National Arts Theatre
National Arts Theatre je ogan gan ibi ipate isere ori-itage ile Naijiria. Ile igbafe naa ni o kale si agbe gbe Iganmu, ni ijoba ibile Surulere, ni ipinle Eko. Won ko gbongan isere yii pari ni odun 1976 fun ipalemo ayeye akojopo ile Adulawo Meri ti (FESTAC) Festival of Arts and Culture ni odun 1977. Awon akojopo ohun oso abalaye ati ti igba-lode ti ile Naijiria ni won ko sinu gbangan naa.
Sise oso re
àtúnṣeKiko gbangan National Arts Theatre ni won bere nigba aye ologun ti olori ogagun Yakubu Gowon ti won si pari re ni igba aye ogaun Olusegun Obasanjo. Aworan ita gbangan naa ni won ko bi fila ologun. O ni aye ijoko ti o le gba egberun marun eniyan leekan soso pelu pepe itage, ti o si tun aye nla meji otooto fun ere itage meji lai dira won lowo bi ere ba n lo, ti won si fi ohun elo igba-lode ti o le se ogbufo ede mejo papo leekan naa fun awon ti won ba gbo ede naa. Okan ni eyi je ninu awon ohun miiran ti o wa ni gbangan naa.
Awon Kongila ara ile Bulgaria ni won ba orile ede Naijiria ko gbangan naa ti won si dara si ti o fi fe jo Palace of Culture and Sports ti ile Varna, ni ilu Bulgaria ( 1968), Amo gbogan National Arts Theatre ti ilu Eko tobi ju afara pe yi lo.
Yanpon-yanrin lori gbangan naa
àtúnṣeNi odun 2010, Aare igba naa, ogbeni Olusegun Obasanjo kede re lati so gbangan nla naa di ti aladani. Eleyi ni o da idaru-dapo sile laarin awon osere amuluudun omo ile Naijiria ati awon akoni onkowo bii Wole Soyinka ko jale lati je ki Aare naa se bee. Ni ogbonjo 30 osu December 2014, won fi lede wipe won ti ta gbangan naa fun awon ajo ti won wa ni ile Dubai ni ogoji Milionu Dollar ($40million), ti won si so wipe won yoo so gbangan naa di ile itaja fun awon arinrin ajo, paa paa julo awon arinrin ajo lo soke.