Lola Margaret tí orúkọ àbísọ rẹ̀ gan-an ń jẹ́ Lola Margaret Oladipupo jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin, olùdarí àti olóòtú sinimá àgbéléwò ọmọ Nàìjíríà. Ó di gbajúmọ̀ lẹ́yìn tí ó kópa olú-ẹ̀dá-ìtàn nínú eré tí àkọlé rẹ̀ ń jẹ́ Bísọ́lá Aláàánú.[1]

Lola Margaret
Ọjọ́ìbíLola Margaret Oladipupo
Iléṣà, Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun
Orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Iṣẹ́
  • Òṣèrébìnri
  • Olùdarí sini á àgbéléwò
  • Olóòtú
Ìgbà iṣẹ́Ọdún 2008 títí di àsìkò yìí

Ìgbà èwe àti ìkẹ́kọ̀ọ́

àtúnṣe

Wọ́n bí Lọlá ní Iléṣà, ní a city located in Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ibẹ̀ ló ti kàwé àkọ̀bẹ̀rẹ̀ àti girama. Ó kàwé gbàwé ẹ̀rí dìgírì nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ìtàn àti ìbáṣepọ̀ orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè, (History and International Relations) ní Yunifásítì Ìpínlẹ̀ Èkó, Lagos State University.[2]

Iṣẹ́ rẹ̀

àtúnṣe

Lọlá Margaret bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tíátà pẹ̀lú ìràlọ́wọ́ Bolaji Amusan, gbajúmọ̀ òṣèré aláwàdà ọmọ Nàìjíríà.[3] Ó di gbajúmọ̀ lẹ́yìn tí ó kópa olú-ẹ̀dá-ìtàn nínú eré tí àkọlé rẹ̀ ń jẹ́ Bísọ́lá Aláàánú. Lolá tí kópa nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ sinimá mìíràn bíi Ẹyin Akùkọ àti Ọmọ Ọlọ́rọ̀, èyí tí òun náà ṣe olóòtú rẹ̀ tí àwọn àgbà òṣèré bíi Faithia Balogun àti Mercy Aigbe kópa nínú rẹ̀. [4]. Lẹ́yìn èyí, ó ti kópa nínú oríṣiríṣi sinimá àgbéléwò.

Àtòjọ àṣàyàn àwọn sini á àgbéléwò rẹ̀

àtúnṣe
  • Bísọọ́lá Aláàánú
  • Ẹyin Akùkọ, 2008[5]
  • Ọmọ ọlọ́rọ̀, 2016[6]
  • Agbara Ìfẹ́ (The Power of Love), 2016[7]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe