Tariro Washe Mnangagwa (tí wọ́n bí ní ọdún 1986) jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Sìmbábúè.[1] Ó gbajúmọ̀ jùlọ fún ipa rẹ̀ tí ó kó nínu eré kan ti ọdún 2020 tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Gonarezhou. Ó jẹ́ ọ̀kan nínu àwọn ọmọ obìnrin Ààrẹ orílẹ̀-èdè Sìmbábúè lọ́wọ́lọ́wọ́ ti orúkọ rẹ̀ n ṣe Emmerson Mnangagwa.

Tariro Mnangagwa
Ọjọ́ìbíTariro Washe Mnangagwa
1986
Zambia
Orílẹ̀-èdèZimbabwean
Iléẹ̀kọ́ gígaCape Peninsula University of Technology
Iṣẹ́Actress, film producer, social activist
Ìgbà iṣẹ́2018–present
Parents

Ọ̀rọ̀ ayé rẹ̀ Àtúnṣe

Wọ́n bí Tariro ní ọdún 1986 ní orílẹ̀-èdè Sámbíà. Òun ni ọmọ obìnrin àbígbẹ̀yìn nínu àwọn ọmọ mẹ́fà ti àwọn òbí rẹ̀. Bàbá rẹ̀ ni Ààrẹ orílẹ̀-èdè Sìmbábúè lọ́wọ́lọ́wọ́. Ìyá rẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ n ṣe Jayne Matarise di olóògbè ní 31 Oṣù Kínní, Ọdún 2002 látàrí ààrùn jẹjẹrẹ kan. Tariro ní àwọn ọmọìyá márùn-ún tí wọ́n ṣe: Farai, Tasiwa, Vimbayi, Tapiwa, àti Emmerson Tanaka. Lẹ́hìnwá ikú ìyá rẹ̀, bàbá rẹ̀ fẹ́ Auxillia Kutyauripo tí òun náà síì ti ní ọmọ mẹ́ta: Emmerson Jr. àti àwọn ìbejì tí wọ́n ṣe Sean àti Collins.[2]

Iṣẹ́ ìṣe rẹ̀ Àtúnṣe

Tariro gba oyè-ẹ̀kọ́ nínu ìmọ̀ fọ́tòyíyà láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga kan tí ó wà ní ìlú Cape Town. Ó tún gba oyè-ẹ̀kọ́ míràn nínu ìmọ̀ ìṣàkóṣo eré ìdárayá láti ilé-ẹ̀kọ́ gígaCape Peninsula University of Technology. Lẹ́hìn tí ó padà sí orílẹ̀-èdè Sìmbábúè, Tariro darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ Akashinga, ẹgbẹ́ kan tí ó n rí sí dídáàbò bo àwọn ẹranko orí-ilẹ̀ àti inú-omi àti láti tako dídẹdẹ àwọn ẹranko náà lọ́nà àìtọ́. Ó padà tún darapọ̀ mọ́ irúfẹ̀ ẹgbẹ́ náà ti àgbáyé, èyí tí wọ́n pè ní International Anti-Poaching Foundation.[3][4]

Láìpẹ́ jọjọ sí dídarapọ̀ rẹ̀ mọ́ ẹgbẹ́ àgbáyẹ́ náà, wọ́n pèé láti wá kópa nínu eré tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Gonarezhou, èyí tí olùdarí eré Sydney Taivavashe ṣe,[5] tí Ààjọ Zimbabwe Parks and Wildlife Management Authority síì ṣe onígbọ̀wọ́ rẹ̀.[6] Tariro kópa gẹ́gẹ́ bi 'Sergeant Onai' nínu eré náà.[7]

Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀ Àtúnṣe

ọdún Àkọ́lé eré Ipa Irúfẹ̀ Ìtọ́kasí
2020 Gonarezhou Sergeant Onai Fiimu

Àwọn ìtọ́kasí Àtúnṣe

  1. "Like Father Like Daughter……Meet ED's Youngest Daughter". iharare. Retrieved 19 October 2020. 
  2. Phiri, Gift (2018-03-23). "Mnangagwa family disclosures raise eyebrows". Nehanda Radio (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-04-03. 
  3. "All female anti-poaching combat unit". theguardian. Retrieved 19 October 2020. 
  4. "Zimbabwe: Mnangagwa Daughter Joins Elite Anti-Poaching Unit". allafrica. Retrieved 19 October 2020. 
  5. "President Emmerson Mnangagwa's Daughter Tariro To Feature In An Anti-Poaching Film". pindula. Retrieved 19 October 2020. 
  6. comments, Blessing Masakadza • 2 October 2018 1:59PM • 0. "ED's daughter in anti-poaching film". DailyNews Live. Archived from the original on 2020-10-20. Retrieved 2019-03-27. 
  7. "Mnangagwa's daughter in anti-poaching film". Bulawayo24 News. Retrieved 2019-03-27. 

Àwọn ìtakùn Ìjásóde Àtúnṣe