Muhammad Inuwa Yahaya

Olóṣèlú

Muhammad Inuwa Yahaya (a bi ní ọjọ kẹsán, oṣù kẹwa ọdún 1961) jẹ alabojuto ati olóṣèlú Naijiria. Òún ni Gomina ti a yan ni ìpínlẹ̀ Gombe nínú idibo gómìnà ọdún 2019 lábẹ́ ẹgbẹ́ All Progressive Congress (APC).[1][2][3][4]

Muhammad Inuwa Yahaya
Governor of Gombe State
Lọ́wọ́lọ́wọ́
Ó gun orí àga
29 May 2019
DeputyManasseh Daniel Jatau
AsíwájúIbrahim Hassan Dankwambo
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí9 Oṣù Kẹ̀wá 1961 (1961-10-09) (ọmọ ọdún 63)
Jekadefari, Northern Region, Nigeria (now in Gombe State)
Ọmọorílẹ̀-èdèNigerian
Ẹgbẹ́ olóṣèlúAll Progressive Congress
(Àwọn) olólùfẹ́
  • Asma'u Inuwa Yahaya
  • Amina Inuwa Yahaya
Àwọn ọmọ7
ResidenceGombe, Nigeria
Alma materAhmadu Bello University
Occupation
  • Politician
  • businessman

Ibẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n bí Muhammad Inuwa Yahaya ní ọjọ́ kẹsànán oṣù kẹwàá ọdún 1961 ní agbègbè Jekadefari, ní ìpínlẹ̀ Gombe. Bàbá rẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Alhaji Yahaya Umaru, jẹ́ oníṣòwò.[5][6]

Etò ẹ̀kọ́ rẹ̀

àtúnṣe

Yahaya lọ sílé-ẹ̀kọ́ alákọ́bẹ̀rẹ̀ ti Central nígbà tí ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ girama ti Science Secondary School tí ó wà ní ìpínlẹ̀ Gombe.[7] Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ìkíní nínú Ìmọ̀ ìṣirò owó ní ọdún 1983 nínú ilé-ẹ̀kọ́ fáfitì ti Ahmadu Bello University, Zaria [5]

Iṣẹ́ ìṣe rẹ̀

àtúnṣe

Yahaya ti ṣiṣẹ́ ní àwọn ilé-iṣẹ́ ìjọba ati aládàáni ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ ìjọba Ìpínlẹ̀ Bauchi tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bauchi State Investment and Property Develpment Company tí ó sì jẹ́ ọ̀gá àgbà aṣèṣirò owó nílé ìṣẹ́ náà ní ọdún 1984 sí 1985. Bákan náà ni ó tún jẹ́ adarí àgbà fún ilé-iṣẹ́ A.Y.U Civil Engineering Company Ltd láàrín ọdún 1993 sí 1999. [7]

Ní ọdún 2003 ni Gómìnà Muhammed Danjuma Gòkè yàn án sípò kọmíṣánà fún ètò owó ìná àti ìdàgbà-sókè ọrọ̀-ajé .[5]

Ẹgbẹ́ akóṣẹ́mọṣẹ́ tí ó wà

àtúnṣe

Yahaya jẹ́ ìkan gbòógì nínú àwọn ẹgbẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ wọ̀nyí:[8]

Ìṣe ìṣèlú rẹ̀

àtúnṣe

Yahaya dara pọ̀ mọ́ ìṣèlú ní ọdún 2003, tí ó sì díje sí ipò Gómìnà ní abẹ́ àsí ẹgbẹ́ ìṣèlú All Progressives Congress (APC) ní ọdún 2015 ní Ìpínlẹ̀ Gombe. Nígbà tí ó di ọjọ́ kíní oṣù Kẹwàá ọdún 2018, ó jáwé olúborí nínú ìdìbò abẹ́lé inú ẹgbẹ́ rẹ̀ pẹ́lú ìbò tí ó tó mọ́kàndínláàdọ́rún tí ó fi gbẹyẹ lọ́wọ́ akẹgbẹ́ rẹ̀ tí ó ń jẹ́ Muhammed Jibrin Barde láti díje sípò Gómìnà ní ọdún 2018. [9][10]

