Nancy Illoh jẹ́ akọ̀ròyìn, ọmọ orílẹ̀-èdè Naijiria. Ó jẹ́ olóòtú ètò "MoneyShow" lórí Africa Independent Television, ó sì tún jẹ́ olùdámọ̀ràn media àti alákòóso òwò ilẹ̀ Afirika ní Daarsat. Ó jẹ́ alákòóso àgbà ti African Economic Congress.

Nancy Illoh
Iléẹ̀kọ́ gígaNnamdi Azikiwe University
Iṣẹ́TV presenter
Journalist
Media Consultant
EmployerAfrica Independent Television

Ìgbésí ayé àti ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀

àtúnṣe

Ọmọ bíbí ipinle Delta ní Illoh, ó sì jẹ́ àkọ́bí nínú ọmọ mẹ́fà. Wọ́n bí i ní Ìpínlẹ̀ Èkó, lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ kí ó tó wá lọ Yunifásítì Nnamdi Azikiwe, Awka níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè BSc. nínú ìmọ̀ Parasitology àti Entomology.

Iṣẹ́ rẹ̀

àtúnṣe

Nancy Illoh jẹ́ agbéròyìn sáfẹ́fẹ́, àti olóòtú ètò nípa ọ̀rọ̀ owó-ìṣúná àti ètò ọrọ̀-ajé tí wọ́n máa ń fi hàn ní Naijiria àti ilẹ̀ Adúláwọ̀.

Ní ọdún 2007, ó dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ tó ń gbé ètò "MoneyShow" kalẹ̀, tí wọ́n máa ń fi hàn lórí AIT, tí wọ́n sì máa ń ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú àwọn ọmọ Africa lórí ètò ọrọ̀-ajé àti owó-ìṣụ́ná. Òun àti ẹgbẹ́ rè ti ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò fún Ààrẹ àná ti African Development Bank, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Donald Kaberuka, ọ̀jọ̀gbọ́n John Kuffor, tó jẹ́ Ààrẹ ìlú Ghana tẹ́lẹ̀, Adams Oshiomhole àti Sanusi Lamido Sanusi, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. [1]

Obi Jideuwa, tí ó jẹ́ Ọba ìlú Issele Azagba, ní apá Àríwá Aniocha ní ipinle Delta fi joyè Adã Né kwùlí Ọwáa.

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Empty citation (help)