Mudashiru Obasa

Olóṣèlú
(Àtúnjúwe láti Mudashiru Ọbasá)

Mudashiru Àjàyí Ọbasá jẹ́ agbẹjọ́rò, olóṣèlú ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress ilẹ̀ Nàìjíríà kan. Òun tún ni ó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé ìgbìmọ̀ Aṣòfin ìpínlẹ̀ Èkó lọ́wọ́lọ́wọ́.[1]

Right Honourable
Mudashiru Obasa
Speaker of the 8th Lagos State House of Assembly
Lọ́wọ́lọ́wọ́
Ó gun orí àga
2015
AsíwájúAdeyemi Ikuforiji
ConstituencyLagos, Agege Constituency I
Member of the Lagos State House of Assembly
In office
2011–2015
Member of the Lagos State House of Assembly
In office
2007–2011
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbíOṣù Kọkànlá 11, 1972 (1972-11-11) (ọmọ ọdún 51)
Ọmọorílẹ̀-èdèNigerian
Ẹgbẹ́ olóṣèlúAll Progressive Congress (APC)
ẸbíMarried
ResidenceLagos
Alma materLASU
OccupationLegislature
ProfessionLegal Practitioner

Ibẹ̀rẹ̀ aye rẹ̀ àtúnṣe

A bí i ní ilù Agege, ní Ìpínlẹ̀ Èkó ní apa gúsù ìwọ̀ Olorun ilẹ̀ Nàìjíríà. [2]

Ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ní Ilé-ẹ̀kọ́ St Thomas Acquinas ní Sùúrù-lérè, ṣáájú kí ó tó lọ sí Ilé-ẹ̀kọ́ girama Archbishop Aggey Memorial, ní ìlú Mushin, ní agbègbè Ìlasa-màjà, ní ìpínlẹ̀ Èkó níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ gba ìwé ẹ̀rí ìdánwò àpapọ̀ Ìwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ Adúláwọ̀ (WAEC). [3] Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ìmọ̀òfinIlé-Ẹ̀kọ́ Ìpínlẹ̀ Èkó ní ọdún 2006. [4]

Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olóṣèlú àtúnṣe

Ní ọdún 1999, Mudashiru díje dupò sí ipò àga ijọba ìbílẹ̀ Agege lábẹ́ egbẹ́ òṣèlú Alliance for Democracy bori ó sì borí, léyìí tí ó ṣiṣẹ́ nibẹ̀ láàrín ọdún 1999 sí 2002. [5]

Ẹ̀wẹ̀, ó ran díje dupò sí Ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin ìpínlẹ̀ Èkó ní ẹkùn ìjọba ìbílẹ̀ Agége ní ọdún 2019, tí ó sì tún jáwé olúborí nínú ìdìbò naa, tí ó sì sọ́ di agbẹnusọ́ fun Ilé ìgbìmọ̀ náà ní Ipinlẹ̀ Ẹ̀kó. [6]

Àwọn ìtọ́kasí àtúnṣe