Mojisola Adeyeye

ọmọ ẹgbẹ́ ọ̀mọ̀wé ìmọ̀ sáyẹ́nsí ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà

Mojisola Christianah Adeyeye jẹ́ onímọ̀ nípa òògùn àti ọ̀jọ̀gbọ́n ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1][2] Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Muhammadu Buhari yàǹ ań sí ipò Olùdarí-Gbogbogbò fún ilé iṣẹ́ tí ó ń rí sí ìṣàkóso óúnjẹ àti òògùn (National Agency for Food and Drug Administration and Control) ní ọjọ́ kẹta oṣú kọkànlá ọdún 2017.[3] Kí ó tó di wípé wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bí olùdarí fún ilé iṣẹ́ yi, òun ni alága àkọ́kọ́ fún ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ lórí Biopharmaceutical àti ọ̀jọ̀gbọ́n onímọ̀ nípa òògùn, ìmọ̀ ẹ̀kọ̀ àti àyẹ̀wò ojà nípa òògùn ní ilé-ẹ̀kọ́ ti ìmọ̀ nípa òògùn tí ó wà ní Yunifásitì Roosevelt ní Schaumburg, Illinois, níbití ó ti lo ọdún méje.[4] Ó tún jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n ti Pharmaceutics and manufacturing fún ọdún mọ́kànlélógún ní Yunifásítì ìlú Duquesne tí ó wà ní Pittsburgh, Pennsylvania, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ó tún jẹ́ olùkọ́ni àgbà Fulbright, onímọ̀nràn àti 2008 American Association of Pharmaceutical Scientists Fellow (ẹlẹ́gbẹ́ obìnrin Áfíríkà àkọ́kọ́). Ó tún jẹ́ Fellow of the Naigerian Academy of Science and Nigeria Academy of Pharmacy.[5] Àwọn ìwádì í rẹ tí ó nìfé sí wà ní àwọn agbègbè ti ìṣáájú-àgbékalẹ̀, ìdàgbàsókè alákòso àkọ́kọ́ tí ó lágbára, semisolid àti àwọn ọ̀nà ìwọn lílò ǹ kan olómi, àti ìpìlẹ̀ IND àti ọgbọ́n ti ìdàgbàsókè ọjà tí ó pẹ́.[6] Oun ni oludasile ati Alakoso ti Elim Pediatric Pharmaceuticals Rolling Meadows, Illinois. Nípasẹ̀ Ilè-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì ìlú Duquesne, ó ṣe àgbéǹde òògùn kan tí wọ́n ń pè ní anti-retroviral (HIV / AIDS) pediatric fixed-dose combination and formulation ní orílẹ̀-èdè United Kingdom àti South Africa.[7]

Ọ̀jọ̀gbọ́n

Mojisola Christianah Adeyeye
Olùdarí Gbogbogbò, NAFDAC
Lọ́wọ́lọ́wọ́
Ó gun orí àga
3 November 2017
AsíwájúAdemola Andrew Magbojuri
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọmọorílẹ̀-èdèNàìjíríà
(Àwọn) olólùfẹ́Prof Olusola Adeyeye
Alma materUniversity of Nigeria, Nsukka
University of Georgia, Athens, Georgia
OccupationPharmasist

Ẹ̀kọ́ àtúnṣe

Moji Adeyeye lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì ìlú Nàìjíríà tí ó wà ní Nsuka níbití ó ti gba oyé alákọ̀ọ́kọ́ nínú ìmọ̀ nípa òògùn (Bachelor's degree in Pharmaceutics) ní ọdún 1976. Ó tẹ̀ síwájú lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásíyì ìlú Georgia níbití ó ti gba oyè ẹlẹ́ẹ̀kejì nínú ìmọ̀ òògùn (Masters degree in Pharmaceutics) ní ọdún 1985 àti oyè ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ (PhD degree) ní ọdún 1988 láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga yi kanna.[8][9]

