Tana Adelana

òṣèré orí ìtàgé
(Àtúnjúwe láti Tana Adélànà)

Christiana Nkemdilim Adélànà tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Tana Adelana (tí wọ́n bí lọ́jọ́ kẹrìnlélógún oṣù Kejìlá ọdún 1984)[1] jẹ́ gbajúmọ̀ Òṣèrébìnrin sinimá àgbéléwò, Olóòtú, afẹ̀wàṣojú, Atọ́kùn ètò tẹlifíṣàn àti oníṣòwò ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó gbàmìn ẹ̀yẹ ammúgbalẹ́gbẹ̀ẹ́ olú-ẹ̀dá-ìtàn ti CITY People’s Movie Awards lọ́dún 2017,[2] bẹ́ẹ̀ náà, ó gbàmìn-ẹ̀yẹ the future Awardsfún Atọ́kùn ètò orí telifisan tó dára jù lọ lọ́dún 2011,[3] àti àmìn-ẹ̀yẹ, the Grind Awards lọ́dún 2095.[4] Tana jẹ́ ọmọ Igbo, láti idile Egbo.[5]

Tana Adélànà
Ọjọ́ìbíChristiana Nkemdilim Egbo
24 Oṣù Kejìlá 1984 (1984-12-24) (ọmọ ọdún 40)
Èkó, Ìpínlẹ̀ Èkó, Nàìjíríà
Ọmọ orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Iléẹ̀kọ́ gígaUniversity of Lagos
Iṣẹ́Òṣèrébìnrin, Olóòtú, afẹ̀wàṣojú, Atọ́kùn ètò tẹlifíṣàn àti oníṣòwò
Websitehttps://www.tanaadelana.com

Ìgbà èwe ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀

àtúnṣe

Wọ́n bí Tana Adélànà sí ìdílé ọba àti ìjọ Kátólíìkì lọ́dún 1984. Ó jẹ́ ọmọ bíbí Nara Unateze ní ìjọba ìbílẹ̀ Nkanu East LGA ní Ìpínlẹ̀ Enugu. [6]. Òun ni àbígbẹ̀yìn nínú àwọn ọmọ mẹ́wàá tí àwọn òbí rẹ̀ bí.

Ó bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ ní Treasure Land Nursery and Primary school, Sùúrùlérè, ní Ìpínlẹ̀ Èkó lórílẹ̀ Nàìjíríà, bẹ́ẹ̀ náà ló tẹ̀ síwájú ní St. Francis Catholic Secondary School ní Idimu,ní Èkó bákan náà.  Tana kàwé gboyè dìgírì nínú ìmọ̀ àtò àgbègbè àti ìlú, (Urban and Regional Planning) ní University of Lagos, Nàìjíríà. Lẹ́yìn èyí, ó kàwé gboyè dípólómà nínú ìmọ̀ aṣaralógé ní London. Lẹ́yìn náà, ó lọ sí Metropolitan School of Business and Management, ní United Kingdom, ó sìn gboyè dìgírì kejì (special executive masters certificate).[7]

Iṣẹ́

àtúnṣe

Ìràwọ̀ Tana bẹ̀rẹ̀ sí ní tàn lẹ́yìn tó pegedé nínú nínú ìdánwò MTN Y’Hello TV Show lọ́dún 2002 fún atọ́kùn ètò. Bẹ́ẹ̀ náà òun ni ọmọ Nàìjíríà àkọ́kọ́ láti tọ́kùn ètò lórí ìkànnìChannel O [8] níbẹ̀ ló ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ eré ṣíṣe lórí tèlifíṣàn. Ó dá ilé iṣẹ́ sinimá tirẹ̀ sílẹ̀ lọ́dún 2013 tí ó pè ní Tana Adelana.[9] Lára àwọn sinimá àgbéléwò wọn ní Quick Sand,[10] níbi tí Ufuoma Ejenobor, Chelsea Eze, Wale Macaulay, Anthony Monjaro, Femi Jacobs àti àwọn gbajúmọ̀ Òṣeré mìíràn ti kópa.

