Nizamuddin Azami

Ọ̀jọ̀gbọ́n Islam ti orílẹ̀-èdè India

Nizamuddin Azami ( (Urdu: نظام الدین اعظمی; Oṣu kọkanla 1910 – 26 oṣù kejì, 2000) jẹ́ ọnímímọ̀ ẹ̀sìn Ìsìláámù kan tí ó jẹ́ ati Grand Mufti ẹlẹ́kejìlá tí ó sì kẹ́hìn ti Darul Uloom Deoband ní. Ó ṣe akitiyan nínú ẹ̀kọ́ òfin ẹ̀sìn Islam, nínú àwọn iṣẹ́ rẹ̀ sì ní Muntakhabat-e-Nizām al-Fatāwa, àkójọpọ̀ àwọn àṣàyàn fatawa tí ó kọ  lákòókò tí ó wà ní Deoband..


Nizamuddin Azami
نظام الدین اعظمی
Grand Mufti, Darul Uloom Deoband
In office
1996–2000
AsíwájúMahmood Hasan Gangohi
Arọ́pòoffice ended
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbíNovember 1910
Azamgarh, Uttar Pradesh, India
AláìsíFebruary 26, 2000(2000-02-26) (ọmọ ọdún 89)
Ọmọorílẹ̀-èdèIndian
Alma materDarul Uloom Deoband
Àdàkọ:Infobox religious biography

Ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n bí Nizamuddin Azami ní ọdún 1910 ni Undra, agbègbè Azamgarh (Azamgarh district).[1] Ó wá láti ìdílé àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n àti pé ó ní  ìfẹ́ tí ó lágbára sí ẹ̀kọ́ ẹsin Ìsìláámù lati ìgbà èwe rẹ̀.[2] Bàbá rẹ̀, Muhammad Rafi jẹ́ Zamindar.[3] Pẹ̀lú akitiyan pe kí ó kàwé, ó fẹ́ràn ìmọ̀ ẹ̀sìn.[4] Ó bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Madrasa Ihyaul Uloom ní Mubarakpur, Azamgarh, níbití ó tí ní ànfàní láti kọ́ ẹ̀kọ́ ní ọ̀dọ̀ àwọn olùkọ olókìkí, nínú wọn ni Shah Wasiullah. Lẹ́yìn ìparí ẹ̀kọ́ alákọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀, Nizamuddin Azami tẹ̀síwájú àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Madrasa Aziziya ní Bihar Sharif àti ní Madrasa Aliya Fatehpuri ní Delhi lẹ́yìn náà. Níkẹyìn, ó darapọ̀ mọ́ Darul Uloom Deoband, níbití ó ti parí Dawra-e Hadith ní ọdún 1933.[5] Nínú àwọn olùkọ́ rẹ̀ ní Shukrullah Mubarakpuri, Hussain Ahmed Madani, Asghar Hussain Deobandi, Izaz Ali Amrohi, Muhammad Ibrahim Balyawi, àti Muhammad Shafi Deobandi.[6]

Iṣẹ́

àtúnṣe

Lẹ́yìn ìparí ẹ̀kọ́ rẹ̀, Nizamuddin Azami kọ́ ọmọ l'ẹ̀kọ́ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ilé kéhú. Ó tún ṣiṣẹ́ olùkọ́ ní Madrasa Jami'ul Uloom ní Jatinpur,[7] Azamgarh fún ọdún márùn-ún, lẹ́yìn náà, Madrasa Jami'ul Uloom Dhamal ni Gorakhpur fún ọdún mẹ́ta.[4] Ó tún lọ sí Darul Uloom Mau nítorí ìtọ́sọ́nà látí olùtọ́sọ́na rẹ̀, Shah Wasiullah, ó sì lo ọdún mẹ́ẹdọ́gbọ̀n tí ó n kọ́ àti fífún àwọn ènìyàn ní fatwa (àwọn ìmọràn òfin) níbẹ̀.