Àwọn iṣẹ́ ẹ rẹ̀ àtúnṣe

Moji Adeyeye bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ tí ó yàn laayo gẹ́gẹ́ bí i Onímọ̀-oogun ní Ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì ìlú Ibadan, Ipinle Oyo, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ọdún 1976. Ilé ìtọ́jú aláìsàn yí ni ó wà títí di ọdún 1979. Ó tẹ̀síwájú láti lọ di olórí ní ẹ̀ẹ̀ka tí ó ń mójútó oogun ní ilé ìwòsàn ti Baptist tí ó wà ní ògbómọ̀shọ́, Ipinle Oyo, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti ọdún 1979 sí ọdún 1980. Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́-ẹ̀kọ́ rẹ ní ilé-ẹ̀kọ́ nípa oogun ẹ̀ẹ̀ka ti Yunifásítì ti Puerto Rico, San Juan gẹ́gẹ́ bí i igbákejì ọ̀jọ̀gbọ́n ní ọdún 1988, kí ó to dí wípé ó tẹ̀síwájú lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì Duquesne, tí ó wà ní Pittsburgh, Pennsylvania gẹ́gẹ́ bí i igbákejì ọ̀jọ̀gbọ́n ní ọdún 1989 kí ó tó wá gba ìgbéga sí ipò ọ̀jọ̀gbọ́n ní ọdún 1994 ni ́ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì yí kanna. Nì ọdún 2003, ó gba ìgbéga sí ipò ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ìmọ̀ oogun àti ìmọ-ìṣe oogun, ẹ̀ẹ̀ka ti ìmọ-ẹ̀rọ oogun, Ilé-ìwé ti oogun ní Ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì kanna tí ó sì wà níbẹ̀ títí di ọdún 2010. Ní ọdún 2010, wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bí i ọ̀jọ̀gbọ́n ti ìmọ̀ nípa oogun, ìmọ̀-ẹ̀rọ àti Ìgbéléwọ̀n Ọjà oogun, Kọ́lẹ́ẹ̀jì ti ìmọ̀ oogun, ti ́ó wà ní Yunifásítì ìlú Roosevelt, Schaumburg, Illinois títí di ọdún 2018. Ó jẹ́ alága, ẹ̀ẹ̀ka ti àwọn ìmọ̀-ẹ̀kọ́ Biopharmaceutical, Kọ́lẹ́ẹ̀jì ti ìmọ̀ oogun, Yunifásítì ìlú Roosevelt láti ọdún 2010 sí ọdún 2017. Láti ọdún 2004 títí di àkókò yí ni Moji Adeyeye ti jẹ́ alákòóso ti àwọn oogun fún àrùn kògbóògùn AIDS àti àwọn aláìsàn HIV (DAHP) èyí ni ìgbìmọ̀ tí ó ń pinnu láti dènà HIV/Àrùn Kògbóògùn AIDS ní àárín àwọn ọ̀dọ́ ilẹ̀ Nàìjíríà àti dídènà kí àrùn yí má ba a ràn láti ọ̀dọ ìyá sí ọmọ àti àbójútó àwọn ọmọ aláìníbaba àti àwọn ọmọdé ní Ipinle Eko, Ipinle Osun àti Ipinle Oyo ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó jẹ́ alákòóso àwọn oogun fún àrùn kògbóògùn AIDS àti àwọn aláìsàn HIV (DAHP), orí ipò yí ni ó wà láti ọdún 2004. Láti ọdún 2004 sí ọdún 2005, ó jẹ́ olùkọ́ àgbà ti Fulbright, ẹ̀ẹ̀ka ti ẹ̀kọ́ ìmọ̀ oogun, Yunifasiti ilu Eko àti National Institute for Pharmaceutical Research and Development, tí ó wà ní Abuja, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Láti ọdún 2006 títí di àkókòyí ni ó ti jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n ní ẹ̀ẹ̀ka ti ẹ̀kọ́ ìmọ̀ oogun àti ìṣe oogun, olùkọ́ ìmọ̀ oogun, Yunifásítì ìlú Èkó, ní Èkó, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Láti ọdún 2009 sí ọdún 2010, òun ni alága fún ẹgbẹ́ Amẹ́ríkà ti àwọn onímọ̀-ìṣe oogun (AAPS) ìgbìmọ̀ alábòjútó ẹgbẹ́ (MSOC). Láti ọdún 2009 títí di àkókò yí ni ó ti jẹ́ olùbẹ̀wò olùkọ́ ti Fulbright (àgbáyé/ Ìlera), ní Ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀, Ile Ife àti ọ̀jọ̀gbọ́n olùbẹ̀wò fún Yunifasiti Nnamdi Azikiwe, Awka, Ipinle Anambra, orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[10]