Àwọn àmìn-ẹ̀yẹ

àtúnṣe
  • Lọ́dún 2011, ó gbàmín-ẹ̀yẹ atọ́kùn ètò tèlifíṣàn tó dára jù lọ ní Future Awards[11]
  • Àmìn ẹ̀yẹ Grind Awards lọ́dún 2015.[12]
  • Àmìn ẹ̀yẹ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ olú ẹ̀dá ìtàn tí ó dára jù lọ ti CITY People’s Movie Awards lọ́dún 2017.[13]

Àṣàyàn àwọn sinimá rẹ̀

àtúnṣe
  • Mr. and Mrs. Revolution (2017)[14]
  • Body Language (2017)[15]
  • Baby daddy (2017)[16]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe
  1. ""Actor, Frederick Is One Of The Handsome Men In The Industry": See Cute Photos Him And Other Actress". www.operanewsapp.com. Retrieved 2020-05-27. 
  2. "TANA ADELANA WINS CITY PEOPLE AWARD FOR BEST SUPPORTING ACTRESS OF 2017 - Glance Online" (in en-US). Glance Online. 2017-10-09. Archived from the original on 2018-11-15. https://web.archive.org/web/20181115153903/https://www.glanceng.com/2017/10/09/tana-adelana-wins-city-people-award-for-best-supporting-actress-of-2017/. 
  3. "The Future Awards 2009 Winners". Linda Ikeji's Blog (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2009-01-19. Retrieved 2018-08-09. 
  4. "Wife, Mum, TV Host, VJ...The List Goes On - Tana Adelana tells BN how she does it! - BellaNaija". www.bellanaija.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2011-09-07. Retrieved 2018-08-09. 
  5. Pulse Nigeria (2015-07-07), Full interview: Chat with Nollywood Actress Tana Adelana - Pulse TV One On One, retrieved 2018-08-08 
  6. "Tana Adelana". www.manpower.com.ng (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2018-09-22. 
  7. "Punch Newspaper - Breaking News, Nigerian News & Multimedia". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-02-07. 
  8. "Wife, Mum, TV Host, VJ...The List Goes On - Tana Adelana tells BN how she does it! - BellaNaija". www.bellanaija.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2011-09-07. Retrieved 2018-08-08. 
  9. "Wife, Mum, TV Host, VJ...The List Goes On - Tana Adelana tells BN how she does it! - BellaNaija". www.bellanaija.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2011-09-07. Retrieved 2018-08-08. 
  10. AfrinollyMeets (2013-07-04), 'Quick Sand' TV Series - Behind The Scenes, retrieved 2018-08-08 
  11. "TFAA 2011 Winners List - The Future Awards Africa" (in en-GB). The Future Awards Africa. http://thefutureafrica.com/awards/past-winners/year-2011/. 
  12. "Wife, Mum, TV Host, VJ...The List Goes On - Tana Adelana tells BN how she does it! - BellaNaija". www.bellanaija.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2011-09-07. Retrieved 2018-08-09. 
  13. "TANA ADELANA WINS CITY PEOPLE AWARD FOR BEST SUPPORTING ACTRESS OF 2017 - Glance Online" (in en-US). Glance Online. 2017-10-09. Archived from the original on 2018-11-15. https://web.archive.org/web/20181115153903/https://www.glanceng.com/2017/10/09/tana-adelana-wins-city-people-award-for-best-supporting-actress-of-2017/. 
  14. FP. "Mr. and Mrs. Revolution | Review & Trailer | Fried Plantains". Fried Plaintains (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2018-08-08. 
  15. Royal Arts Academy TV (2017-09-08), BODY LANGUAGE TEASER LATEST 2017 MOVIE, retrieved 2018-08-08 
  16. IROKOTV Nigerian Movies 2017 - Best of Nollywood [#6] (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì), retrieved 2018-08-08