ̀m̀pútà àti ìṣirò ní University of Nigeria, Nsukka.[3] Kehinde bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ orin rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i ọmọ-ẹgbẹ́ akọrin Apex Choir tí Celestial Church of Christ níbi tí ó ti jẹ́ olùdarí ẹgbẹ́ náà báyìí. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Kunle Afolayan Productions ní ọdún 2016, láti ìgbà náà sì ni ó ti ń kọ orin fún ìṣejáde ilé-iṣẹ́ náà.

Ní ọdún 2023, ó bọ́ sí gbàgede lẹ́yìn tí ó kọ orin nínú fíìmù Aníkúlápó [4]. Ní ọdún kan náà ni ó ṣàgbéjáde Ebenezer tí ó kọ pẹ̀lú Apex Choir. Àwọn ènìyan 1 million ló wo fọ́nrán yìí ní YouTube, ní oṣù àkọ́kọ́ tí ó jáde.[5]

Àwọn orin rẹ̀

àtúnṣe
Àwọn orin inú fíìmù
Odun Fiimu
Ọdun 2023 Aníkúlápó
2021 A Naija Christmas
2021 King of Boys: The Return of the King
2020 Citation
2018 Diamonds in the Sky
2017 The Bridge
2017 Swallow
2017 Roti
Àwọn orin àdàkọ
Ọdún Orin Ref
Ọdun 2023 Ebenezer [5]

Àwọn ẹ̀bùn

àtúnṣe
  • Orin inú fíìmù tó dára jù lọ ní ayẹyẹ Africa Movie Academy fún Citation.[6]
  • Orin inú fíìmù tó dára jù lọ, ní ayẹyẹ Africa Magic Viewers' Choice Awards, ti ọdún 2023, fún Aníkúlápó.[7][8]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Ogunsunlade, Imisioluwa (2022-11-02). "Kent Edunjobi: The Folk Music Maestro Drawing Audience Into the World of Make-Believe With His Soundtracks". Nigerian Entertainment Today (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-08-09. 
  2. 36Extra.com (2024-04-12). "Stream And Download All Kent Edunjobi Song's". 36Extra.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2024-04-12. 
  3. "Kent Edunjobi : Sound Track Side of Movies Now Taken Seriously - THISDAYLIVE". www.thisdaylive.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-08-09. 
  4. Ajose, Kehinde (2022-10-15). "How I made soundtracks for 'Anikulapo' – Kent Edunjobi". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-08-09. 
  5. 5.0 5.1 https://thenationonlineng.net/ebenezer-made-me-fear-god-more-kent-edunjobi/
  6. Ajose, Kehinde (2023-06-18). "I didn't envisage the success of 'Ebenezeri' – Kent Edunjobi". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-08-09. 
  7. "Ọ̀rọ̀ inú orin "Ebenezeri" kó àwọn Mùsùlùmí àti gbogbo ìjọ ìgbàlódé wá sí Cele, ìdí rèé - Kent Edunjobi". BBC News Yorùbá. 2023-06-09. Retrieved 2023-08-09. 
  8. Alabi, Tope (2023-05-21). "AMVCA 2023: Full list of winners". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-08-09.