Lákòókò tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ ẹ rẹ̀, Adeyeye ti kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ ó gboyè ti Ph.D tí ó lé ní márùndínlógún àti àwọn akẹ́kọ̀ ọ́ gboyè MSc. Adeyeye ní àwọn ìwé-ẹ̀rí márùn ún, àwọn ìwé àfọwọ́kọ márùndínlọ́gọ́ta tí àwọn ẹlẹgbẹ́ ṣe àtúnyẹ̀wò wọn, àwọn orí ìwé àti àwọn ìwé, àti àwọn ìgbéjáde ìjìnlẹ̀ sayensi tí ó lé ní ogóje.

Ní ọjọ́ kọkànlá oṣù kọkànlá, ọdún 2017 ni wọ́n dárúkọ Adeyeye gẹ́gẹ́ bí i olùdarí gbogbogbò fún ilé iṣẹ́ tí ó ń rí sí ìṣàkóso òògùn àti oúnjẹ (National Agency for Food and Drug Administration and Control) láti rọ́pò Ademola Andrew magbojuri.

Àwọn àmì Ẹ̀yẹ àti Ọlá àtúnṣe

Mojisola adeyeye ti gba àwọn àmì ẹ̀yẹ lóríṣiríṣi. Lára àwọn àmì ẹ̀yẹ ná à ni ìwọ̀nyí: Ní ọdún 2016, Fellow of the Naijiria Academiv of Science Ní ọdún 2015, Research Fellow of the American Association of College of Pharmacy (AACP) Ní ọdún 2011, Recognition Service Award fron the AAPS Manufacturing Science Engineering section Ní ọdún 2008, Fellow of the American Association of Pharmaceutical Scientists (AAPS) Ní ọdún 2006, láti ọdún yi ni ó ti jẹ́ J.William Fulbright Senior Special Candidate. Ní ọdún 2004 sí ọdún 2005, ó gba àmì ẹ̀yẹ ti J. William Fulbright Scholar for African regional research Program lórí àrùn AIDS àti àwọn ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ tí ó farajọ àrùn AIDS. Ní ọdún 1991/1992, wọ́n kọ orúkọ rẹ̀ sínú ìwé Marquis Who's Who of American women. Ní ọdún 1983, graduate fellowship by the American Association of University Women (AAUW).

Àwọn ìwé-àṣẹ àtúnṣe

  • Christianah M Adeyeye, Vicki L Davis, Udaya Kotreka. (2011). In situ gel ophthalmic drug delivery system of estradiol or other estrogen for prevention of cataracts. United States patent US 2011 US Patent 8,679,511[11]
  • Christianah Moji Adeyeye, Anjali Joshi and Fred Esseku. Anti-retroviral Drug Formulations for Treatment of Children Exposed to HIV/AIDS. PCT/US2009/031285 [12]
  • Christianah Moji Adeyeye and Ashwin Jain, Controlled Release Pharmaceutical Preparation for Treatment of Endometriosis and Fibrocystic Breast Disease., U.S. Patent No. May 6, 2003
  • Christianah Moji Adeyeye, Hideki Ichikawa and Yoshinobu Fukumori, Method of Treating a Patient with a Prolonged Time-Release Drug and the Drug itself, U.S. Patent No. 6,156,340, December 5, 2000.[13]

