Aníkúlápó jẹ́ fíìmù onítàn àròsọ Nàìjíríà ọdún 2022 tí Kúnlé Afọláyan ṣe tí Netflix sì pín kiri. Wọ́n gbé e jáde lọ́jọ́ ọgbọ̀n oṣù kẹsàn-án ọdún 2022, àwọn òṣèré Hakeem Kae-Kazim, Ṣọlá Ṣóbọ̀wálé, Kúnlé Rẹmí, Bím̀bọ́ Adémóyè, ati Táíwò Hassan ló kó ipa aṣáájú.[1][2] Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni wọn ya eré, Afọláyan sì ti júwe eré yìí gẹ́gẹ́ bí “Game of Thrones tí a ṣe ní Nàìjíríà ṣùgbọ́n èyí tí a fi ojú ìwòye àṣà wa (àṣà Yorùbá) ṣe”.[3][4]

Aníkúlápó
AdaríKúnlé Afọláyàn
Olùgbékalẹ̀Kúnlé Afọláyan
Àwọn òṣèré
OlùpínNetflix
Déètì àgbéjáde
  • 30 Oṣù Kẹ̀sán 2022 (2022-09-30)
Àkókòìṣẹ́jú 111
Orílẹ̀-èdèNàìjíríà
ÈdèYorùbá

Ìsọníṣókí

àtúnṣe

Aníkúlápó pa ìtàn nípa Saró (tí Kúnlé Rẹmí ṣe) tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé Ọ̀yọ́ gẹ́gẹ́ bí àjèjì, àti ahunṣọ tó ń hun aṣọ-òfì. Saró ṣe pan̄ṣágà pẹ̀lú Ayaba Arọ́lákẹ́ (tí Bím̀bọ́ Adémóyè ṣe) tí ìgbéyàwó rẹ̀ kò dùn nítorí kò nífẹ̀ẹ́ sí ọba, ṣùgbọ́n ojúṣe òun ni kí ó bá a sùn. Ó tún jẹ́ ọ̀dọ́ àti pé fífi tí ọba arúgbó ń fiyè sí òun nígbà gbogbo kò wù ú. Ojúsàájú ọba máa ń fà kí àwọn orogún tó jù ú lọ lọ́jọ́ orí máa fìyà jẹ ẹ́. Òun àti Saró wá bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ra wọn ní bòókẹ́lẹ́. Bí wọ́n ṣe ń múra àtisálọ, àkàrà tú sépo, ọ̀rọ̀ ìfẹ́ wọn sì dé ọ̀dọ̀ Aláàfin tó dájọ́ ikú fún Saró. Bí ìtàn nínú Odù Ifá ṣe sọ, ẹyẹ àkàlà tí ó lè jí òkú dìde wà, Saró tìtorí ọgbọ́n Arọ́lákẹ́, jèrè agbára àkàlà láti jí òkú dìde tí ó sì gba orúkọ ìnagijẹ rẹ̀, Aníkúlápó, tí ó túmọ̀ sí “ẹni ti ó di ikú sínú apó rẹ̀." Bí Saró ṣe ń di olókìkí ní Ojúmọ́, abúlé tí wọ́n ṣí lọ, ó wá ń ṣe pan̄ṣágà pẹ̀lú àwọn obìnrin míì, ó sì da Arọ́lákẹ́. Ìgbéraga wá di ìgbéraṣánlẹ̀ fún Saró, ó sì kọjá ààlà bí ó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè n̄ǹkan púpọ̀ lọ́wọ́ àwọn ará abúlé kí òun tó lè jí òkú dìde. Nígbà tí Arọ́lákẹ́ gbọ́ròyìn pé Saró ti bèèrè lọ́wọ́ ọba fún ọmọ rẹ̀ láti fi ṣe ìyàwó kí ó tó jí àrẹ̀mọ dìde, ó pagi dínà agbára rẹ̀, ó sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Saró kùnà láti jí àrẹ̀mọ dìde, ó sì wá rí pé agbára àkàlà ti pòórá, òun kò sì ní agbára lórí ikú mọ́.

Àwọn Akópa

àtúnṣe

Eré yíya

àtúnṣe

Aníkúlápó, èyí tí Kúnlé Afọláyan àti Netflix jùmọ̀ ṣe, ni Jonathan Kovel gbé kalẹ̀ tó sì yà á ní ibi ìgbafẹ́ KAP tí a dá sílẹ̀ lẹ́nu àìpẹ́ yìí ní abúlé kan ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.[7] Wọ́n ya eré lórí ilẹ̀ 40 éékà (hẹ́kítà 16) wọ́n sì kọ́ gbogbo àwọn n̄ǹkan amáyédẹrùn àti àwọn ilé láti ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀ láti bá eré sinimá mu, tí wọ́n tún pinnu láti sọ ọ́ di abúlé sinimá.[8] Eré sinimá yìí tún jẹ́ àfihàn àkọ́kọ́ fún ọmọ Kúnlé Afọláyan, Èyíyẹmí Afọláyan, èyí tí BusinessDay ti júwe gẹ́gẹ́ bíi “ogún ìdílé” nítorí pé ìdílé wọn ti gbajúmọ̀ lára oníṣẹ́ sinimá fún ìgbà pípẹ́. [6]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Kunle Afolayan’s Epic ‘Anikulapo’ Premieres on His Birthdate – THISDAYLIVE". www.thisdaylive.com. Retrieved 2022-08-30. 
  2. Oyero, Ezekiel (15 August 2022). "Netflix releases Anikulapo trailer starring Kunle Remi, Sola Sobowale". Premium Times Nigeria. Retrieved 30 August 2022. 
  3. BellaNaija.com (2 August 2022). "Kunle Afolayan's Film Anikulapo is Coming to Netflix on September 30!". BellaNaija. Retrieved 30 August 2022. 
  4. Banquet, Naija (2022-09-20). "Anikulapo Movie: All You Need to Know". Naija Banquet (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2022-09-20. Retrieved 2022-09-20. 
  5. "Watch Aníkúlápó | Netflix Official Site". www.netflix.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-10-02. 
  6. 6.0 6.1 Udugba, Anthony (17 August 2022). "Afolayan cements family legacy as daughter debuts in Anikulapo movie". Businessday NG. Retrieved 30 August 2022. 
  7. Nwogu, Precious 'Mamazeus' (15 August 2022). "Netflix debuts official trailer for the Kunle Afolayan directed epic Anikulapo". Pulse Nigeria. Retrieved 30 August 2022. 
  8. Oke, Jeremiah (26 February 2022). "Anikulapo transforming Nigeria's movie industry, months before its release". Daily Trust. Retrieved 30 August 2022.