Oúnjẹ Kitfo

Oúnjẹ Ethiopia

Kitfo jẹ́ oúnjẹ ìbílẹ̀ àwọn ará ilẹ̀ Ethiopia èyí tí a le tọ ipasẹ̀ rẹ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn Gurage. Ó kún fún àwọn ẹran màálù ṣiṣè èyí tí a yí mọ́ mitmita (irúfẹ́ ata gúngún kan) àti niter kibbeh (bútà kan tí a ṣe láti ara egbògi). Orúkọ yìí wá láti ara èdè ilẹ̀ Ethiopia kan (Ethio-Semitic) root k-t-f, tí ó túmọ̀ sí "kí ènìyàn jẹ́ nǹkan dáadáa; rún un."

Kitfo tí a bá rọra sè fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ ni a máa ń pè ní kitfo leb leb.[1] A máa ń jẹ́ Kitfo pẹ̀lú àwọn oúnjẹ kan bíi ayibe tàbí ẹ̀fọ́ tí a sè èyí tí a mọ̀ sí gomen. Ní àwọn apá ibìkan ní orílẹ̀-èdè Ethiopia, kitfo jẹ́ oúnjẹ tí a máa ń jẹ pẹ̀lú injera, búrẹ́dì kan tí a ṣe láti ara ìyẹ̀fun teff, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nínú àwọn oúnjẹ ìbílẹ̀ àwọn Gurage , ènìyàn yóò lo kocho, búrẹ́dì kan tí ó pẹlẹbẹ tí a ṣe láti ara ewé ensete.

A máa ń jẹ Kitfo ní àwọn ibi ayẹyẹ pàtàkì. Wọ́n sáábà máa ń lò ó ní "Meskel" ìsinmi tí wọ́n máa ń ṣe lọ́dọọdún ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹsàn-án ní orílẹ̀-èdè Ethiopia

Wò pẹ̀lú

àtúnṣe

Ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. Mesfin, D.J. Exotic Ethiopian Cooking, Falls Church, Virginia: Ethiopian Cookbooks Enterprises, 2006, pp.124, 129.
àtúnṣe