Ìgbésí ayé rẹ àtúnṣe

Adeyeye ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú Senator Olusola Adeyeye ti agbègbè Ọ̀ṣun. Wọ́n bí ọmọ méjì, ọkùnrin kan àti obìnrin kan.[14]

Inúrere àti iṣẹ́ agbègbè àtúnṣe

Adeyeye ni olùdásílẹ̀ ẹgbẹ́ tí kò wà fún èrè jíjẹ tí wọ́n sì ń ṣẹ ìrànlọ́wọ́ lórí àwọn òògùn fún àrùn AIDS àti àwọn aláìsàn tí ó ní àrùn AIDS ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Òun tún ni olùdásílẹ̀ Sarah àwọn ìdílé tí ó gbòòrò sii fún àwọn ọmọdé, eyí ni ilé tí ó ńṣe ìtọ́jú àwọn ọmọ wẹẹrẹ láti ilé-ìwé jéléósimi títí dé ìpele ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì. Ilé yì í fìdíkalẹ̀ sí ìlú Òṣogbo, ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun àti Ògbómòṣọ́, ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.[15]

Awọn itọkasi àtúnṣe

  1. Ayodele (2017-11-14). "Buhari appoints Adeyeye as new NAFDAC DG". Punch Newspapers. Retrieved 2020-11-10. 
  2. "Buhari appoints Adeyeye as NAFDAC DG". Latest Nigeria News, Nigerian Newspapers, Politics (in Èdè Latini). 2017-11-14. Retrieved 2020-11-10. 
  3. Ayodele (2017-11-14). "Buhari appoints Adeyeye as new NAFDAC DG". Punch Newspapers. Retrieved 2020-11-10. 
  4. "Director General’s Page – NAFDAC". NAFDAC – National Agency for Food & Drug Administration & Control. Retrieved 2020-11-10. 
  5. "Director General’s Page – NAFDAC". NAFDAC – National Agency for Food & Drug Administration & Control. Retrieved 2020-11-10. 
  6. "Mojisola Adeyeye". Wikipedia. 2018-03-29. Retrieved 2020-11-10. 
  7. "Moji Adeyeye: Another Woman on The NAFDAC Block". Time Nigeria Magazine. 2017-11-16. Retrieved 2020-11-10. 
  8. punchng (2017-11-12). "Sen. Adeyeye’s wife to be named as NAFDAC DG". Punch Newspapers. Retrieved 2020-11-10. 
  9. Odunsi, Wale (2017-11-11). "Buhari appoints Adeyeye’s wife, Prof. Moji Christianah new NAFDAC DG". Daily Post Nigeria. Retrieved 2020-11-10. 
  10. "Search For Roosevelt University Faculty Members & Profiles". Roosevelt University. 2020-05-22. Retrieved 2020-11-10. 
  11. "US Patent for In-situ gel ophthalmic drug delivery system of estradiol or other estrogen for prevention of cataracts Patent (Patent # 8,679,511 issued March 25, 2014) - Justia Patents Search". patents.justia.com. 
  12. "Antiretroviral Drug Formulations for Treatment of Children Exposed to Hiv/Aids". 
  13. "Technologies Available for Licensing". www.duq.edu. 
  14. Bolashodun, Oluwatobi (2017-11-11). "President Buhari appoints Prof. Moji Christianah Adeyeye as new DG of NAFDAC". Legit.ng - Nigeria news. Retrieved 2020-11-10. 
  15. "Hostmonster.com". Welcome dahp.net (in Èdè Afrikani). Retrieved 2020-11-10.