Ogun Àgbáyé Ẹlẹ́ẹ̀kejì

ogun tó ṣẹlẹ̀ láàrin ọdún 1939 àti 1945 láàgbáyé
(Àtúnjúwe láti Ogun Agbaye Elekeji)

Ogun Àgbáyé Ẹlẹ́ẹ̀kejì tàbí Ogun Agbáyé Kejì jẹ́ ogun tí ó pa gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè agbáyé pọ̀ lẹ́ẹ̀kan-ṣoṣo tí ó bẹ̀ ní àárín ọdún 1939 sí ọdún 1945. Ogun yí jẹ́ èyí tí ó kan gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè agbáyé tí wọ́n jẹ́ alágbára tí wọ́n sì lààmì-laaka. Ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n jagun náà ni a lè pin sí méjì. Àwọn apá kíní ni Òngbèjà nígbà tí àwọn apá kejì jẹ́ Atọ́jà. Iye àwọn tí wọ́n jẹ́ jagun-jagun tí wọ́n kópa nínú ogun yí jẹ́ ọgbàọ́rùn un mílíọ́nù láti àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n jẹ́ ọgbọ̀n lápapọ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n jẹ́ oníjà gan an sa ipá wọn nípa lílo gbogbo ọrọ̀-ajé, ìṣúná, ilé-iṣẹ́ jànkàn-jànkàn, ìwádí ìmọ̀ sáyéẹ́nsì tí wọ́n ní láti fi jagun náà, èyí kò jẹ́ kí á mọ̀ nkan ogun àwoọ́n ọmọ ogun nikan ni àwọn orílẹ̀-èdè yí ló láti fi jagun ni tàbí wọ́n lo àwọn nkan mìíràn tí kìí ṣe ti Olohun tí ó jẹ́ ti àwọn ará ìlú lásán. Ogun agbáyé ẹlẹ́kejì yí jẹ́ ọ̀kan gbòógì nínú àwọn ogun tí èmi ati dúkìá ti ṣòfò jùlo lágbàáyé nínú ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ ọmọ adáríhurun. Àwọn ológun tí wọ́n sọ ẹ̀mí wọn nu níbi ìjà-àgbà yí jẹ́ mílíọ́nù ọ́nà àádọ́rin àti mílíọ́nù lọ́nà márùndínláàdọ́taọ́sàn án ènìyàn, nígbà tí àwọn tí wọ́n kú jùlọ jẹ́ ará ìlú lásán tí wọn kìí ṣe jagun-jagun. Ohun tí ó fàá tí òkú yí fi pọ̀ tó bẹ̀ẹ́ ni ìwà ìmọ̀ọ́mọ̀-ṣekú pa ọ̀pọ̀ ènìyàn tí àwọn Gẹ̀ẹ́sì ń pe ní jẹ́nósáìtì, nípa ìlànà ìfebipani , pípa àwọn aláìṣẹ̀ àti fífi ajàkálẹ̀ àrùn pani. Wọ́n ṣamúlò àwọn bàlúù dìgbòlùjà nínú ogun àgbáyé yí, ba kan náà ni wọ́n tún lo àwọn àdó olóró tí ó le pa ìlú run, bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n tun lo nuclear weaponsláti jagun lásìkò náà., lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ iwe àdéhùn ati òfin oríṣiríṣi

Ogun Àgbáyé Ẹlẹ́ẹ̀kejì

Clockwise from top left: Chinese forces in the Battle of Wanjialing, Australian 25-pounder guns during the First Battle of El Alamein, German Stuka dive bombers on the Eastern Front winter 1943–1944, US naval force in the Lingayen Gulf, Wilhelm Keitel signing the German Surrender, Soviet troops in the Battle of Stalingrad
Ìgbà 1 September 1939 – 2 September 1945
Ibùdó Europe, Pacific, Atlantic, South-East Asia, China, Middle East, Mediterranean and Africa, briefly North America
Àbọ̀ Ìborí àwọn Alájọṣepọ̀
Àwọn agbógun tira wọn
Àwọn Alájọṣepọ̀

 Ìsọ̀kan Sófìẹ̀tì (1941–45)[nb 1]
 Àwọn Ìpínlẹ̀ Aṣọ̀kan (1941–45)
 Ilẹ̀ọbalúayé Brítánì

