Steph-Nora Okere

Steph-Nora Okere jẹ́ òṣèrébìnrin àti ònkọ̀tàn eré ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó gba àmì-ẹ̀yẹ Special Recognition Award níbi ayẹyẹ City People Entertainment Awards ní ọdún 2016.[1] Ní ọdún 2015 Okere jẹ igbákejì Ààrẹ ẹgbẹ́ Script Writers Guild of Nigeria (SWGN).[2]

Steph-Nora Okere
Ọjọ́ìbíSteph-Nora Okere
26 Oṣù Kẹrin 1974 (1974-04-26) (ọmọ ọdún 48)
Imo State
Orílẹ̀-èdèNigerian
Iléẹ̀kọ́ gígaUniversity of Ife
Iṣẹ́Actress
Ìgbà iṣẹ́1994-Present

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀Àtúnṣe

̀Wọ́n bí Okere ní ìlú Owerri, èyítí ó jẹ́ olú-ìlú Ìpínlẹ̀ Ímò ní gúúsù ìla-òòrùn Nàìjíríà. Nígbà tí ó wà lọ́mọdé, ó kó lọ sí ìlú Èkó níbi tí ó ti ní ètò-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ rè láti ilé-ìwé St Paul Primary School tí ó wà ní Ebute Metta. Okere padà sí ìpínlẹ̀ abínibí rẹ̀ níbi tí ó ti ní ètò-ẹ̀kọ́ girama rẹ̀ láti ilé-ìwé Akwakuma Secondary School. Ó gba oyè-ẹ̀kọ́ nínu ìmọ̀ eré ìtàgé láti Yunifásítì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ tí ó wà ní Ilé-Ifẹ̀.[3][4]

Iṣẹ́ ìṣe rẹ̀Àtúnṣe

Ṣááju kí Okere tó kópa nínu fíìmù Nollywood ní ọdún 1994 nígbà tí ó wà lọ́mọ ọdún mọ́kànlélógún, ó maá n ṣe eré orí ìpele.[5]

Àwọn àmì-ẹ̀yẹ rẹ̀Àtúnṣe

Okere gba àmì-ẹ̀yẹ Special Recognition Award níbi ayẹyẹ City People Entertainment Awards ti ọdún 2016.[6]

Ọ̀rọ̀ ayé rẹ̀Àtúnṣe

Okere ti sọ ní gbangba pẹ́ òun fẹ́ràn ọkùnrin akẹgbẹ́ rẹ̀ kan tí orúkọ rẹ̀ n ṣe Jim Iyke.[7][8]

Àwọn àṣàyàn eré rẹ̀Àtúnṣe

 • African Time (2014)
 • Big Heart Treasure (2007)
 • Eleda Teju (2007)
 • Angels Forever (2006)
 • Joy Of A Mother (2006)
 • Destiny’s Challenge (2005)
 • Empire (2005)
 • Fake Angel (2005)
 • Immoral Act (2005)
 • Aye Jobele (2005)
 • Circle Of Tears 2004)
 • Dark Secret (2004)
 • Indecent Girl (2004)
 • Lost Paradise (2004)
 • Singles & Married (2004)
 • Aristos (2003)
 • Bleeding Love (2003)

Àwọn ìtọ́kasíÀtúnṣe

 1. "Timeless Nollywood Actress, Steph-Nora Okere". guardian.ng (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-12-06. 
 2. "My marriage would have made me a sad woman – Steph Nora Okere". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2015-05-02. Retrieved 2019-12-06. 
 3. Ogbeche, Danielle. "I’m married to Jesus – Steph-Nora Okere opens up on failed relationships" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-12-06. 
 4. "Steph Nora Okere, actress (Beauty Secrets of the Rich and Famous) | Encomium Magazine" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-12-06. 
 5. Published. "BoI supports Okere’s new film". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-12-06. 
 6. "Steph Nora Okere Opens Up On Her Failed Marriage ⋆". www.herald.ng. Retrieved 2019-12-06. 
 7. Oleniju, Segun (2015-05-03). "Steph Nora Okere Talks Her Relationship With Jim Iyke and Her Failed Marriage to Lanre Falana | 36NG" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-12-06. 
 8. "Steph Nora Okere 'It's impossible to live away from Jim Iyke' actress opens up". www.pulse.ng. Retrieved 2019-12-06.