Ni ọdún 1965, Nizamuddin Azami darapọ̀ mọ́ Darul Uloom Deoband gẹ́gẹ bí Mufti ( ọ̀mọ̀wé ti o péye láti fúnni ní àwọn fatwa) orí ipò náà ní ó kú sí ní Oṣù Kejì ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n, ọdun 2000. O jẹ́ olókìkí fún ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ rẹ̀ níbi yíyànjú àwọn ọ̀rọ̀ ìgbàlódé àti lílo àwọn ìlànà Ìsìláámù nípasẹ̀ Qiyas (ìròrí) àti Ijtihadi (ìpinnu ofin àdáṣe).[8] Nínú àwọn akẹ́ẹ̀kọ́ ni Abdul Haq Azmi, Mujahidul Islam Qasmi, Nizamuddin Asir Adrawi and Khalid Saifullah Rahmani.[9]

Ipa tí ó kó

àtúnṣe

Ó kọ àwọn ìdáhùn ọ̀kẹ́ mẹ́ta dín ẹgbẹ̀rún máàrún (75,000) sí àwọn ìbéèrè, tí ó fi pamọ́ sínú àwọn ìforúkọsílẹ ọgọ́fà lé márùn (125), pẹlú ìforúkọsílẹ ti a yà s'ọ́tọ̀ fún akojọpọ àwọn fatwa tí ó pàtàkì julọ sí ọ́tọ̀.[10] Iṣẹ́ rẹ̀ tí ó gbajúmọ̀ jùlọ ni àkójọpọ̀ Muntakhabat-e-Nizām al-Fatāwa, èyí tí ó ní àwọn àṣàyàn fatwa tí ó kọ ní àkókò rẹ̀ ní Darul Uloom Deoband. Mujahidul Islam Qasmi ni ó ṣe alábojútó àtẹ̀jáde náà. Àwọn ìpín meji fatwa rẹ̀ ni àwọn Ilé-ẹ̀kọ́ gíga Islam Fiqh ni New Delhi tẹ̀ jáde. Islamic Fiqh Academy (Ilé-ẹ̀kọ́ gíga Islam Fiqh) Ó tún ṣe àtẹ̀jáde ẹ̀yà iṣẹ́ náà tí ó gbòòrò ni awọn ìpín mẹ́ta[8] ṣe àtúnṣe, ó sì tẹ ìwé Fath al-Rahman fi Ithbāt Madhab al-Nu’man láti ọwọ́ 'Abd al-Haqq al-Dehlawi jáde.[8] tún kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn iṣẹ́ lórí Hadith, Fiqh, àti àwọn àkọlé mìíràn, nínú wọn ni Aqsaamul Ahaadith, Osulul Hadith, Assan Ilmus-sarf, Assan Ilmun-Nahu, Sirajul Waritheen Sharhu Siraji, Mazaya Imam Azam, àti àwọn tókù.[2]

Tún ṣe àyẹ̀wò

àtúnṣe

Àwọn atọ́ka

àtúnṣe
  1. (in Urdu) Fuzala-e-Deoband Ki Fiqhi Khidmat. Deoband: Kutub Khana Naimia. February 2011. pp. 305. https://besturdubooks.net/tag/fuzala-e-deoband-ki-fiqhi-khidmat-pdf-book/. Retrieved 22 February 2023. 
  2. 2.0 2.1 "Mufti Nizamuddin Azami (Rh)" (PDF). Islamic Fiqh Academy (India). Retrieved 31 May 2023. 
  3. Qasmi, Khursheed Hasan (2003) (in ur). Darul Uloom aur Deoband ki Tareekhi Shakhsiyaat. India: Maqtaba Tafsirul Quran. pp. 46. https://besturdubooks.net/darul-uloom-aur-deoband-ki-tareekhi-shakhsiyaat/. Retrieved 31 May 2023. 
  4. 4.0 4.1 Ullah 2018, p. 127.
  5. Àdàkọ:Cite thesis
  6. Barni, Khalilur Rahman Qasmi (2016) (in ur). The caravan of knowledge and excellence. Bangalore: Idara-e Ilmi Markaj. pp. 115. 
  7. Rizwi, Syed Mehboob (1981). "Maulana Mufti Nizam al-Din". Tarikh Darul Uloom Deoband. 2. Deoband: Darul Uloom Deoband. p. 195. 
  8. 8.0 8.1 8.2 Ullah 2018, p. 128.
  9. Qasmi, Mohammad Islam (2019) (in ur). Darakhshan Sitaren. India: Maqtaba Al-Noor. pp. 150. https://www.islamicbuk.com/product/darakhshan-sitaren/. 
  10. Qasmi, Muhammadullah (2020) (in ur). Darululoom Deoband ki Jame o Mukhtasar Tareekh. India: Sheikh Ul Hind Academy. pp. 655. https://besturdubooks.net/darululoom-deoband-ki-jame-o-mukhtasar-tareekh/. Retrieved 31 May 2023. 
Àdàkọ:S-relÀdàkọ:S-endÀdàkọ:Authority control
Preceded by
Mahmood Hasan Gangohi
Grand Mufti of Darul Uloom Deoband Succeeded by
office ended