Wọ́n kéde Yahaya gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jáwé olúborí nínú ìdìbò sípò gómìnà ìpínlẹ̀ Gombe náà ní ọjọ́ kẹsàán oṣù kẹta ọdún 2019 lẹ́ni tó mókè pẹ̀lú iye ìbò tí ó tó 364,179 láti fi fẹ̀yìn alatako rẹ̀ Sẹnetọ Usman Bayero Nafada láti inú ẹgbẹ́ Peoples Democratic Party (PDP), tí ó ní ìbò 222,868.[11]

Bákan náà ni Yahaya tún wọlé sípò gómìnà lẹ́ẹ̀kejì ní ọdún 2022 nígbà tí ó foju alátakò rẹ̀ gbolẹ̀ pẹ̀lù ìbò tí ó tó 342,821 láti inú ẹgbẹ́ ìṣèlú Peoples Democratic Party (PDP) , ìyẹn Muhammad Jibiri Barde tí ó ní iye ìbò 233,131. Ìkéde ìjáwé olúborí rẹ̀ yí ni ó wáyé láti ẹnu òṣìṣẹ́ Independent National Electoral Commission (INEC), Maimuna Waziri, tí ó sọ wípé ẹgbẹ́ APC borí pẹ̀lú ìbò tí ó tó 74,493 nínú ìdìbò náà.[12]

Ayé rẹ̀

àtúnṣe

Gómìnà Yahaya fẹ́ ìyàwó méjì, ó sì bí ọmọ méje tí gbogbo wọn ń gbé ní ìpínlẹ̀ Gombe. Àkọ́bí rẹ̀ lọ́kùnrin náà ṣègbéyàwó ní ọdún 2022. [5]

Oyè ìbílẹ̀ tí wọ́n fi jẹ

àtúnṣe

Dan Majen Gombe[13]

Matawallen Kaltungo[14]

Ẹ lè wo

àtúnṣe

Àwọn itọ́kasí

àtúnṣe
  1. "INEC declares APC’s Inuwa Yahaya Gombe Gov-elect". Punch Newspapers. Retrieved 2019-03-20. 
  2. "Governor Yahaya of Gombe signs N154.9bn 2022 budget into law". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. 2021-12-18. Archived from the original on 2022-02-22. Retrieved 2022-02-22. 
  3. "Gombe 2023: Inuwa's journey of no return - The Nation Newspaper". thenationonlineng.net. Retrieved 2022-03-01. 
  4. "INEC declares APC's Inuwa Yahaya Gombe Gov-elect". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 10 March 2019. Retrieved 2019-03-20. 
  5. 5.0 5.1 5.2 5.3 "Brief biography of Gombe State Governor-Elect". Daily Trust (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-03-19. Archived from the original on 20 March 2019. Retrieved 2019-03-20. 
  6. "Gombe State Governor". www.nggovernorsforum.org. Archived from the original on 2022-04-08. Retrieved 2022-03-26. 
  7. 7.0 7.1 "Gombe State Governor". www.nggovernorsforum.org. Archived from the original on 2022-04-08. Retrieved 2022-03-17. 
  8. "Gombe State Governor". www.nggovernorsforum.org. Retrieved 2022-03-28. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  9. "APC Votes Yahaya as Gombe Guber Candidate". THISDAYLIVE (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-10-01. Retrieved 2019-03-20. 
  10. "Gombe 2019: The game changers". Tribune Online (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-09-25. Archived from the original on 2019-06-16. Retrieved 2019-03-20. 
  11. www.premiumtimesng.com https://www.premiumtimesng.com/regional/nnorth-east/319240-its-official-apc-wins-gombe-governorship-election.html?tztc=1. Retrieved 2023-06-29.  Missing or empty |title= (help)
  12. Umar, Auwal (2023-03-19). "JUST IN: Gombe governor wins second term in office". Premium Times Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-06-29. 
  13. "Governor Yahaya bags traditional title of Dan Majen Gombe - Daily Trust". dailytrust.com. Retrieved 2023-06-03. 
  14. "Gombe Governor bags traditional title of Matawallen Kaltungo - Daily Trust". dailytrust.com. Retrieved 2023-06-03.