Sọjí Cole tí àpèjẹ́ rẹ̀ ń jé Olúsọjí Henry Cole jẹ́ ònkọ̀wé [1] , òṣèré, adarí eré ìtàgé àti sinimá ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.Wọ́n bí Olúsọjí Henry Cole ní ọjọ́ Kẹtàdínlógún oṣù Ọ̀pẹ, ọdún 1976 ní òpópónà Kókà ní ìlú Mushinìpínlẹ̀ Èkó. Ọ̀mọ̀wé Cole gba ẹ̀bun Nigeria Prize for Literature ti ọdún 2018.[2]

Soji Cole
Dr. Soji Cole in his office (2018)
Ọmọ orílẹ̀-èdèNigerian
Alma materUniversity of Ibadan
GenreShort story, Realistic fiction, drama


Ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀

àtúnṣe

Sọjí bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ilé-ẹ̀kọ́ alákọọ́bẹ̀rẹ̀ St. Micheal ti Olóòṣà, tí ó sì parí rẹ̀ ní ilé-ẹ̀kọ́ alákọọ́bẹ̀rẹ Àgọ́ Òwu ní Ṣógúnlẹ̀ìpínlẹ̀ Èkó. Lẹ́yìn èyí ni ó tẹ̀ síwájú ní ilé-ẹ̀kọ́ Girama ti Ìkẹjà, tí ó wà ní Oṣòdì, ó tún lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ Girama Ẹ̀wù Tun-Tun tí ó wà ní Máfolúkùìpínlẹ̀ Èkó àti iké-ẹ̀kọ́ Girama Orímọládé ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun. Bákan náà ni ó tún lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ gbogbo-nìṣe (UI) ti ìlú Ìbàdàn níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ gbàwé ẹ̀rí dípúlọ́mà, gboyè àkọ́kọ́ (B.a) ní ọdún 2006, gboyè ẹlẹ́ẹ̀kejì (M.a) ní ọdún 2010, àti oyè ọ̀mọ̀wé (PHD) ní ọdún 2016 nínú ìmọ̀ eré orí ìtàgé "Theatre Arts". Tí ó sì ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ àti adarí fún ìpele àpilẹ̀kọ́ eré orí ìtàgé eré oníṣe abáwùjọ mu ní agbọ̀n Theatre Arts ti ilé-ẹ̀kọ́ gbogbo-nìṣe ti ìlú Ìbàdàn, níbi tí ó ti kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àpilẹ̀kọ fún ṣíṣe ní orí pẹpẹ, amóhùn-máwọ́rán, àti ọ̀pọ̀ sinimá tó ti dàgbéléwò. Ẹ̀wẹ̀, ó tún jẹ́ olùdarí fún eré ìtàgé àti sinimá, bákan náà ni ó tún jẹ́ òṣèré orí ìtàgé. Nínú ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀ yí ló ti gba àwọn ètò ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ àti àwọ̀n àmì ẹ̀yẹ̀ lọóríṣiríṣi.[3]

Àwọn àmì ẹ̀yẹ tó ti gbà

àtúnṣe

Ó gba àmì ẹ̀yẹ Akẹ́kọ̀ọ-jáde tó pegedé jùlọ ní ọdún 2006, ní agbọ̀n ẹ̀kọ́ òṣèré orí ìtàgé ìyẹn ( Theatre Arts) ní UI, ó jáwé olúborí tí ó sì gbàmì ẹ̀yẹ́ gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ̀ọ́ tó mọ ìtàn eré orí ìtàgé kọ jùlọ nínú ìdíje Zulu Sofola ní agbọ̀n ẹ̀kọ́ Theatre Atrs bákan náà ní ọdún 2006. Òun ló gba ipò àkọ́kọ́ nínú ìdíje African Theatre Association, (AFTA) tí ó sì gba àmì ẹ̀yẹ Scholars ní ọdún 2011. Ẹ̀wẹ̀, kò dúró níbẹ̀, ó tún gba àmì ẹ̀yẹ Onímọ̀ tuntun ( New Scholar) láti ọ̀dọ̀ (IFTR/FIRT) tí ó túmọ̀ sí International Federation for Theatre Research látàrí iṣẹ́ ìwádí rẹ̀ tó pegedé ní ọdún 2013. Bákan náà ló tún jànfàní ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ ́(Diversity Studies international Teaching and Schorlaship Network Fellowship) láti ọ̀dọ̀ Fasitì Carl Von Ossietzsky Univeraity tí ó wà ní Oldenburg ní orílẹ̀ èdè Jamaní ní ọdún 2013. Kò yán síbẹ̀, ó tún gba àmì ẹ̀yẹ ẹni tó mọ àpilẹ̀kọ eré-oníṣe kọ jùlọ nínú ìdíje tí (ANA) ìyẹn Association of Nigerian Authors gbé kalẹ̀ ní ọdún 2014. Bẹ́ẹ̀ kẹ̀, ó tún gba àmì ẹ̀yẹ ìkópa nílé ẹ̀kọ́ Fasitì ìpílẹ̀ Kansas ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ní oṣù Kẹ́jọ 2014 sí oṣù Kẹ́rin ọdún 2015. Ó tún gba àmì ẹ̀yẹ INASP Travel Fellowship fún ìdíje (AUTHORAID) ní ọdún 2015 .Ó tún jẹ ànfàní ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ nílé ẹ̀kọ́ Fásitì Augsburg ní orílẹ̀ ẹ̀dẹ̀ Jamanì fún ( Diversity Studies International) ní ọdún 2017. Ó sì gba ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ gẹ́gẹ́ bí (Olùbẹ̀wò àti Onímọ̀ ìwádí) sí Center for Research and Creative Exchange ní ilé ẹ̀kọ́ Fásitì Roehampton ní ìlú UK ní ọdún 2018. Kí ó tó fọba àmì ẹ̀yẹ (NLNG) ìdíje Nigerian Prize for Literature tí ó gbà pẹ̀lú ìwé rẹ̀ *Ember* fa ọwọ́ rẹ̀ sókè gbọgbọrọ tí ọwọ́ ń yọ jorí láàrín àwọn akẹ́gbẹ́ rẹ̀ tókù ní ọdún 2018.[4]

