Mercy Ima Macjoe, tí ó gbajúmọ̀ gẹ́gẹ́ bí Mercy Macjoe tí wọ́n bí lógúnjọ́ oṣù kẹfà ọdún 1993 (June 20 1993)[1] jẹ́ gbajúmọ̀ Òṣèrébìnrin, olóòtú sinimá àgbéléwò àti oníṣòwò ọmọ Nàìjíríà.[2] Ó di gbajúmọ̀ ìlúmọ̀ọ́ká fún ipa tó kó nínú sinimá Jenna' 'àti Magdalene. Lọ́dún 2018, wọ́n yàn án láti díje fún àmìn-ẹ̀yẹ fún amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ olú-ẹ̀dá-ìtàn tó dára jù lọ ti City People Awards bẹ́ẹ̀ ló gbàmìn ẹ̀yẹ tí Hollywood and African Prestigious Awardsfún Òṣèré fún lọ́dún 2019.[3]

Mercy Macjoe
Ọjọ́ìbíMercy 'Ima' Macjoe
20 Oṣù Kẹfà 1993 (1993-06-20) (ọmọ ọdún 31)[1]
Èkó, Ìpínlẹ̀ Èkó, Nigeria
Iṣẹ́Actress, producer, entrepreneur
Ìgbà iṣẹ́2011 sí àsìkò yìí
Ọmọ ìlúEket, Ìpínlẹ̀ Akwa Ibom


Iṣẹ́ rẹ̀

àtúnṣe

Gégé bí onísinimá àgbéléwò

àtúnṣe

Mercy bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ sinimá àgbéléwò lọ́dún 2011 pẹ̀lú ipa tó kó nínú sinimá Lonely Princess pẹ̀lú gbajúmọ̀ Òṣèrébìnrin Mercy Johnson.Lẹ́yìn ìgbà náà ló ti ń kópa nínú oríṣiríṣi sinimá, tí ó sìn di ìlúmọ̀ọ́ká. Lára àwọn sinimá tí ó ti kopa ni; Midnight Crew, Zenith of Love, Shame, Bread of Life, Girl Next Door àti Flaws. Ní ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ sinimá rẹ̀, ó ti báwọn kópa nínú àwọn sinimá àgbéléwò tí orílẹ̀-èdè Ghana.[4] Lọ́dún 2018, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ló wa ẹnu sí i, tí ọ̀pọ̀ sìn gbóríyìn fún un nípa ipa tó kó nínú Sinimá Jenna. Lọ́dún 2020, bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ sinimá ti New York Film Academy.[5][6]

Gẹ́gẹ́ bí olóòtú sinimá àgbéléwò

àtúnṣe

Lọ́dún 2018, ó ṣe olóòtú Sinimá àgbéléwò rẹ̀ àkọ́kọ́ tí ó pè ní Red, tí wọ́n sìn ṣe àfihàn rẹ̀ ní Ìbákà TV, pẹ̀lú àwọn gbajúmọ̀ àwọn Òṣèré bíi Nonso Diobi, Ifeanyi Kalu àti Mercy Macjoe, tí ó kópa olú-ẹ̀dá-ìtàn fún ara rẹ̀in.[7] Lọ́dún 2019, ó tún gbé àwọn sinimá gbankọgbì mẹ́ta jáde ti àkọlé wọ́n ń jẹ́, 30 and Single, ó yà èyí ní London, Love in a Puff àti Passion’s Promise.[2]

Awards and Recognition

àtúnṣe
Ọdún Ètò Àmìn-ẹ̀yẹ Olúborí Èsì
Ọdún 2016 Scream Awards Ìràwọ̀ tuntun Òṣèrébìnrin lágbo Sinimá àgbéléwò tó tayọ jù lọ Mercy Macjoe Gbàá
Ọdún 2017 City People Movie Awards[8] Òṣèrébìnrin tó dára jù lọ Mercy Macjoe Wọ́n pèé
2018 City People Movie Awards[9] Amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ olú-ẹ̀dá-ìtàn obìnrin tó dára jù lọ Best Supporting Mercy Macjoe Wọ́n pèé
CA Award, London Òṣèrébìnrin tó dára jù lọ Mercy Macjoe Gbàá
2019 Humanitarian Award Oníṣòwò gbajúmọ̀ Òṣèrébìnrin tí ọdún náà Mercy Macjoe Gbàá
GMYT African Humanitarian Award Òṣèrébìnrin tí fáàrí rẹ̀ dára jù lọ́dún náà Mercy Macjoe Gbàá
Hollywood and African Prestigious Awards, Los Angeles[3][6] Sinimá àgbéléwò tó dá dúró jùlọ ní Áfíríkà Love in a Puff Gbàá

Àtẹ àwọn sinimá àgbéléwò rẹ̀

àtúnṣe

Àtẹ àṣàyàn àwọn sinimá àgbéléwò rẹ̀

àtúnṣe
  • Jenna
  • Midnight Crew
  • Zenith of Love
  • Shame
  • Bread of Life
  • Girl Next Door
  • Flaws
  • Magdalene
  • Red
  • Obsessed alongside Daniel K Daniel
  • Wedding Eve
  • Forbidden Pleasure
  • Somewhere in Hell
  • Body of a Virgin
  • Moonwalker
  • Bonded by Fate

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named bio
  2. 2.0 2.1 "Pay from acting not enough to live comfortable life — Mercy Macjoe". Jennifer Mba. https://punchng.com/pay-from-acting-not-enough-to-live-comfortable-life-mercy-macjoe/. Retrieved 13 February 2020. 
  3. 3.0 3.1 "Mercy Macjoe nominated for Hollywood and African Prestigious Awards". Vanguard Newspaper. Cletus Egwu. Retrieved 13 February 2020. 
  4. "I once hawked oranges - Actress Mercy Macjoe". Vanguard Newspaper. Kehinde Ajose. Retrieved 19 February 2020. 
  5. "Actress Mercy Macjoe lands in New York Film Academy; shares photo". Sidomex Entertainment. Bridget Andrew. Retrieved 13 February 2020. 
  6. 6.0 6.1 "Actress Mercy Macjoe hones Film-making skill in New York". Vanguard Newspaper. Ayo Onikoyi. Retrieved 17 February 2020. 
  7. "Red – New Blockbuster Movie 2018 Starring Mercy MacJoe, Nonso Diobi, Ifeanyi Kalu.". Near Reel. Archived from the original on 13 February 2020. Retrieved 13 February 2020. 
  8. "City People Releases Nomination List For 2017 Movie Awards". City People Magazine. Chinedu Adiele. Retrieved 13 February 2020. 
  9. "Nominees For 2018 City People Movie Awards [FULL LIST]". City People Magazine. Chidera Nwachukwu. Retrieved 13 February 2020.