Nuella Njubigbo jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèrébìnrin, oǹkọ̀tàn sinimá àgbéléwò, arẹwà àti olóòtú tẹlifíṣàn ọmọ Nàìjíríà.[1] Ó dara pọ̀ mọ́ iṣẹ́ eré tíátà lọ́dún 1999.[2] wọ́n sìn yàn án fún ìdíje àmìn ẹ̀yẹ 2012 Nollywood Movies Awardsfún oṣèré tó ń dàgbà jù lọ lọ́dún 2012 .[3][4][5][6][7]

Nuella Njubigbo
Ọjọ́ìbíÌpínlẹ̀ Anambra
Orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Ẹ̀kọ́Government and Public Administration, Imo State University
Iléẹ̀kọ́ gígaImo State University
Iṣẹ́Òṣèrébìnrin Screen writer

Ìgbà èwe àti ẹ̀kọ́ rẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n bí Nuella Njubigbo lọ́jọ́ kejìdínlógún oṣù kẹta ọdún 1984 ní Ìpínlẹ̀ Anambra lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ìpínlẹ̀ yìí ló ti kàwé àkọ́bẹ̀rẹ̀ àti gírámà.[8]. Ó kàwé gbàwé ẹ̀rí nínú ìmọ̀ ètò ìṣèjọba àti àkóso àwùjọ, (Government and Public Administration) ní Imo State University. Ó sìn orílẹ̀ èdè bàbá rẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Delta fún àkànṣe ìsìnlú, National Youth Service Corps.[9]

Ìgbésí ayé rẹ

àtúnṣe

Lọ́jọ́ kokàndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹta ọdún 2014, òun àti gbajúmọ̀ olùdarí sinimá àgbéléwò, Tchidi Chikere fẹ́ ara wọn. Awuyewuye pọ̀ lórí ìgbéyàwó wọn nítorí pé ọkọ rẹ̀ ti kọ́kọ́ fẹ́ ìyàwó kan tẹ́lẹ̀ kí wọ́n tó fẹ́ ara wọn. Sophia Chikere, tí òun náà jẹ́ òṣèrébìnrin ni ọkọ rẹ̀ kọ́kọ́ fẹ́, tí wọ́n sìn ti bímọ fún ara wọn. .[10][11] Tchidi, ọkọ rẹ̀ kò ṣàìṣàlàyé ìdí tí ìgbéyàwó àkọ́kọ́ fi forí ṣánpán lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ awuyewuye wọ̀nyí.[12][13] Wọ́n bímọ kan fún ara wọn lẹ́yìn ìgbéyàwó náà. Ó dara pọ̀ mọ́ iṣẹ́ tíátà lọ́dún 1999, eré àkọ́kọ́ tó ṣe ni “Royal Destiny”. Lẹ́yìn náà, ó ti kópa nínú sinimá tí ó ti ju àádọ́rùnún lọ. Ó ti bá àwọn gbajúmọ̀ oṣèré bí i Ini Edo, Mercy Johnson, Desmond Elliot, Uche Jombo, Genevieve Nnaji, John Okafor, Pete Edochie ati Ken Eric's ṣeré pọ̀. [14][15].

Àtòjọ àwọn àṣàyàn sinimá rẹ̀

àtúnṣe
  • Life's incidence
  • Lord of marriage
  • Evil project
  • Heart of a slave
  • Royal Grandmother
  • Open & Close (2011)
  • Apparition
  • Royal Touch
  • Place war

Àmìn ẹ̀yẹ

àtúnṣe
  • Africa Magic Viewers Choice Awards
  • City People Entertainment Awards
  • Rising Star Award 2012.[16]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "Ẹda pamosi". Archived from the original on 29 November 2020. Retrieved 3 November 2020. 
  2. "Ẹda pamosi". Archived from the original on 29 November 2020. Retrieved 3 November 2020. 
  3. "Nuella Njubigbo Biography on AfricanSeer". africanseer.com. Archived from the original on 7 July 2014. Retrieved 18 April 2014. 
  4. "Nuella Njubigbo". Archived from the original on 20 April 2014. Retrieved 19 April 2014.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  5. "Hot Pants actress acquires new SUV". modernghana.com. Retrieved 18 April 2014. 
  6. "Nuella on iMDb". imdb.com. Retrieved 19 April 2014. 
  7. "Nella releases hot new photos". informationng.com. Retrieved 19 April 2014. 
  8. "Ẹda pamosi". Archived from the original on 29 November 2020. Retrieved 3 November 2020. 
  9. "Nollywood Actress completes NYSC Program". bellanaija.com. Retrieved 19 April 2014. 
  10. "Tchidi Chikere blasted for abandoning wife". informationng.com. Retrieved 19 April 2014. 
  11. "Nuella weds Tchidi amidst several controversy". dailypost.ng. Retrieved 19 April 2014. 
  12. "Actress finally weds Tchidi". africanspotlight.com. Archived from the original on 20 April 2014. Retrieved 19 April 2014. 
  13. "Nuella speaks on marriage to Tchidi". vanguardngr.com. Retrieved 19 April 2014. 
  14. https://austinemedia.com/nuella-njubigbo-biography-net-worth/
  15. "Ẹda pamosi". Archived from the original on 29 November 2020. Retrieved 3 November 2020. 
  16. "Ẹda pamosi". Archived from the original on 29 November 2020. Retrieved 3 November 2020.