Arárọ̀míre

eré amóhùn máwòrán tí ójáde ní ọdún 2009
(Àtúnjúwe láti The Figurine)

The Figurine: Arárọ̀míre jẹ́ eré amóhùn máwòrán tí ójáde ní ọdún 2009 tí Kemi Adesoye kọ, tí Kunle Afolayan ṣàgbéjáde àti atọ́kùn, rẹ̀ tí ó sì tún kópa nínu rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìkan gbọ̀n. Ramsey Nouah àti Omoni Oboli kópa nínú rẹ̀.

The Figurine: Araromire
AdaríKunle Afolayan
Olùgbékalẹ̀Golden Effects
Òǹkọ̀wéKemi Adesoye[1]
Asọ̀tànLagbaja
Àwọn òṣèréRamsey Nouah
Omoni Oboli
Kunle Afolayan
Funlola Aofiyebi-Raimi
Tosin Sido
Orin
Wale Waves
Ìyàwòrán sinimáYinka Edward
Olóòtú
  • Kayode Adeleke
  • Steve Sodiya
Ilé-iṣẹ́ fíìmùGolden Effects Studios
Jungle FilmWorks
OlùpínGolden Effects Pictures
Déètì àgbéjáde
  • 6 Oṣù Kejì 2009 (2009-02-06) (IFFR)
  • 2 Oṣù Kẹ̀wá 2009 (2009-10-02) (Nigeria)
Àkókò122 minutes
Orílẹ̀-èdèNigeria
Èdè
  • English
  • Yoruba
Ìnáwó50[2]- 70 million[3]
Owó àrígbàwọlé₦30,000,000 (domestic gross) [4]

Eré yìí sọ ìtàn àwọn ọ̀ré méjì tí wọ́n rí ère alágbára ní ojúbọ tí wọ́n ti pa tì nínú igbó nígbà tí wọ́n ń ṣàgùnbánirọ̀, tí ìkan nínú wọn gbé ère yìí lọlé. Láìmọ̀ pé ère Arárọ̀míre tí ó maa ń gbé ire fún ènìyàn tí ó bá ri fún ọdún meje pẹlú ìyà ọdún méje míràn tí ó tẹ̀le. Ayé àwọn ọ̀ré méjì yìí bẹ̀ẹ̀rẹ̀ sí ní dára, tí wọ́n sì ń ní ìlọsíwájú àti ìgbéga nínú iṣẹ́ àti okùn òwò wọn. Síbẹ̀síbẹ̀, lẹ́yìn ọdú méje yìí, Gbogbo nkan bẹ̀ẹ̀rẹ̀ sí ní dàrú fún wọn.[5][6]

Àwọn ìtọ́kasí

àtúnṣe