 China (at war 1937–45)

 France[nb 2]
 Poland
 Canada
 Australia
 New Zealand
 South Africa
 Yugoslavia (1941–45)
 Greece (1940–45)
 Norway (1940–45)
 Netherlands (1940–45)
 Belgium (1940–45)
 Czechoslovakia
 Philippines (1941–45)
 Brasil (1942–45)
...and others

Àwọn Olóòpó

 Germany
 Japan (at war 1937–45)

 Italy (1940–43)

 Hungary (1941–45)
 Romania (1941–44)
 Bulgaria (1941–44)
 Thailand (1942–45)


Co-belligerents
 Finland (1941–44)
 Iraq (1941)


Puppet states
 Manchukuo
 Croatia (1941–45)
 Slovakia
...and others

Àwọn apàṣẹ
Allied leaders

Ìsọ̀kan Sófìẹ̀tì Joseph Stalin
Àwọn Ìpínlẹ̀ Aṣọ̀kan Franklin D. Roosevelt
Ilẹ̀ọba Aṣọ̀kan Winston Churchill
Republic of China Chiang Kai-shek
...and others

Axis leaders

Nazi Germany Adolf Hitler
Empire of Japan Hirohito
Kingdom of Italy (1861–1946) Benito Mussolini  Executed
...and others

Òfò àti ìfarapa
Military dead:
Over 16,000,000
Civilian dead:
Over 45,000,000
Total dead:
Over 61,000,000 (1937–45)
...further details
Military dead:
Over 8,000,000
Civilian dead:
Over 4,000,000
Total dead:
Over 12,000,000 (1937–45)
...further details

Bí ó ṣe bẹ̀rẹ̀

àtúnṣe

A gbọ́ wípé ogun àgbáyé ẹlẹ́kejì yí bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kínní oṣù Kẹsàn an ọdún 1939, nígbà tí orílẹ̀-èdè ilé-iṣẹ́ ológun Nazi ti ilẹ̀ Germany kọlu orílẹ̀-èdè Pólándì tí àjọ ìṣọ̀kan United Kingdom àti orílẹ̀-èdè Faransé náà sì ṣígun kọlu orílẹ̀-èdè Germany lẹ́ni tí ó ń gbèjà orílẹ̀-èdè Pólándì ní ọjọ́ kẹta tí Germany kọlu Pólándì. Níparí ọdún 1939 sí 1941, orílẹ̀-èdè Germany ti ń ṣàkóso lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀ àti Ìlú ní apá Yúróòpù, lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìfọwọ́bọ̀wé àdéhùn àti òfin oríṣiríṣi. Lẹ́yìn èyí, orílẹ̀-èdè Germany, orílẹ̀-èdè Japan àti orílẹ̀-èdè Italy kórapọ̀ di ọ̀kan tí wọ́n pe orúkọ wọn ní Axis Alliance, nígbà tí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn náà sì ń dara pọ̀ mọ̀ wọn nígbà tí ó yá. Nínú we àdéhùn tí ọ̀gágun Molotov–Ribbentrop fọwọ́bọ̀ ní oṣù Kẹjọ ọdún 1939, orílẹ̀-èdè Germany àti Soviet Union nígbà náà fọwọ́-sowọ́pọ̀ láti túbọ̀ gba àwọn ilẹ̀ àwọn alámùúlégbè wọn ní Yúróòpù siwájú si.




Footnotes
  1. 23 August 1939, the USSR and Germany sign non-aggression pact, secretly dividing Eastern Europe into spheres of influence. USSR armistice with Japan 16 September 1939; invades Poland 17 September 1939; attacks Finland 30 September 1939; forcibly incorporates Baltic States June 1940; takes eastern Romania 4 July 1940. 22 June 1941, USSR is invaded by European Axis; USSR aligns with countries fighting Axis.
  2. After the fall of the Third Republic 1940, the de facto government was the Vichy Regime. It conducted pro-Axis policies until November 1942 while remaining formally neutral. The Free French Forces, based out of London, were recognized by all Allies as the official government in September 1944.


Àwọn ìtókasí

àtúnṣe