Olóyè Muraina Oyelami (tí a bí ní ọjọ́ kọkànlélógún, oṣù kejì, ọdún 1940) jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ó sì jẹ́ ayàwòrán àti onílù ti Ìran Yorùbá. Ó wà lára àwọn tó kọ́kọ́ gboyè ní Osogbo School of Art ní ọdún 1960. Ó wà lára àwọn onílù àti òṣèré fún ègbé tíátà ti Duro Ladipoe. Ó kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní orin àti ijó àbáláyé níObafemi Awolowo University láti ọdún 1976 sí1987. Gẹ́gẹ́ bíi olórin, ó kọ bí wọ́n ṣe ń lu Gangan àti Bàtá. Wọ́n fi joyè ní ìlú rẹ̀, ní Iragbiji.

Muraina Oyelami
Ilẹ̀abínibí Nigerian
Movement Modernism, Osogbo Art

Láti ọdún 1963 sí 1965, Oyelami ti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nínú ẹ̀kọ́ dùndún (tí ń sọ̀rọ̀ ìlù) láti ọ̀dọ̀ Ọba Laoye, tí í ṣe Timi ti ìlú Ede. Láàárín àkókò náà, ó kẹ́kọ̀ọ́ ìlù Batá pẹ̀lú Ayantunji Amoo ará Okinni àti Abeyefo ará Ìseyin.

Ó jẹ́ onílù àti òṣèré pẹ̀lú Duro Ladipo National Theatre, ilé iṣẹ́ tiata òṣèré Yorùbá Duro LadipO rin irin ajo Yuroopu gẹgẹbi ọmọ ẹgbẹ ti ẹgbẹ, akọkọ si Germany fun Festival Festival of Art ni 1964 ati lẹhinna si United Kingdom fun Festival Arts Commonwealth ni 1965.

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n bí Muraina Oyelami ní ọjọ́ kọkànlélógún, oṣù kejì, ọdún1940 ní ìlú Iragbiji, Osun State.[1]

Iṣẹ́ ìlù lílù àti òṣèré tíátà

àtúnṣe

Láti ọdún 1963 dé 1965, Oyelami kọ́ ẹ̀kọ́ ìlù lílù, láti lè mọ bí wọ́n ṣe ń lu Gangan lọ́wọ́ Oba Laoye, tí ó jẹ́ Timi ti ìlú Ede nígbà náà. Nígbà kan náà, ó ń kọ́ Ìlù bàtá lọ́wọ́ Ayantunji Amoo tí ó jé Okinni àti Abeyefo ti ìlú Iseyin. Òun ni onílù àti òṣèré fún ègbé tíátà ti Duro Ladipoe tí ó jẹ́ ẹgbẹ́ tó máa ń ṣe tíátà Yorùbá.[1] Ó lọ sí Europe, ìlú Germany fún Berlin Festival of Art ní ọdún 1964 àti United Kingdom fún Commonwealth Arts Festival ní ọdún 1965.

Ní ọdún 1964, Oyelami lọ ilé-ìwé Mbari Mbayo Artists and Writers Club ní Òṣogbo[1] níbi tó ti kọ́ ẹ̀kọ́ ìyàwòrán tí Georgina Beier gbé kalẹ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ní gba ẹ̀kọ́ ní Osogbo Art School, èyí tí Georgina and Ulli Beier gbé kalẹ̀, kò sì yọ ọwọ́ ní ìdí ìlù lílù àti iṣẹ́ tíátà rẹ̀.

Iṣẹ́ Hezbon Owiti, tó jẹ́ ayàwòrán ti orílẹ̀-èdè Kenya ló máa ń fun ní ìwúrí láti ya àwọn àwòrán tìrẹ.[1] Ní ọdún 1967, ó ṣe àfihàn àwọn iṣẹ́ rẹ̀ ní Edinburgh, wọ́n sì fi iṣẹ́ rẹ̀ wé iṣẹ́ Paul Klee àti Amedeo Modigliani, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò mọ̀ nípa àwọn àwòrán Europe.[1]Wọ́n padà fi iṣẹ́ rẹ̀ wé iṣẹ́ George's Rouault

Ó sì dara pọ̀ mọ̀ àpérò iṣẹ́ fún àwọn ayàwòrán ti Ru Van Rossem ní ọdún 1966 àti 1972.

Oyelami lọ ilé-ìwé gíga ti Obafemi Awolowo UniversityIle-Ife, ó sì gboyè nínú technical theatre, theatre design àti dramatic arts.

Oyelami jẹ́ olóyè ní ìlú rẹ̀, wọ́n fi joyè Eesa ti ìlú Ìrágbìjí [2] ní ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù kejì, ọdún 1993.

