Rachel Oniga (tí a bí ní 23 Oṣù Kaàrún, Ọdún 1957) jẹ́ òṣèré orí-ìtàgé ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà[1]

Rachel Oniga
Ọjọ́ìbí23 Oṣù Kàrún 1957 (1957-05-23) (ọmọ ọdún 67)
Ebute Metta, Lagos, Lagos State, Nigeria.
Aláìsí2021
Orílẹ̀-èdèNigerian
Orúkọ mírànTabuno
Ọmọ orílẹ̀-èdèNigerian
Iṣẹ́film actress
Ìgbà iṣẹ́1993-2022
Notable workSango (Film)

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti iṣẹ̀ ìṣe rẹ̀

àtúnṣe

Rachel Oniga wá láti agbègbè Eku, ní Ìpínlẹ̀ Dẹ́ltà ṣùgbọ́n tí a bí ní Èbútté Mẹ́tta, Ìpínlẹ̀ Èkó.[2] Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òṣèré rẹ̀ ní ọdún 1993 ní kété tí ó pínyà pẹ̀lú ọkọ rẹ̀.[3] Ó kọ́kọ́ ṣiṣẹ́ fún ìgbà díè ní ilé-iṣẹ́ alámọ̀ràn Ascoline Nigeria Limited, ṣááju kí ó tó kó àkọ́kọ́ ipa rẹ̀, èyí tó wáyé nínu sinimá tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Ọnọmẹ́. Ṣùgbọ́n àkọ́kọ́ ipa rẹ̀ nínu eré èdè Yorùbá wáyé níbi kíkópa rẹ̀ nínu Owó Blow.[4] Ó ti wá ṣe bẹ́ẹ̀ kópa nínu àwọn fíìmù míràn tó lórúkọ bíi fíìmù Ṣàngó, èyí tí Wálé Ògúnyẹmí kọ, tí Ọbáfẹ́mi Lasode sì ṣe àgbékalẹ̀ àti ìdarí rẹ̀.[5] Ó sì tún ti kópa nínu eré tẹlifíṣọ̀nù Super story tí Wálé Adénúgà ṣe.

Ọ̀rọ̀ ayé rẹ̀

àtúnṣe

Rachael ti ní ọmọọmọ lẹ́hìn tí ọmọ bíbí inú rẹ̀ obìnrin náà ti di ìyá.[6]

Àwọn àṣàyàn eŕe rẹ̀

àtúnṣe
  • Sango (1997)
  • Out of Bounds (1997)
  • Owo Blow (1997)
  • Passion of Mind (2004)
  • Power Of Sin,
  • Restless Mind
  • Doctor Bello (2013)
  • 30 Days in Atlanta (2014)
  • [The Royal Hibiscus Hotel] (2017)
  • Power of 1 (2018)
  • The Wedding Party

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. "My Late Husband Abandoned Me For Another WomanRachael Oniga Laments - nigeriafilms.com". nigeriafilms.com. Retrieved 20 January 2015. 
  2. BOLDWIN ANUGWARA. "I’ll never marry except... – Rachael Oniga - Newswatch Times". Newswatch Times. Retrieved 20 January 2015. 
  3. BOLDWIN ANUGWARA. "I’ll never marry except... – Rachael Oniga - Newswatch Times". Newswatch Times. Retrieved 20 January 2015. 
  4. "I was a tomboy –Rachael Oniga". Daily Independent, Nigerian Newspaper. Retrieved 20 January 2015. 
  5. "Africultures - Fiche film : Sango". africultures.com. Retrieved 20 January 2015. 
  6. Dayo Showemimo. "Veteran actress, Rachael Oniga, becomes grandmother". Nigerian Entertainment Today. http://thenet.ng/2014/09/veteran-actress-rachael-oniga-becomes-grandmother/. Retrieved March 29, 2015.