Iṣẹ́-ǹ-ṣe àti àwọn iṣẹ́ ìwádí rẹ̀

àtúnṣe

a.Applied Theatre / Theatre Therapy. b.Performnce as Practice and Research. d.Trauma and Memory Studies in Drama and Performance.[5]

e.Literary and Performance Criticism. ẹ.Playwriting, Acting and Directing.

Àwọn Iṣẹ́ Àtẹ̀jáde rẹ̀

àtúnṣe
  • Àwọn tí ó jẹ́ eré oníṣe

1. Maybe Tomorrow (2013), published by Kraft Books Ltd. (Winner of the 2014 ANA Playwriting Prize and nominated as one of the best 20 plays for the BBC Radio Play competition in 2007)

2. Embers (2018), published Emotion Press Ltd. (Winner of the Nigeria Prize for Drama 2018)

  • Àwọn tí ó jẹ mọ́ ìtàn kúkúrú

1. My Little Stream tí ilé iṣẹ́ CCC Press, United Kingdom tẹ̀ jáde nì ọdún 2010.

2. Ghost tí ANA REVIEW gbé jáde ní ọdún 2014.

3. Bambo Bambo tí ANA REVIEW gbé jáde ní ọdún 2017.

4. Silence tí ilẹ́ iṣẹ́ atẹ̀wé-jáde Pacesetters tẹ̀ jáde nínú ìwé Magasíínì.

  • Ewì àpilẹ̀kọ rẹ̀

The Presidents Visit tí ilẹ́ iṣẹ́ atẹ̀wé-jáde Pacesetters tẹ̀ jáde nínú ìwé Magasíínì.

Eré orí ìtàgé àti fíìmù tó ti kópa

àtúnṣe

1. Death and the Kings Horseman, for FESTINA 2001, Lagos (Òṣèré).[6]

2. Marriage of Anansewa, Departmental play, Department of Theatre Arts, University of Ibadan, 2001 (Òṣèré).

3. Hopes of the living dead, University of Ibadan convocation play, 2002 (Òṣèré).

4. Àgbàlagbà Akàn, a Yoruba movie shot in 2002, Oyo (Òṣèré)

5. International cargo, for NUCAFEST, 2004, Abuja. (Òṣèré àti Alámòójútó).

6. Langbodo, University of Ibadan convocation play, 2004 (Alámòójútó ìgbéré-jáde)

7. Sweet trap, Departmental play, Department of Theatre Arts, University of Ibadan, 2005 (Òṣèré)

8. Isara, for the 20th year celebration of Wole Soyinkas winning of the Nobel Prize for literature, 2006, Ibadan and Ife. (Òṣèré)

9. Lángbòdó, performed for Ogun State Government to celebrate democracy day, 2006, Abeokuta. (Òṣèré)

10. Murhya, for NAFEST 2007, Enugu (Olùkọ̀tàn àti Òṣèré tí ó ń ṣojú ìpínlẹ̀ Yóbè)

11. Sweet Mother, childrens drama for the 60th anniversary celebration of Children Home School; the first private nursery and primary school in Nigeria, 2008 (Olùkọ̀tàn àti Ọ́ṣèré)

