Rahmon Adédoyin
Ọmọba Rahmon Adégòkè Adédoyin ẹni tí wọ́n bí ní ọjọ́ Kínì oṣù Kíní, ọdún 1957 (born January 1, 1957) jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè is a Nàjíríà. Olùkọ́ni, àti bajú-gbajà oníṣòwò ,bákan náà ni ó jẹ́ olùdásílẹ̀ iké-ẹ̀kọ́ Fásitì Odùduwà àti ilé-ẹ̀kọ́ gbogb-nìṣe Polytechnic, ní Ilé-Ifẹ̀[1] Nínú ìtàkurọ̀sọ rẹ̀ pẹ̀lú aṣojú ilé-iṣẹ́ ìwé ìròyìn Vanguard, Rahmon fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé Ọba Okùnadé Ṣìjúadé tí ó wàjà kọjá nílé-Ifẹ̀ ni ó yan ọòun gẹ́gẹ́ bí Ọọ̀ni Ilé-Ifẹ̀ ṣáájú kí ó tó gbésẹ̀ nítorí iṣẹ́ ìdàgbà-sókè ribiribi tí òun gbé ṣe ní ìlú náà, pàápàá jùlọ nílẹ̀ Yorùbá lápapọ̀.[2]
Rahmon Adedoyin | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Rahmon Adegoke Adedoyin 1 Oṣù Kínní 1957 Ile-Ife, Osun State, Nigeria |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Iléẹ̀kọ́ gíga | University of Ife All Saints University School of Medicine |
Iṣẹ́ | |
Ìgbà iṣẹ́ | 1990–present |
Notable work | Oduduwa University The Polytechnic, Ile-Ife |
Ìbẹ̀rẹ̀ ayé, ẹ̀kọ́ àti iṣẹ́ rẹ̀
àtúnṣeRahmon Adégòkè ni wọ̀n bí nídìílé ọba Akui, ní Ilé-Ifẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun[3] níbi tí ó ti parí ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti ilé-ẹ̀kọ́ girama rẹ̀. Ó tẹ̀ síwájú nílé-ẹ̀kọ́ Fásitì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ níbi tí ó ti gba oyè àkọ́kọ́ nínú ìmọ̀ Sáyẹ́nsì ní ọdún 1983, lẹ́yìn èyì ni ó tú kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ìṣirò ( Mathematics Education). Ẹ̀wẹ̀, ó tún lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ fásitì Centurion International ní orílẹ̀-èdè California, níbi tí ó ti gba oyè ìmọ̀ ẹlẹ́kej (master's degree), tí ó sì tún gba oyè ìmọ̀ ọ̀mọ̀wé ( doctorate degree) nílé ẹ̀kọ́ All Saints University School of Medicine, New York City, ní ọdún 1966.[4]
Pẹ̀lú ìgbìyànjú rẹ̀ láti gbẹ́ ẹ̀ka ètò ẹ̀kọ́ sókè ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Ó dá ilé-ẹ̀kọ́ gbogbo-nìṣe ( Polytechnic), Ile-Ife kalẹ̀ ní ọdún 1984 tí ó sì dá Fásitì Oduduwa náà kalẹ̀ ní ọdún 2009. Rahmon jẹ́ ọ̀kan gbòógì lára àwọn Industrial Statisticians ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà[4]
Àwọn ìtọ̀ka sí
àtúnṣe- ↑ "Adedoyin Claims Late Ooni Of Ife Nominated Him As Successor". Naij. 17 August 2015. https://www.naij.com/520022-ooni-death-adedoyin-claims-ooni-nominated-succesor-demis.html. Retrieved 13 September 2015.
- ↑ "Ooni nominated me as his successor before he died – Adedoyin". Vanguard News. 16 August 2015. https://www.vanguardngr.com/2015/08/ooni-nominated-me-as-his-succesor-before-he-died-adedoyin-2/. Retrieved 13 September 2015.
- ↑ .
- ↑ 4.0 4.1 .