Olubunmi Olateru Olagbegi
Olubunmi Olateru Olagbegi, OFR jẹ́ ọmọ ilé-ìgbìmọ̀ Nàìjíríà àti adájọ́ àgbà tẹ́lẹ̀ ti Ìpínlẹ̀ Ondo, Nàìjíríà. Ó tún jẹ́ olùkàwé ní Yunifásítì Afe Babalola. [1]
Olubunmi Olateru Olagbegi | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Ile-Ife, Oyo State, Nigeria |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Iṣẹ́ |
|
Ìgbà iṣẹ́ | 1973 - Present |
Àwọn olùbátan | Folagbade Olateru Olagbegi III brother |
Awards | OFR |
Ẹgbẹ́
àtúnṣe- Nigerian Body of Benchers
- Nigerian Bar Association
- National Judicial Council
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ Ayé Rẹ̀
àtúnṣeÌdílé Omitowoju ní Ilé-Ifẹ̀, ìlú kan ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ni wọ́n bí Adájọ́ Olubunmi. Ìyàwó sínú ìdílé Ọlágbẹ́gi, ìdílé ọba ní Ọ̀wọ̀ ní ìpínlẹ̀ Ondo, Nàìjíríà. Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì ti London níbi tí ó ti gba ìwé ẹ̀rí àti oye òye iṣẹ́ Òfin. Ní ọdún 1990, wọn yàn án sí ibùjókòó ti Adájọ́ ilé-ẹjọ́ gíga kan ti Ìdájọ́ Ìpínlẹ̀ Ondo àti ní ọdún 2003, ó di adájọ́ àgbà ti adájọ́ ìpínlẹ̀ náà. Ọdún méje ló ṣiṣẹ́ yìí kó tó di pé ó fẹ̀yìntì iṣẹ́ náà ní ọjọ́ kẹrin-dín-lọ́gbọ̀n oṣù kẹwàá ọdún 2010. Ní ọjọ́ kejì-dín-lọ́gbọ̀n oṣù kejìlá ọdún 2008 ni Olóyè Olusegun Obasanjo, Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nígbà náà fún un ní ọlá ti orílẹ̀-èdè. [1]
Àwọn Ìtọ́ka Sí
àtúnṣe- ↑ 1.0 1.1 "Gladys Olumbuni Olateru Olegbegi". Afe Babalola University. Archived from the original on 4 March 2016. Retrieved 16 April 2016.