12. Eniyan, for Ogun state government, 2009, Abeokuta (Òṣèré)

13. Wizard of Law, for Lagos state secondary schools, 2009 (Amúgbá-lẹ́gbẹ̀ẹ́ àti Òṣèré)

14. Ireke Onibudo, for Chams Theatre series 2009 (Alámòójútó ìtàgé)

15.The woman of Calabar (TV) for KAYMOUZO PRODUCTIONS. 2009. (Alátúntò àpilẹ̀kọ àti alámòójútó ìgbé-jáde eré)

16. Who is afraid of Solarin, for FOLK HERITAGE MULTIMEDIA (performed at O.A.U), 2009 (Olùdarí)

17. VIP (TV) for AMAKA IGWE STUDIO. 2010. (Amúgbá-lẹ́gbẹ̀ẹ́ Olùgbéré-jáde

18. The Engagement, University of Ibadan (Olùgbéré-jáde àti Adarí) 2011

19. Maybe Tomorrow, sponsored by Naija dreams Ltd., Abuja, 2011 (Olùkọ̀tàn àti òṣèré)

20. Women of Owu, produced by The Classical Society of Nigeria and The Department of Classics, University of Ibadan, 2011 (Alámòójútó ìtàgé)

21. Kongis Harvest: sponsored by National Association of Seadogs in celebration of the 25th anniversary of Wole Soyinkas Nobel Prize 2011 (Òṣèré)

22. Loves unlike lading, a play written by Femi Osofisan, 2011 (Òṣèré)

23. A Tempest, a play written by Aime Cesaire and produced for the Lagos Heritage Festival, 2012 (Amúgbá-lẹ́gbẹ̀ẹ́ adarí eré/ Alámòójútó ìtàgé)

24. Sortilege (Black Mystery), a play written by Abdias Do Nascimento and produced for the Lagos Heritage Festival, 2013 (Amúgbá-lẹ́gbẹ̀ẹ́ adarí eré/ Alámòójútó ìtàgé)

25. Victims of War, a feature length film by Christ Chariot Media 2013 (Adarí eré)

26. Alapata Apata, premier play of Professor Wole Soyinka at the Ake Book and Arts Festival, Abeokuta, Nigeria, 2013 (Amúgbá-lẹ́gbẹ̀ẹ́ adarí eré/Alámòójútó ìtàgé)

27. The Hiss & The Sisters, premier plays of Professor J.P. Clark to commemorate his 80th birthday, Lagos, Nigeria, 2013 (Alámòójútó ìtàgé)

28. The Queen of the Night, a play production by the British Council Nigeria for the 2014 Lagos Theatre Festival, 2014 (Olùkọ̀tàn)

29. Robin Hood (an adaptation) by Sally Bailey at the Manhattan Arts Center, Manhattan, Kansas, USA, April 2015 (Òṣèré)

30. Marriage of Anansewa, University of Ibadan Convocation Play 2015, (Director)

31. Shaka Zulu, University of Ibadan Convocation Play 2016 (Adarí eré)

32. Death and the Kings Horseman, University of Ibadan Convocation Play 2018 (Amúgbá-lẹ́gbẹ̀ẹ́ adarí eré)

Ẹbí rẹ̀

àtúnṣe

Olúsọjí Henry Cole ń gbé ní ìlú Ìbàdàn pẹ̀lú àwọn ìyàwó àti ọmọ rẹ̀.[7]

Àwọn ìtọ́ka sí

àtúnṣe
  1. "African Books Collective: Soji Cole". africanbookscollective.com. Retrieved 2021-02-22. 
  2. "Pomp, drama as Soji Cole wins 2018 Nigeria Prize for Literature". Nigerian Tribune. Archived from the original on 2019-01-01. Retrieved 2018-12-17. 
  3. Sam-Duru, Prisca (2018-10-20). "Soji Cole wins $100,000 NLNG Prize for Literature". Vanguard News Nigeria. Retrieved 2018-12-17. 
  4. "Soji Cole - University of Ibadan Nigeria". Academia.edu. 2015-08-03. Retrieved 2018-12-17. 
  5. "Pomp, drama as Soji Cole wins 2018 Nigeria Prize for Literature". Tribune Online. 2018-10-27. Archived from the original on 2019-01-01. Retrieved 2018-12-17. 
  6. dickson (2018-11-23). "NLNG, A Tedious Journey of Expectation & Anxiety – Soji Cole". Leadership Newspaper. Retrieved 2018-12-17. 
  7. "Dr. Soji Cole Archives - Nigeria and World News". The Guardian Nigeria Newspaper - Nigeria and World News. Retrieved 2018-12-17.