Ní ọdún 2018, Oyelami ṣe ìdásílẹ̀ Abeni Visual and Performing Art Institute ní Iragbiji. Òun ni adarí ilé-ìwé náà.[3] Ní ilé-ìwé náà, wọ́n máa ń kọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kẹ́kọ̀ọ́ lórí ìlú lílù, aró dídá, àti àwòrán yíyà.[4][5]

Iṣẹ́ àwòrán yíyà

àtúnṣe

Oyelami ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ lórí àwòrán yíyà..[6] Ní ọdún 2017,wọ́n ṣe àfihàn iṣẹ́ rẹ̀ ní Osogbo art ní United States[2] àti ní Art Dubai.[7]

Ìwé tó kọ

àtúnṣe

Oyelami ti kọ oríṣiríṣi ìwé lórí ìlú lílù àti àṣà Yorùbá. Monograph ti ọdún 1993 lórí Abefe: tí ó jẹ́ ìtàn ìgbésí ayé Muraina Oyelami dá lórí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tí wón ṣe fún Oyelami, Ulli Beier jẹ́ olóòtú ìwé náà.[8]

  • Oyelami, Muraina (1982). My Life in the Duro Lapido Theatre. [Bayreuth]: Iwalewa-Haus. OCLC 16528068. 
  • Oyelami, Muraina (1989). Yoruba Dundun Music: A New Notation with Basic Exercises & Five Yoruba Drum Repertoires. Iwalewa. OCLC 24257917. 
  • Oyelami, Muraina (1993). Ulli Beier. ed. Abefe: An Autobiography of Muraina Oyelami. Bayreuth: Iwalewa-Haus, University of Bayreuth. OCLC 5827185. 

Àwọn Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. 1.0 1.1 1.2 1.3 1.4 Campbell, Bolaji V. (21 March 2000). "Oyelami, Muraina". Oxford Art Online. doi:10.1093/gao/9781884446054.article.T096629. https://www.oxfordartonline.com/groveart/view/10.1093/gao/9781884446054.001.0001/oao-9781884446054-e-7000096629#oao-9781884446054-e-7000096629. Retrieved 11 March 2021. 
  2. 2.0 2.1 Garba, Kabir Alabi (17 April 2017). "50 years of Osogbo Art exhibition loud in America". The Guardian. Archived from the original on 12 July 2018. https://web.archive.org/web/20180712081237/https://guardian.ng/art/50-years-of-osogbo-art-exhibition-loud-in-america/. 
  3. Utor, Florence (14 November 2018). "Artists, royal fathers storm Iragbiji for AVPAI's opening". Guardian. Archived from the original on 14 November 2018. https://web.archive.org/web/20181114131344/https://guardian.ng/art/artists-royal-fathers-storm-iragbiji-for-avpais-opening/. 
  4. Sowole, Tajudeen (20 December 2015). "Half A Century Of Brushing With Osogbo Master, Oyelami". The Guardian. https://guardian.ng/art/half-a-century-of-brushing-with-osogbo-master-oyelami/. 
  5. Kolawole, Yinka (25 March 2020). "Empowering Osun Youths in Arts, Culture". This Day. https://www.thisdaylive.com/index.php/2020/03/25/empowering-osun-youths-in-arts-culture/. 
  6. Eaton, Maynard (22 February 2016). "Osogbo: Art and Heritage and Controversy". Saporta Report. https://saportareport.com/54134-2/columnists/maynard/. 
  7. Sowole, Tajudee (27 March 2017). "At Art Dubai 2017, African artists boost sales". The Guardian. Archived from the original on 9 November 2018. https://web.archive.org/web/20181109072203/https://guardian.ng/art/at-art-dubai-2017-african-artists-boost-sales/. 
  8. Oyelami, Muraina (1993). Ulli Beier. ed. Abefe: An Autobiography of Muraina Oyelami. Bayreuth: Iwalewa-Haus, University of Bayreuth. OCLC 5827185. 
  • Adenaike, A. Omotayo (1979). The Osogbo experiment sixteen years after. University of Nigeria, Nsukka. OCLC 23295996.  [unpublished; unillustrated copy available in the National Museum of African Art Library]
  • Beier, Ulli (1988). Three Yoruba artists : Twins Seven-Seven, Ademola Onibonokuta, Muraina Oyelami. Bayreuth : Bayreuth University. OCLC 1228761440. 
  • Beier, Ulli (1991). "Visual Experience". Thirty Years of Oshogbo Art. Bayreuth: Iwalewa-Haus. OCLC 24704098. 
  • Crowder, Michael (1978). "The contemporary Nigerian artist: His patrons, his audience and his critics". Présence Africaine (Paris) 105–106 (105/106): 130. doi:10.3917/presa.105.0130. 
  • Filani, Kunle (2005). Patterns of Culture in Contemporary Yoruba Art. Nigeria: Symphony Books. ISBN 9789783787759. 
  • Jegede, Dele (1984). "Patronage and change in Nigerian art". Nigeria Magazine (Lagos) (150): 29–36. 
  • Kennedy, Jean (1992). New Currents, Ancient Rivers: Contemporary African Artists in a Generation of Change. Washington DC: Smithsonian Institution Press. ISBN 978-1-56098-037-7. 
  • National Gallery of Modern Art, The Nucleus: A Catalogue of Works in the National Collection on the Inception of the National Gallery of Modern Art (Lagos), Lagos: Federal Department of Culture, 1981
  • Oguntona, Toyin (1981). The Oshogbo workshops: A case study of nonformal art education in Nigeria. Ann Arbor: University of Wisconsin. OCLC 8839582. 
  • Udechukwu, Obiora (1978). "Observations on art criticism in Nigeria". Nigeria Magazine (Lagos) (126/127).