Ngozi Nwosu
Wọ́n bí Ngozi Nwosu ní Ọjọ́ Kínní, Oṣù Kẹẹ̀jọ Ọdún 1963. Ó jẹ́ gbajúgbajà òṣèrébìnrin àti olùgbéréjáde ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1][2] Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ eré ṣíṣe rẹ̀ pẹ̀lú ṣíṣe eré èdè Yorùbá ṣááju kí ó tó wá kópa nínu eré èdè ígbò kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Living in Bondage.[3][4][5]
Ngozi Nwosu | |
---|---|
Nwosu in Skinny Girl in Transit | |
Ọjọ́ìbí | 1 Oṣù Kẹjọ 1963 ìlú Èkó |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Iṣẹ́ | Actress |
Gbajúmọ̀ fún | Ripples Living in Bondage Fuji House of Commotion |
Ọ̀rọ̀ ayé rẹ̀
àtúnṣeNwosu jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Arochukwu ní Ìpínlẹ̀ Abíá.[6][7] ó dàgbà ní ìlú Èkó níbi tí wọ́n bi sí. Ó pàdánù bàbá rẹ̀ ní àkókò Ogun Abẹ́lé Nàìjíríà. Ó gbọ́ èdè Gẹ̀ésì, Yorùbá, àti Ígbò dáada.[8] Ó ní ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ní St Paul Anglican School, Idi Oro. Lẹ́hìn náà, ó lọ sí Maryland Comprehensive High School ní ìlú Ìkẹjà, Ìpínlẹ̀ Èkó. Ó gba àwọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún iṣẹ́ òṣèré rẹ̀ lábẹ Reverend Fabian Oko ní ilé-ìṣeré Royal Theatre Art Club School.[9]
Ó ṣàìsàn ní ọdún 2012, ṣùgbọ́n ó gba ìtọ́jú ní ilẹ̀ òkèrè nípasẹ̀ ìrànlọ́wọ́ ìjọba àti àwọn ilé-iṣẹ́ míràn.[10]
Iṣẹ́ ìṣe rẹ̀
àtúnṣeÓ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òṣèré rẹ̀ ní àkókò ìgbà tí ó wà ní ilé-ìwé. Ó ti kópa gẹ̀gẹ̀ bi “Madam V boot” nínu eré tẹlifíṣọ̀nù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Ripples. Ó tún ti kópa gẹ́gẹ́ bi "Peace" nínu eré tẹlifíṣọ̀nù aláwàdà kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Fuji House of Commotion (èyí tíAmaka Igwe gbé kalẹ̀). Òun ni ìyàwó kẹẹ̀ta ti Olóyè Fújì nínu eré náà.[11] Ní ọdún 2018, ó kópa gẹ́gẹ́ bi "Ene" nínu fíìmù "Sade". Ó tún ti ṣe olóòtú àwọn eré bíi Evil Passion, Stainless àti ètò rédíò kan tí n ṣe Onga.[12]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Adebayo, Tireni (March 11, 2022). ""God healed me when they thought it was over" Ngozi Nwosu comforts Kemi Afolabi - Kemi Filani News". Kemi Filani News. Retrieved May 24, 2022.
- ↑ Kenechi, Stephen (January 23, 2022). "'It felt like being buried alive' - Ngozi Nwosu recalls rumours on health struggle". TheCable Lifestyle. Retrieved May 24, 2022.
- ↑ "My regrets about my marriage, Ngozi Nwosu speaks".
- ↑ "I’ll get married at the right time – 53-year-old actress, Ngozi Nwosu".
- ↑ Ogala, George (June 6, 2020). "INTERVIEW: Why I don't believe in prophets - Ngozi Nwosu". Premium Times Nigeria. Retrieved May 24, 2022.
- ↑ "Hurray! Ngozi Nwosu celebrates 54th birthday".
- ↑ "Van Vicker, Ngozi Nwosu are a year older today". Archived from the original on 2018-07-12. Retrieved 2018-07-11.
- ↑ "My regrets about my marriage, Ngozi Nwosu speaks".
- ↑ "Veteran actress speaks up on sex-for-roles trend". Pulse. Archived from the original on 2018-07-14. Retrieved 2018-07-14.
- ↑ "NGOZI Nwosu still active and agile". The Nation. Retrieved 2018-07-14.
- ↑ "My regrets about my marriage, Ngozi Nwosu speaks".
- ↑ "Ngozi Nwosu: How I Feel About Young Nollywood Stars Getting Endorsement Deals". Information Nigeria. Retrieved 2018-07-14.