Nigerian Police


Nigeria Police jẹ́ ẹ̀ka pàtàkì nínú ilé-iṣẹ́ agbófinró ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Gẹ́gẹ́ bí òfin àgbà orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ṣe fi lélẹ̀ ní ọdún 1999, ilé-iṣẹ́ ọlọ́pá ní àṣẹ láti ní ẹ̀ka jákè-jádò orígun orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Nígbà tí yóò fi di ọdún 2016, àwọn tí wọ́n jẹ́ òṣìṣẹ́ ilé-iṣẹ́ yí ti tó 371,800.[2], ìjọba àpapọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ń gbèrò láti mú àlékún bá àwọn òṣìṣẹ́ ibẹ̀ sí 650,000 nígbà tí wọ́n bá fi 280,000 kún 370,000. Ilé-iṣẹ́ ọlọ́pá ni ó jẹ́ àjọ ìjọba àpapọ̀ kan tí ó tóbí jùlọ pẹ̀lú bí wọ́n ṣe ní ẹ̀ka káàkiri Ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì tí ó wà ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà , tí wọ́n pín sí ẹkùn mètàdínlógún àti ẹ̀ka àṣẹ mẹ́jọ. [3] Ní àsìkò tí a ń kọ àyọkà yí, ẹni tí ó jẹ́ IGP (Inspector General) ni Usman Alkali Baba. Oríṣiríṣi àtúntò ni ó dé bá ilé-iṣẹ́ náà ní ọdún 2020 látàrí rógan ti END SARS tí ó wáyébláàrín àwọn ọ̀dọ́ àti àwọn ọlọ́pá jákè-jádò Nàìjíríà In 2020, it underwent major overhauls.

The Nigeria Police
Abbreviation NPF
Logo of the The Nigeria Police.
Badge of the Nigeria Police officers
Motto Police is your friend
Agency overview
Formed 1930
Preceding agencies
  • Northern Nigeria Police (NNP)
  • Southern Nigeria Police (SNP)
Legal personality Governmental: Government agency
Jurisdictional structure
Nigeria sm02.gif
Nigeria
Size 923,768 km2
Population 206 million
Governing body Ministry of Police Affairs
Constituting instruments
  • Section 214 of the 1999 Constitution of the Federal Republic of Nigeria (as amended)
  • Nigeria Police Act 2020
General nature
Operational structure
Headquarters Louis Edet House, Abuja
Sworn members 371,800 officers [1]
Agency executive IGP Usman Alkali Baba, Inspector-General of Police
Website
npf.gov.ng

ÌtànÀtúnṣe

Wọ́n ilé-iṣẹ́ àjọ ọlọ́pá sílẹ̀ ní ọdún 1820 ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà .[4]

Ní ọdún 1879, àwọn ẹ̀yà Hausa tí wọ́n jẹ́ 1,200 níye tí wón jẹ́ kọ́nstebu ni wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ ẹ̀ka àjọ yí. [5] Nígbà tí ó fi ma di ọdún 1896, wọ́n ṣe ìfilọ́lẹ̀ ilé-iṣẹ́ ọlọ́pá ní ní Èkó tí ó jẹ́ olú ìlú fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nígbà náà. Bákan náà ni wọ́n ṣ’ẹ̀dá irú rẹ̀náà ní ẹkùn Niger Coast, ní ìlú Calabar ní ọdún 1894 l'ábẹ́ ilẹ̀ tuntun tí wọ́n dá sílẹ̀ tí wọ́n pè ní: (Niger Coast Protectorate). Ní apá òkè ọya lọ́hùn ún, ilé-iṣẹ́ Royal Niger Company ṣe agbékalẹ̀ ọlọ́pá tiwọn náà tí wọ́n pè ní : ‘’Royal Niger Company Constabulary ní ọdún 1888 tí wọ́n sì fi ìlú Lokoja ṣe olú Ilé-iṣẹ́ náà.[6]

Àwọn ìtọ́ka síÀtúnṣe

  1. "About this Collection – Country Studies | Digital Collections | Library of Congress" (PDF). Lcweb2.loc.gov. Archived from the original (PDF) on 27 May 2008. Retrieved 8 August 2016. 
  2. "Nigeria / Africa / Member countries / Internet / Home – INTERPOL". Interpol.int. Archived from the original on 29 November 2018. Retrieved 8 August 2016. 
  3. "Home Page – Nigeria Police Force". Npf.gov.ng. 29 July 2016. Archived from the original on 12 August 2016. Retrieved 8 August 2016. 
  4. "History of Nigeria Police: Facts You Need to Know" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 4 August 2020. Retrieved 2020-05-23.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  5. Micah, John (June 2017). "Public Perception of Police Activities in Okada, Edo State Nigeria". Covenant Journal of Business & Social Sciences 8. 
  6. AKINOLA, BOLAJI (2012-07-25) (in en). Authority Stealing: How Greedy Politicians and Corporate Executives Loot the World'S Most Populous Black Nation. AuthorHouse. ISBN 978-1-4772-1891-4. https://books.google.com/books?id=i8LQKx0qmCkC&pg=PA26. Retrieved 21 July 2020.